Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé O Ronú Pé Ọlọ́run Ti Já Ẹ Kulẹ̀?

Ṣé O Ronú Pé Ọlọ́run Ti Já Ẹ Kulẹ̀?

ỌMỌ ọdún mẹ́rìnlélógún [24] ni Sidnei tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil. Lọ́jọ́ kan, jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí i níbí tó ti lọ gbafẹ́, àtìgbà náà ló sì ti wà lórí àga arọ. Ìbéèrè tó máa n wá sí Sidnei lọ́kàn ni pé: “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kírú èyí ṣẹlẹ̀ sí mi.”

Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀, irú bí ìjàǹbá, àìsàn, ikú ẹni téèyàn nífẹ̀ẹ́, àjálù tàbí ogun, ó lè mú kéèyàn máa ronú pé Ọlọ́run ti já òun kulẹ̀. Èyí kì í ṣe tuntun. Nígbà àtijọ́, oríṣiríṣi àjálù ló dé bá ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Jóòbù. Àmọ́ Jóòbù dá Ọlọ́run lẹ́bi láìmọ̀, ó ní: “Mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn; mo dúró, kí o bàa lè fi ara rẹ hàn ní olùfiyèsílẹ̀ sí mi. Ìwọ yí ara rẹ padà láti ṣe mí níkà; ìwọ fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá ọwọ́ rẹ ṣe kèéta sí mi.”Jóòbù 30:20, 21.

Jóòbù kò mọ ohun tó fa ìṣòro rẹ̀ tàbí ìdí tó fi jẹ́ pé òun ló ṣẹlẹ̀ sí àti ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ sí i. Ó dùn mọ́ wa pé Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó máa ń fa ìṣòro àti èrò tó yẹ ká ní nípa àwọn ìṣòro wa.

ṢÉ ỌLỌ́RUN FẸ́ KÍ ÀWA ÈÈYÀN MÁA JÌYÀ?

Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé ó mọ́gbọ́n dání ká sọ pé Ọlọ́run tó jẹ́ “olódodo àti adúróṣánṣán” máa fẹ́ kí àwa èèyàn máa jìyà tàbí kó jẹ́ kí àjálù ṣẹlẹ̀ sí wa láti fi jẹ wá níyà tàbí kó lè dán wa wò?

Rárá o, Bíbélì sọ fún wa pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Bíbélì tiẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí Ọlọ́run dá àwa èèyàn, kò fẹ́ kí ìyà kankan jẹ wá. Ó fún ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà ní ilé tó dára, ó fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò àti iṣẹ́ tó rọrùn. Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” Kò sí ìdí kankan fún Ádámù àti Éfà láti ronú pé Ọlọ́run já àwọn kulẹ̀.Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

Àmọ́ ipò nǹkan ti yàtọ̀ gan-an lóde òní. Kódà, ọjọ́ pẹ́ tí ìyà ti ń jẹ àwa èèyàn lọ́nà tó lékenkà. Òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì to sọ pé: “Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) Kí ló fà á?

KÍ LÓ FA ÌYÀ TÓ Ń JẸ WÁ?

Ká lè mọ ohun tó fa ìjìyà, ó yẹ ká mọ bí ìyà ṣe bẹ̀rẹ̀. Ańgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan tá a mọ̀ sí Sátánì Èṣù ló tan Ádámù àti Éfà láti kọ ìlànà Ọlọ́run lórí ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Ó mú kí wọ́n rú òfin tí Ọlọ́run fún wọn pé kí wọ́n má ṣe jẹ lára èso “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” Èṣù sọ fún Éfà pé wọn ò ní kú tí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ pe Ọlọ́run ní òpùrọ́. Sátánì tún fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé kò jẹ́ kí àwọn èèyàn lè fúnra wọn pinnu ohun tó dáa àti èyí tí kò dáa. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:1-6) Sátánì sọ pé nǹkan máa dáa fún àwọn èèyàn tí wọ́n ò bá sí lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Gbogbo èyí ló gbé ọ̀rọ̀ pàtàkì kan dìde, ìyẹn ni pé, Ṣé Ọlọ́run lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso àwa èèyàn?

Sátánì tún gbé ọ̀ràn míì dìde. Ó sọ pé torí ohun tí àwa èèyàn máa rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run la ṣe ń sìn ín. Sátánì ṣàríwísí Jóòbù lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé: “Ìwọ fúnra rẹ kò ha ti ṣe ọgbà ààbò yí i ká, àti yí ilé rẹ̀ ká, àti yí ohun gbogbo tí ó ní ká? . . . Ṣùgbọ́n, fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fọwọ́ kan ohun gbogbo tí ó ní, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.” (Jóòbù 1:10, 11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ni Sátánì darí ọ̀rọ̀ náà sí, àmọ́ ohun tí Sátánì ní lọ́kàn ni pé torí ohun tí àwa èèyàn máa rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run la ṣe ń sìn ín.

BÍ ỌLỌ́RUN ṢE YANJÚ Ọ̀RÀN NÁÀ

Ọ̀nà wo ló dáa jù láti gbà yanjú àwọn ẹ̀sùn yìí tírú ẹ̀ kò fi ní wáyé mọ́? Ọlọ́run tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n mọ ojútùú sí ìṣòrò náà, ọ̀nà tó dára jù lọ ló sì gbà yanjú rẹ̀. (Róòmù 11:33) Ó gba àwọn èèyàn láyè láti ṣàkóso ara wọn fúngbà díẹ̀, èyí máa jẹ́ kí gbogbo wa mọ̀ bóyá ìṣàkóso Ọlọ́run ló dára jù tàbí tàwọn èèyàn.

Bí ipò àwa èèyàn ṣe burú lónìí jẹ́ ẹ̀rí pé ìṣàkóso èèyàn ti forí ṣánpọ́n. Kò sí àlàáfíà, ààbò àti ayọ̀ lábẹ́ ìṣàkóso èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó máa pa ayé run ni wọ́n ń ṣe. Èyí fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ṣàkóso nìkan ló máa jẹ́ ká ní àlàáfíà àti ayọ̀, táá sì jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀, torí pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ gan-an nìyẹn.Aísáyà 45:18.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe kó lè rí bó ṣe fẹ́? Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Tí àsìkò bá tó, Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti mú gbogbo ohun tó fa ìyà fún àwa èèyàn kúrò. (Dáníẹ́lì 2:44) Ìṣẹ́ àti òṣì, àìsàn àti ikú máa di ohun àtijọ́. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa “dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè.” (Sáàmù 72:12-14) Ní ti àwọn aláìsàn, Bíbélì ṣèlérí pé: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Kódà, Jésù sọ nípa àwọn òkú pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Àwọn ìlérí yìí má tuni nínú o!

Tá a bá gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́, kò ní jẹ́ ká máa ronú pé Ọlọ́run ti já wa kulẹ̀

BÁ A ṢE LÈ BORÍ ÌJÁKULẸ̀

Lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlógún [17] tí Sidnei, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ti ní ìjàǹbá, ó sọ pé: “Mi ò dá Jèhófà Ọlọ́run lẹ́bi nítorí jàǹbá tí mo ni, àmọ́ kí n sòótọ́, ó kọ́kọ́ ṣe mí bí i pé Ọlọ́run ti jà mí kulẹ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìrònú máa ń sorí mi kodò, mo sì máa ń sunkún nítorí ipò tí mo wà. Àmọ́ ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ́ kí n rí i pé, kì í ṣe Ọlọ́run ló fi ìjàǹbá náà jẹ mí níyà. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ‘ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa.’ Gbígbàdúrà sí Jèhófà àti kíkà Bíbélì ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, mi ò sì ro ara mi pin mọ́.”Oníwàásù 9:11; Sáàmù 145:18; 2 Kọ́ríńtì 4:8, 9, 16.

Tá a bá ń ronú nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà àti bí Ọlọ́run ṣe máa mú ìjìyà kúrò láìpẹ́, kò ní jẹ́ ká máa ronú pé Ọlọ́run ti já wa kulẹ̀. Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run ni “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” Gbogbo àwọn tó bá gbọ́kàn lé òun àti ọmọ rẹ̀ kò ní rí ìjákulẹ̀.Hébérù 11:6; Róòmù 10:11.