Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ TI RỌ́PÒ BÍBÉLÌ?

Ibi Tí Òye Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mọ

Ibi Tí Òye Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mọ

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n tẹ àwọn ìwé kan jáde. Àwọn ìwé náà ṣàlàyé èrò àwọn tó gbà pé kò sí Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ ka ìwé yìí. Ìwé náà sì ti dá àríyànjiyàn ńlá sílẹ̀ nípa bóyá Ọlọ́run wà tàbí kò sí. David Eagleman tó jẹ́ onímọ̀ nípa iṣan ara sọ nípa ìwé náà pé, èrò àwọn kan lára àwọn tó ka ìwé náà ni pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mọ gbogbo nǹkan tán. Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ kì í ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Iṣẹ́ wọn sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣàwárí àwọn nǹkan tuntun tó máa ń yani lẹ́nu.

Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó mọ́ṣẹ́ dunjú ti máa ń ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan tó jẹ́ àwámáàrídìí nínú ayé. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí wọ́n rí máa ń yani lẹ́nu. Àmọ́ ṣá o, àwọn kan lára wọn máa ń ṣe àṣìṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwádìí náà. Bí àpẹẹrẹ, Isaac Newton jẹ́ ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó mọṣẹ́ jù lọ. Òun ló sọ bí agbára òòfà ṣe ń mú kí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì, ìràwọ̀ àti àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ wà pa pọ̀, tí wọn ò sì kọlu ara wọn. Òun náà ló ṣàwárí ẹ̀ka ìṣirò kan tí wọ́n fi ń ṣe kọ̀ǹpútà, ìyẹn calculus. Ẹ̀ka ìṣirò yìí náà ni àwọn tó ń rìnrìn àjò lójú òfúrufú máa ń lò, àwọn onímọ̀ nípa átọ́ọ̀mù náà sì ń lò ó. Ṣùgbọ́n Newton tún lọ́wọ́ sí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kan tí wọ́n ń pè ní alchemy, tó ní í ṣe pẹ̀lú wíwo ìràwọ̀ àti idán pípa, torí pé ó ń wá bó ṣe lè sọ irin lásán di góòlù.

Onímọ̀ nípa sánmà kan wà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ptolemy. Ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ni. Ó gbé ayé ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] ọdún kí wọ́n tó bí Newton. Ojú lásán ni ọ̀gbẹ́ni yìí fi ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó wà lójú sánmà. Ó máa ń tọpasẹ̀ àwọn ìràwọ̀ tó wà lójú sánmà lọ́wọ́ alẹ́. Bákan náà, ó mọ̀ nípa yíya àwòrán ilẹ̀ gan-an. Àmọ́, ó gbà pé ààrín ni ayé yìí wà, tí oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ sì ń yípo rẹ̀. Carl Sagan tó jẹ́ onímọ̀ nípa sánmà sọ pé, ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] ọdún gbáko ni àwọn èèyàn fi gba èrò tí kò tọ́ tí Ptolemy ní yìí gbọ́. Èyí fi hàn pé, èèyàn jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n kò túmọ̀ sí pé kò lè ṣe àṣìṣe tó bùáyà.

Lónìí, kì í ṣe gbogbo ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ ni èèyàn lè gbára lé. Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ lè ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run? Ká sòótọ́, ìtẹ̀síwájú ti bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àǹfààní tó sì ń ṣe wá kúrò ní kèrémí. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣe. Paul Davies tó jẹ́ onímọ̀ nípa físíìsì sọ pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ilẹ̀ ayé àti ìsálú ọ̀run, kí àlàyé náà sì bára mu délẹ̀délẹ̀.” Òótọ́ ọ̀rọ̀ tí kò ṣe é já ní koro ni ọ̀gbẹ́ni yìí sọ. Ìyẹn ni pé: Àwa èèyàn kò lè mọ gbogbo nǹkan nípa ayé àti ìsálú ọ̀run láéláé. Fún ìdí yìí, tí àwọn èèyàn kan bá sọ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣàlàyé nípa gbogbo nǹkan tó wà lọ́run àti láyé, kò yẹ ká gbára lé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pátápátá.

Láìsí àní-àní, Bíbélì fún wa ní ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè fún wa

Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tó wà lọ́run àti láyé pé: “Wò ó! Ìwọ̀nyí jẹ́ bèbè àwọn ọ̀nà [Ọlọ́run], àhegbọ́ mà ni ohun tí a sì gbọ́ nípa rẹ̀!” (Jóòbù 26:14) Ọ̀kẹ́ àìmọye nǹkan ló ṣì wà táwa èèyàn ò mọ, tó jẹ́ pé ó kọjá ìrònú àti òye ẹ̀dá. Kò sí àní-àní pé, ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn ṣì jẹ́ òótọ́ títí dòní. Ó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!”—Róòmù 11:33.