ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Ìran Méje Tó Sin Jèhófà
Àwọn èèyàn máa ń sọ pé mo jọ bàbá mi láìkù síbì kan, bí mo bá dúró àfi bíi pé bàbá mi ni. Mo tún fojú jọ ọ́, mo sì máa ń ṣàwàdà bíi bàbá mi. Àmọ́, mo tún jogún nǹkan míì látọ̀dọ̀ bàbá mi, ìyẹn ni pé ó ti di ìran keje nínú ìdílé wa báyìí tó ń jọ́sìn Jèhófà. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ fún yín.
Wọ́n bí baba ńlá mi, ìyẹn Thomas1 * Williams ní January 20, ọdún 1815 nílùú Horncastle nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Kò tíì ju ọmọ ọdún méjì lọ tí ìyá rẹ̀ fi kú, àtìgbà náà ni bàbá rẹ̀ tó ń jẹ́ John Williams ti ń tọ́jú òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́ta títí tí wọ́n fi dàgbà. Iṣẹ́ káfíńtà ni John kọ́ Thomas, àmọ́ ọ̀tọ̀ ni iṣẹ́ tó wu Thomas láti ṣe.
Àsìkò yìí ni ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ń gbóná janjan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Oníwàásù kan tó ń jẹ́ John Wesley ṣẹ̀ṣẹ̀ yapa kúrò nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni, ó sì lọ dá Ẹgbẹ́ Onísìn Mẹ́tọ́díìsì sílẹ̀, ìyẹn ẹgbẹ́ kan tó ń gbé ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti iṣẹ́ ìwàásù lárugẹ. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, àwọn ẹ̀kọ́ tí John Wesley ń kọ́ àwọn èèyàn ti tàn káàkiri débi pé gbogbo ìdílé Williams náà di onísìn Mẹ́tọ́díìsì. Bí Thomas ṣe di oníwàásù lábẹ́ Wesley nìyẹn, kò sì pẹ́ tó fi gba iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Gúúsù Pàsífíìkì. Ní oṣù July, ọdún 1840, òun àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Mary,2 gúnlẹ̀ sí Erékùṣù Lakeba, * lórílẹ̀-èdè Fíjì, ìyẹn erékùṣù ayọnáyèéfín kan tó jẹ́ pé àwọn tó ń jẹ èèyàn ló kún ibẹ̀.
WỌ́N GBÉ LÁÀÁRÍN ÀWỌN TÓ Ń JẸ ÈÈYÀN
Láwọn ọdún díẹ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ lò ní orílẹ̀-èdè Fíjì, Thomas àti Mary fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro, kódà ojú wọn rí màbo. Ipò tí wọ́n bára wọn kò bára dé rárá, wọ́n sì ní láti fara da ooru tó máa ń mú ní ilẹ̀ náà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn nǹkan tójú wọn rí kì í ṣe kékeré. Bí ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, fífún àwọn opó lọ́rùn pa, pípa àwọn ọmọdé jòjòló nípakúpa àti bí àwọn kan ṣe ń pa èèyàn jẹ. Bákan náà, àwọn tó wà ní ilẹ̀ náà kọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere tí wọ́n ń wàásù. Mary àti John tó jẹ́ àkọ́bí rẹ̀ ọkùnrin ṣàìsàn tó le gan-an, díẹ̀ ló kù kí ẹ̀mí wọn bọ́. Lọ́dún 1843, Thomas kọ̀wé pé: “Inú mi bà jẹ́ gan-an . . . gbogbo nǹkan sì tojú sú mi.” Síbẹ̀, òun àti ìyàwó rẹ̀ forí tì í, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà Ọlọ́run sì túbọ̀ fún wọn lókun.
Torí pé Thomas jẹ́ káfíńtà, òun ló kọ́kọ́ kọ́ irú ilé tí wọ́n máa ń kọ́ ní ilẹ̀ Yúróòpù sí orílẹ̀-èdè Fíjì. Ọ̀nà tó gbà kọ́ ilé náà máa ń ya àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Fíjì lẹ́nu, torí pé ó jẹ́ kí ilé náà ga sókè débí tí atẹ́gùn á fi lè máa fẹ́ wọlé, ó sì tún ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ọ̀nà sára ilé náà. Ìgbà tó ń kọ́ ilé náà lọ́wọ́ ni ìyàwó rẹ̀ bí ọmọkùnrin kejì, wọ́n sì pè é ní, Thomas Whitton3 Williams, òun sì ni baba ńlá mi tó kàn.
Ní ọdún 1843, Thomas Williams tú ìwé Ìhìn Rere Jòhánù sí èdè Fijian, iṣẹ́ kékeré kọ́ ló sì ṣe. * Àmọ́, ó tún jẹ́ ẹni tó máa ń kíyè sí ìṣesí àwọn èèyàn. Torí náà, ó ṣe ìwé kan tó dá lórí bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Fíjì ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ó pe orúkọ ìwé náà ní Fiji and the Fijians (1858).
Lẹ́yìn tó ti lo ọdún mẹ́tàlá ní orílẹ̀-èdè Fíjì, ìlera rẹ̀ kò gbé e mọ́, lòun àti ìdílé rẹ̀ bá kó lọ sí orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Thomas ṣiṣẹ́ àlùfáà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó sì di ìlúmọ̀ọ́ká. Ó kú ní ọdún 1891 nílùú Ballarat, ní ìpínlẹ̀ Victoria lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà.
WỌ́N RÍ OHUN TÓ ṢEYEBÍYE NÍ ÌWỌ̀ OÒRÙN
Nígbà tó di ọdún 1883, Thomas Whitton Williams àti ìyàwó rẹ̀ Phoebe,4 pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn kó lọ sí ìlú Perth, tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni Arthur Bakewell 5 Williams nígbà yẹn, òun ni wọ́n bí ṣìkejì, òun sì ni Bàbá ńlá mi tó kàn.
Arthur kò ju ọmọ ọdún méjìlélógún [22] lọ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́wọ́ mú ní ìlú Kalgoorlie tí wọ́n ti ń wa góòlù. Ìlú yìí jẹ́ ẹgbẹ̀ta [600] kìlómítà sí ìlú Perth, ibẹ̀ ló sì ti ka díẹ̀ lára ìwé tí àwọn International Bible Students tẹ̀ jáde, ìyẹn orúkọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ nígbà yẹn. Ó tún san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower. Ó gbádùn ohun tuntun tó kà nínú ìwé náà débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ́ fún àwọn èèyàn. Ó sì tún ṣètò àwọn ìpàdé tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ ní Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Ọsirélíà nìyẹn.
Arthur tún ṣàlàyé ohun tó ń kọ́ fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Inú Thomas Whitton tó jẹ́ bàbá rẹ̀ sì dùn sí bó ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ kò pẹ́ sígbà náà ni Thomas kú. Phoebe tó jẹ́ ìyá Arthur àti àwọn àbúrò rẹ̀ obìnrin, ìyẹn Violet àti Mary náà di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, Violet bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀pọ̀ wákàtí wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn aṣáájú-ọ̀nà. Arthur sọ pé àbúrò òun ni “aṣáájú-ọ̀nà tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ tó sì tún nítara jù lọ ní Ìwọ̀ Oòrùn Ọsirélíà.” Ohun tí Arthur sọ lè má jẹ́ òótọ́ pọ́ńbélé àmọ́, àpẹẹrẹ rere tí Violet fi lélẹ̀ ni ìran Williams tó kàn tẹ̀ lé.
Nígbà tó yá, Arthur ṣègbéyàwó, ó sì kó lọ sí ìlú Donnybrook tó wà ní Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Ọsirélíà. Nítorí bó ṣe máa ń fi ìtara sọ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914, àwọn èèyàn ń fojú agbawèrèmẹ́sìn wò ó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní “Old Mad 1914!” * Àmọ́ nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ̀rẹ̀, kò sẹ́ni tó fi ṣẹ̀sín mọ́. Arthur máa ń to àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì sójú fèrèsé rẹ̀, èyí ló fi ń wàásù fáwọn oníbàárà rẹ̀ níbi tó ti ń tajà. Arthur kò gba ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan gbọ́ torí kò sí nínú Ìwé Mímọ́. Ó wá gbé àmì kan sójú fèrèsé tó sọ pé ẹni tó bá lè fi hàn òun pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan, òun máa fún un ní ọgọ́rùn-ún [100] pounds. Kò sí ẹni tó gba owó náà.
Ilé Arthur Bakewell Williams tó wà ní Donnybrook wá di ibi tí àwùjọ àwọn èèyàn kan ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ń ṣe ìpàdé ìjọ. Nígbà tó yá, Arthur kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ilé ìjọsìn, èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára ilé ìjọsìn àkọ́kọ́ tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Nígbà tí Arthur dẹni àádọ́rin [70] ọdún ó lé díẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jáde lọ wàásù. Bó bá ti wọ kóòtù rẹ̀ tó sì fi
táì sí i, tó sì gun ẹṣin rẹ̀ báyìí, ó ń lọ nìyẹn, kò sí ibi tí kì í wàásù dé ní gbogbo agbègbè Donnybrook.Bí Arthur ṣe jẹ́ èèyàn jẹ́jẹ́, tó gbayì láwùjọ tó sì tún jẹ́ onítara yìí ní ipa tó dáa lórí àwọn ọmọ rẹ̀. Ọmọ rẹ̀ obìnrin tó ń jẹ́ Florence6 ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Íńdíà. Àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, Arthur Lindsay (7) àti Thomas, sì jẹ́ alàgbà nínú ìjọ fún ọ̀pọ̀ ọdún, bíi ti bàbá wọn.
ÈSO ÁPÙ LADY WILLIAMS TÓ DÙN YÀTỌ̀
Arthur Lindsay Williams ni bàbá tó bí bàbá bàbá mi, gbajúmọ̀ ni, àwọn èèyàn sì fẹ́ràn rẹ̀ torí onínúure ni. Ó jẹ́ ẹni tó kó èèyàn mọ́ra, ó sì máa ń fọ̀wọ̀ wọ àwọn èèyàn. Ó tún mọ nípa iṣẹ́ fífi àáké gé igi. Ìgbà méjìdínlógún [18] ló gbégbá orókè nínú ìdíje àwọn tó ń fi àáké gégi láàárín ọdún méjìlá.
Inú Arthur kò dùn nígbà tí Ronald (8) tó jé bàbá mi àgbà, tí kò ju ọmọ ọdún méjì lọ nígbà yẹn, fi àáké ṣá igi ápù tó wà ní ìtòsí ilé wa. Ìyá rẹ̀ wá fi okùn wé ibi tó fi àáké ṣá náà, igi náà sì yè. Ó sì so èso ápù tó dùn yàtọ̀, kódà kò sí irú rẹ̀ rí. Àtìgbà náà ni wọ́n tí ń fi orúkọ ìdílé William pe èso ápù náà, ìyẹn Lady Williams apple. Ara ápù yìí ní wọ́n tí mú oríṣi èso ápù aláwọ̀ osùn jáde. Èso ápù aláwọ̀ osùn yìí wà lára àwọn ápù tó gbayì jù lọ láyé.
Nígbà tó yá, Ronald tó jẹ́ bàbá mi àgbà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ kọ́lékọ́lé. Òun àti ìyàwó rẹ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ àwọn ilé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò fún ìjọsìn káàkiri orílẹ̀-èdè Ọsirélíà àti erékùṣù Solomon Islands. Ní báyìí, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́rin [80] ọdún, àmọ́ ó ṣì jẹ́ alàgbà nínú ìjọ. Ó sì tún máa ń bá wọn kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun àti èyí tí wọ́n fẹ́ tún ṣe, ní Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Ọsirélíà.
MO MỌYÌ OGÚN IYEBÍYE TÍ MO NÍ
Àwọn òbí mi náà ṣìkẹ́ ogún iyebíye tí àwọn baba ńlá mi fi sílẹ̀. Geoffrey (9) àti Janice (10) Williams làwọn òbí mi, wọ́n sì sa gbogbo ipá wọn láti fi àwọn ìlànà Bíbélì kọ́ èmi àti àbúrò mi obìnrin tó ń jẹ́ Katharine. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdùn mẹ́tàlá, mo ṣè ìrìbọmi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Mo rántí ìgbà kan tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ Arákùnrin John E. Barr tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àpéjọ kan. Ó rọ gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tó wà ní ìkàlẹ̀ lọ́jọ́ náà pé: “Ẹ má ṣe fi ogún iyebíye tẹ́ ẹ ní tàfàlà, ìyẹn àǹfààní tẹ́ ẹ ní láti mọ Jèhófà kẹ́ ẹ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Alẹ́ ọjọ́ náà ni mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Ọdún méjì lẹ́yìn náà ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé.
Èmi (12) àti ìyàwó mi Chloe, (11) ṣì ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún tí à ń ṣe ní Tom Price, ìlú kékeré kan tí wọ́n ti ń wa irin, tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Àkókò díẹ̀ la fi ń ṣiṣẹ́ lóòjọ́, ká lè rí owó gbọ́ bùkátà ara wa. Àwọn òbí mi, àbúrò mi Katharine àti ọkọ rẹ̀, Andrew náà ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Port Hedland, tó jẹ́ nǹkan bí okòó lé nírínwó [420] kìlómítà sí àríwá. Èmi àti bàbá mi sì jẹ́ alàgbà nínú ìjọ.
Ìran keje rèé tó ti ń sin Jèhófà bọ̀ nínú ìdílé wa, ìyẹn látìgbà tí Thomas Williams tó jẹ́ baba ńlá mi ti pinnu láti sin Jèhófà Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́-ìsìn yẹn tàn dé ọ̀dọ̀ mi. Ìbùkún tí mo rí gbà látàrí ogún tẹ̀mí yìí kò lẹ́gbẹ́, mo sì mọrírì rẹ̀ gan-an ni.
^ ìpínrọ̀ 5 Nọ́ńbà tá a kọ sí ara àwòrán kọ̀ọ̀kan tó wà lójú ìwé 12 àti 13 ń tọ́ka sí àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn.
^ ìpínrọ̀ 6 Lakeba ni wọ́n ń pe Erékùṣù Lakemba tẹ́lẹ̀, ó wà ní Ìlà Oòrùn Lau Group lórílẹ̀-èdè Fíjì.
^ ìpínrọ̀ 10 Míṣọ́nnárì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John Hunt, tú èyí tó pọ̀ jù nínú Májẹ̀mú Tuntun sí èdè Fijian, ó sì tẹ̀ ẹ́ jáde lọ́dún 1847. Ìtumọ̀ Bíbélì yìí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn torí ó lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn “Jiova” nínú Máàkù 12:36, Lúùkù 20:42 àti Ìṣe 2:34.
^ ìpínrọ̀ 16 Ka àfikún àlàyé tó wà ní apá ìparí ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? lábẹ́ àkòrí náà “1914—Ọdún Pàtàkì Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì.” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó tún wà lórí ìkànnì www.ps8318.com/yo.