Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Mi Ò Fẹ́ Kú O!

Mi Ò Fẹ́ Kú O!
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1964

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: ENGLAND

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO YÀYÀKUYÀ, MO SÌ BÍMỌ NÍGBÀ TÍ MO ṢÌ KÉRÉ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀

Ìlú Paddington, ní àgbègbè London, lórílẹ̀-èdè England ni wọ́n bí mi sí, èrò sì pọ̀ gan-an ní ìlú yìí. Èmi àti màmá mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin mẹ́ta la jọ ń gbé. Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan la máa ń rí dádì mi torí pé ọ̀mùtí ni wọ́n.

Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ìyá mi kọ́ mi pé kí n máa gbàdúrà lálaalẹ́. Mo ní Bíbélì kékeré kan tó jẹ́ pé ìwé Sáàmù nìkan ló wà nínú rẹ̀, mo sì máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lórin. Mo rántí ọjọ́ tí mo ka ọ̀rọ̀ kan nínú ìwé kan, ohun tí mo kà náà ò sì kúrò lọ́kàn mi. Ọ̀rọ̀ náà ni: “Ọjọ́ ń bọ̀ tí gbogbo nǹkan máa pa run.” Tí mo bá rántí ọ̀rọ̀ yẹn, ńṣe ló máa ń gba oorun lójú mi, tí màá sì máa ronú nípa ọjọ́ ọ̀la. Mo máa ń ronú pé ‘A ò kàn lè wà láyé yìí lásán.’ ‘Kí nìdí tí mo fi wà láyé?’ Mi ò fẹ́ kú o!

Ó wù mí kí n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn. Torí náà, mo gbìyànjú láti máa bá òkú sọ̀rọ̀, mo tún tẹ̀ lé àwọn ọmọléèwé mi lọ sí itẹ́ òkú, a sì tún máa ń lọ wo àwọn fíìmù tó ń bani lẹ́rù. Àwọn fíìmù náà máa ń jáni láyà, àmọ́ lójú wa à ń gbádùn ẹ̀.

Ìgbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í yàyàkuyà. Mò ń mu sìgá, kò sì pẹ́ tí mo fi ń mu ún lójú páálí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo wá ń mugbó. Mo dán ọtí mímu wò lọ́mọ ọdún mọ́kànlá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò gbádùn bó ṣe máa ń rí lẹ́nu, bó ṣe máa ń pa mí máa ń dùn mọ́ mi. Mo tún fẹ́ràn orin àti ijó, mo sì máa ń lọ síbi àríyá àti ilé fàájì alaalẹ́. Ńṣe ni mó máa ń yọ́ jáde nílé lálẹ́ tí màá sì yọ́ wọlé ní ìdájí ọjọ́ kejì. Mo máa ń sá níléèwé torí pé á ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu. Ọjọ́ tí mo bá wá jàjà lọ síléèwé, ọtí ni mo máa ń mu tí tíṣà bá ti jáde ní kíláàsì.

Mi ò ṣe dáadáa nígbà ìdánwò àṣekágbá tá a ṣe. Torí náà inú bí màmá mi gan-an, ó sì ká wọn lára pé ìwàkiwà ọwọ́ mi ti burú tó bẹ́ẹ̀. A bára wa fà á, mo sì sá jáde nílé. Ọ̀dọ̀ Tony ọ̀rẹ́kùnrin mi ni mo sá lọ. Ó máa ń jalè, ó ń ta oògùn olóró, ó sì máa ń hùwà jàgídíjàgan. Kò pẹ́ tí mo fi lóyún, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ni mí nígbà tí mo bí àkọ́bí mi.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

Ìgbà tí mò ń gbé ní ilé àwọn ìyá anìkàntọ́mọ ni mo pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn aláṣẹ fún mi ní yàrá kan nínú ilé náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n jẹ́ obìnrin máa ń wá sọ́dọ̀ àwọn obìnrin kan tó ń dá tọ́ ọmọ níbẹ̀. Lọ́jọ́ kan, mo dá sí ìjíròrò wọn. Mo fẹ́ fi hàn wọ́n pé ẹ̀kọ́ wọn ò tọ̀nà. Àmọ́ wọ́n fara balẹ̀ dáhùn àwọn ìbéèrè mi lọ́nà tó ṣe kedere látinú Bíbélì. Onínúure àti ẹni pẹ̀lẹ́ ni wọ́n, ìwà yẹn sì fà mí mọ́ra. Lèmi náà bá gbà kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Kò pẹ́ tí mo fi kọ́ ohun kan nínú Bíbélì tó yí ìgbésí ayé mi pa dà. Àtìgbà tí mo ti wà ní kékeré lẹrù ikú ti ń bà mí. Àmọ́ ní báyìí, mo ti wá mọ ohun tí Jésù sọ nípa àjíǹde! (Jòhánù 5:28, 29) Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ka èmi fúnra mi sí pàtàkì. (1 Pétérù 5:7) Ọ̀rọ̀ inú Jeremáyà 29:11, tún wọ̀ mí lọ́kàn, ó ní: “‘Nítorí èmi fúnra mi mọ àwọn èrò tí mo ń rò nípa yín ní àmọ̀dunjú,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àwọn èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti ìyọnu àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’” Ìgbà yẹn ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í nírètí pé màá gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.Sáàmù 37:29.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi tọkàntọkàn. Nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sípàdé wọn, ibẹ̀ tù mí lára gan-an torí pé gbogbo wọn hùwà sí mi bí ọ̀rẹ́! (Jòhánù 13:34, 35) Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ìwà tí wọ́n ń hù sí mi ní ṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn Ẹlẹ́rìí gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀ láìka ipò mi sí. Wọ́n ṣe sùúrù fún mi, wọ́n tọ́jú mi, wọ́n sì ń gbọ́ tèmi, kódà wọ́n máa ń fún mi ní nǹkan. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí mo wà lára ìdílé ńlá kan tó nífẹ̀ẹ́ mi.

Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé mo ní láti jáwọ́ nínú àwọn ìwàkíwà tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. Àmọ́, kò kọ́kọ́ rọrùn fún mi láti jáwọ́ nínú sìgá mímu. Bákan náà, mo tún kíyè sí i pé àwọn orin kan máa ń jẹ́ kó wù mí láti mugbó, torí náà mo ṣàtúnṣe àwọn orin tí mò ń gbọ́. Lẹ́yìn náà, mi ò lọ síbi àríyá àti ilé fàájì alaalẹ́ mọ, kí n má báa tún lọ mutí yó. Mo wá yan àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tí ìgbé ayé wọn máa ní ipa rere lórí mi.Òwe 13:20.

Àárín àkókò yẹn náà ni Tony bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀, ó wá dá òun náà lójú pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n ń kọ́ ọ. Ó ṣe àwọn àyípadà pàtàkì nígbèésí ayé rẹ̀: kò bá àwọn ọmọọ̀ta rìn mọ́, ó jáwọ́ nínú olè jíjà, kò sì mugbó mọ́. Ká lè túbọ̀ ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, a rí i pé ó yẹ ká jáwọ́ nínú bíba ara wa ṣèṣekúṣe, ká sì pawọ́ pọ̀ tọ́ ọmọ wa. Torí náà, a ṣègbéyàwó lọ́dún 1982.

“Oorun kì í dá lójú mi mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ọjọ́ ọ̀la tàbí ìbẹ̀rù pé mi ò fẹ́ kú”

Mo rántí pé mo máa ń ṣèwádìí nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! * nípa àwọn èèyàn tó ti ṣe irú àyípadà tí mo fẹ́ sẹ, tí wọ́n sì ṣàṣeyọrí. Àpẹẹrẹ wọn ràn mí lọ́wọ́ gidigidi! Ó jẹ́ kí n lè máa sapá nìṣó, mi ò sì jẹ́ kó sú mi. Mo sì máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó má ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ mi sú u. Ní July ọdún 1982, èmi àti Tony ṣe ìrìbọmi láti di ọ̀kan lara àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

Bí mo ṣe di ọ̀rẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ló jẹ́ kí n ṣì wà láàyè. Èmi àti Tony tún ti rí ọwọ́ Jèhófà láyè wa lásìkò tá a wà nínú ìṣòro. Àwọn ìṣòro tá a dójú kọ tí jẹ́ ká gbára lé Ọlọ́run, a sì ti rí i pé Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́, ó sì ń gbé wa ró.Sáàmù 55:22.

Inú mi tún dùn pé mo láǹfààní láti ran ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wa lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, bí èmi náà ṣe mọ̀ ọ́n. Ní báyìí, mò ń láyọ̀ bí mo ṣe ń rí àwọn ọmọ ọmọ mi táwọn náà ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run.

Oorun kì í dá lójú mi mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ọjọ́ ọ̀la tàbí ìbẹ̀rù pé mi ò fẹ́ kú. Ọwọ́ èmi àti Tony ọkọ mi dí gan-an bá a ṣe ń ṣèbẹ̀wò sí ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ká lè fún wọn ní ìṣírí. A jọ ń sọ fún àwọn èèyàn pé tí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, àwọn náà á gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun.

^ ìpínrọ̀ 17 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.