Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?
ORÍ 1
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?
“Mo gbìyànjú gan-an láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi fún àwọn òbí mi, àmọ́ ohun tí mò ń sọ kò yé wọn, bí wọ́n ṣe dá ọ̀rọ̀ mọ́ mi lẹ́nu nìyẹn. Kò sì rọrùn fún mi láti sọ ìwọ̀nba tí mo sọ yẹn o. Ibi tọ́rọ̀ yẹn parí sí dùn mí gan-an!”—Rosa.
NÍGBÀ tó o ṣì kéré, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òbí rẹ lo máa ń lọ bá tó o bá nílò ìmọ̀ràn. Kò sí ohun tí o kì í sọ fún wọn. O máa ń sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ, ohun tí wọ́n bá sì sọ lo máa ń ṣe.
Àmọ́ ní báyìí, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ọ̀rọ̀ rẹ kì í yé àwọn òbí rẹ mọ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Edie sọ pé: “Nígbà tá à ń jẹun nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi, mo sì ń sunkún. Àwọn òbí mi tẹ́tí gbọ́ o, àmọ́ ó dà bíi pé
ohun tí mò ń sọ kò tiẹ̀ yé wọn.” Kí ló wá yọrí sí? Edie ní: “Ńṣe ni mo kàn gba yàrá mi lọ, tí mo lọ ń sunkún!”Ìgbà míì wà tí kò ní wù ẹ́ pé kó o sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fáwọn òbí rẹ. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Christopher sọ pé: “Oríṣiríṣi nǹkan lèmi àtàwọn òbí mi jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àmọ́, nígbà míì, kì í ṣe gbogbo nǹkan tí mò ń rò lọ́kàn ló máa ń wù mí kí n sọ fún wọn.”
Ǹjẹ́ ó burú kó o láwọn nǹkan kan tó ò ń rò lọ́kàn tí o kò sì fẹ́ sọ fáwọn òbí rẹ? Ó lè má burú, tó bá jẹ́ pé ohun tó dáa ni, tí kì í ṣe pé ṣe lo fẹ́ tan àwọn òbí rẹ jẹ. (Òwe 3:32) Síbẹ̀, bóyá ó dà bíi pé àwọn òbí rẹ kò lóye rẹ ni o tàbí ìwọ lò ń fi ọ̀rọ̀ pa mọ́ fún wọn, ohun tó dájú ni pé: Ó yẹ kó o máa bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀, ó sì yẹ kí àwọn náà máa gbọ́ èrò ọkàn rẹ.
Rí I Pé Ò Ń Bá Wọn Sọ̀rọ̀!
Láwọn ọ̀nà kan, bíbá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ dà bí ìgbà tó ò ń wa mọ́tò lọ. Tí wọ́n bá fi nǹkan dí ojú ọ̀nà níbì kan, o ò ní torí ìdènà yẹn pa dà sílé, ńṣe ni wàá gba ọ̀nà míì. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ìdènà méjì kan.
ÌDÈNÀ ÀKỌ́KỌ́ O ní ohun tó o fẹ́ bá àwọn òbí rẹ sọ àmọ́ ó jọ pé wọn ò ráyè tìẹ. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Leah sọ pé: “Ó máa ń ṣòro fún mi láti bá dádì mi sọ̀rọ̀. Nígbà míì, mo lè ti máa sọ̀rọ̀ lọ o, wọ́n á kàn dédé sọ pé: ‘Ẹn-ẹ́n! Ṣó ò ń bá mi sọ̀rọ̀ ni?’”
ÌBÉÈRÈ: Kí ni Leah lè ṣe tó bá ní ìṣòro kan tó fẹ́ sọ fún dádì rẹ̀? Ó kéré tán, ohun mẹ́ta wà tó lè ṣe.
Ohun Àkọ́kọ́
Kó jágbe mọ́ dádì rẹ̀. Leah lè kígbe pé: “Hà! Ṣé pé ẹ ò gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ? Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì o!”
Ohun Kejì
Kó má sọ̀rọ̀ mọ́. Leah lè má sọ ìṣòro náà fún àwọn òbí rẹ̀ mọ́.
Ohun Kẹta
Kó dúró dìgbà míì tí wọ́n á ráyè, kó tún wá sọ ọ́. Leah lè pa dà lọ bá dádì rẹ̀ nígbà míì láti sọ̀rọ̀ náà tàbí kó ṣàlàyé ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ sínú lẹ́tà, kó sì fún bàbá rẹ̀.
Èwo ni ìwọ rò pé ó yẹ kí Leah ṣe nínú ohun wọ̀nyí? ․․․․․
Jẹ́ ká gbé ohun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹ̀ wò ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ká sì wo ibi tó ṣeé ṣe kí wọ́n yọrí sí.
Ohun kan gba bàbá Leah lọ́kàn, torí náà kò mọ ìṣòro tí ọmọ rẹ̀ ń bá yí. Tí Leah bá ṣe Ohun Àkọ́kọ́, tó jágbe mọ́ dádì rẹ̀, ìyẹn ò lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ohun tó ṣe yẹn kò ní mú kí dádì ẹ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kò ní pọ́n dádì ẹ̀ lé, kò sì ní fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún un. (Éfésù 6:2) Ó dájú pé èyí ò ní yanjú ọ̀rọ̀ náà bí Leah ṣe fẹ́.
Ó jọ pé Ohun Kejì ló rọrùn jù, àmọ́ ìyẹn kọ́ ló bọ́gbọ́n mu jù. Kí nìdí? Torí pé “àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” (Òwe 15:22) Ó dájú pé kí Leah tó lè yanjú ìṣòro yìí, ó ní láti bá dádì rẹ̀ sọ̀rọ̀, tí dádì rẹ̀ bá sì máa ràn án lọ́wọ́, ó gbọ́dọ̀ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí i. Bó bá wá kọ̀ tí kò sọ ohunkóhun, ìyẹn ò ní yanjú ìkankan nínú méjèèjì.
Àmọ́ tí Leah bá ṣe Ohun Kẹta, tó dúró di ìgbà míì kó tó sọ ohun tó fẹ́ sọ, ìyẹn kò ní jẹ́ kí ìdènà yẹn dá a dúró kó má lè bá dádì rẹ̀ sọ̀rọ̀. Tó bá sì yàn láti kọ lẹ́tà sí dádì rẹ̀, ìyẹn lè mú kí ọ̀rọ̀ náà fúyẹ́ lọ́kàn rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Lẹ́tà yẹn á tún jẹ́ kó lè ṣàlàyé ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Tí bàbá Leah bá ka lẹ́tà náà, á mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ fẹ́ bá a sọ, èyí sì lè mú kó túbọ̀ mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro ọmọ náà. Nípa báyìí, àwọn méjèèjì ni Ohun Kẹta yìí máa ṣe láǹfààní.
Kí làwọn ohun míì tí Leah lè ṣe? Wò ó bóyá wàá lè ronú kan ohun míì tó lè ṣe, kó o sì kọ ọ́ sórí ìlà yìí. Lẹ́yìn náà, wá kọ ibi tó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà yọrí sí.
․․․․․
ÌDÈNÀ KEJÌ Àwọn òbí rẹ fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ kò wù ẹ́ sọ báyìí. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah sọ pé: “Mi ò fẹ́ kí wọ́n máa da ìbéèrè bò mí bí mo bá ṣe ń ti ilé ìwé dé pẹ̀lú gbogbo wàhálà tójú mi ti rí lọ́hùn-ún. Ó máa ń wù mí kí n ṣì gbé ọ̀rọ̀ ilé ìwé kúrò lọ́kàn ná. Àmọ́ bí mo bá ṣe
ń wọlé báyìí, àwọn òbí mi á ti máa bi mí pé: ‘Báwo ni ilé ìwé lónìí? Ṣé kò sí wàhálà?’” Ó dájú pé ohun tó dáa làwọn òbí Sarah ní lọ́kàn tí wọ́n ṣe ń bi í láwọn ìbéèrè yẹn. Síbẹ̀ Sarah sọ pé: “Ó máa ń ni mí lára láti sọ̀rọ̀ ilé ìwé tó bá ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu.”ÌBÉÈRÈ: Kí ni Sarah lè ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí? Bíi ti àpẹẹrẹ tá a gbé yẹ̀ wò ṣáájú, ó kéré tán ohun mẹ́ta wà tó lè ṣe.
Ohun Àkọ́kọ́
Kó má sọ nǹkan kan. Sarah lè sọ pé: “Ẹ wò ó, ọ̀rọ̀ ò wù mí sọ báyìí jàre!”
Ohun Kejì
Kó kàn dáhùn bákan ṣá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ Sarah, ó ṣáà ń dá àwọn òbí rẹ̀ lóhùn lọ́nà kan ṣá.
Ohun Kẹta
Kó fọgbọ́n ti ọ̀rọ̀ nípa iléèwé sígbà míì, àmọ́ kó bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan míì. Sarah lè dábàá pé kí àwọn sọ̀rọ̀ nípa iléèwé nígbà míì, ìyẹn nígbà tí ara á ti tù ú. Ṣùgbọ́n kó béèrè látọkàn wá pé: “Báwo ni iṣẹ́ tiyín lónìí? Ṣé kò le jù?”
Èwo ni ìwọ rò pé ó yẹ kí Sarah ṣe nínú ohun wọ̀nyí? ․․․․․
Jẹ́ ká gbé ohun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹ̀ wò ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ká sì wo ibi tó ṣeé ṣe kí wọ́n yọrí sí.
Ó ti rẹ Sarah, ọ̀rọ̀ ò sì wù ú sọ. Tó bá ṣe Ohun Àkọ́kọ́, ó ṣì máa rẹ̀ ẹ́ náà, á sì tún dá ara rẹ̀ lẹ́bi pé òun pariwo lé àwọn òbí òun lórí.—Òwe 29:11.
Inú àwọn òbí Sarah náà kò ní dùn sí bó ṣe pariwo, inú wọn kò sì ní dùn sí bí kò ṣe ní fẹ́ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn náà. Wọ́n lè máa rò pé Sarah ń fi ohun kan pa mọ́ fún àwọn. Wọ́n tiẹ̀ tún lè máa gbìyànjú láti rí i pé ó ṣáà sọ̀rọ̀, ìyẹn á sì túbọ̀ bí i nínú. Èyí ò ní yanjú ọ̀rọ̀ náà bí Sarah ṣe fẹ́.
Ó ṣe kedere pé Ohun Kejì sàn ju ohun Àkọ́kọ́ lọ. Ó ṣe tán, Sarah àtàwọn òbí rẹ̀ á ṣì máa bá ọ̀rọ̀ wọn lọ. Àmọ́ torí pé ọ̀rọ̀ tí Sarah ń sọ kò ti ọkàn rẹ̀ wá, ara kò ní tu òun àtàwọn òbí rẹ̀, wọn ò sì ní lè jọ sọ̀rọ̀ fàlàlà.
Àmọ́ tí Sarah bá ṣe Ohun Kẹta, ara máa tù ú torí pé ìyẹn á mú kí wọ́n ṣì pa ọ̀rọ̀ nípa ilé ìwé tì ná. Àwọn òbí rẹ̀ máa mọyì rẹ̀ pé ó fẹ́ bá àwọn sọ̀rọ̀, ìyẹn sì máa múnú wọn dùn. Ohun Kẹta yìí ló dà bíi pé ó máa dáa jù, torí á jẹ́ kí Sarah àtàwọn òbí rẹ̀ lè tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Fílípì 2:4, tó sọ pé: “Ẹ má máa mojútó nǹkan ti ara yín nìkan, ṣugbọn kí ẹ máa mojútó nǹkan àwọn ẹlomiran.”—Ìròhìn Ayọ̀.
Má Ṣe Sọ Ohun Tó Máa Túmọ̀ Sí Nǹkan Míì
Rántí pé, lọ́pọ̀ ìgbà, o lè máa sọ ohun kan kó sì jẹ́ pé ọ̀tọ̀ lohun tó máa túmọ̀ sí létí àwọn òbí rẹ. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé àwọn òbí rẹ béèrè pé, “Kí ló ṣe ẹ́ tínú rẹ ò dùn?” O wá dáhùn pé: “Mi ò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ jàre.” Ohun tó lè túmọ̀ sí létí àwọn òbí rẹ ni pé: “Mi ò lè máa bá yín sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ torí mi ò fọkàn tán yín. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ni màá sọ fún.” Gbìyànjú ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí wò, kó o kọ ìdáhùn sórí ìlà tó wà níbẹ̀. Ká ní o ní ìṣòro kan, táwọn òbí rẹ sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Tó o bá sọ pé: “Ẹ má ṣèyọnu. Màá yanjú ẹ̀ fúnra mi.”
Ohun tó lè túmọ̀ sí létí àwọn òbí rẹ ni pé: ․․․․․
Ohun tó máa dáa kó o sọ ni pé: ․․․․․
Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o máa ronú dáadáa kó o tó sọ̀rọ̀. Máa sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. (Kólósè 4:6) Ka àwọn òbí rẹ sí ọ̀rẹ́ rẹ, má ṣe kà wọ́n sí ọ̀tá. Ká sòótọ́, o nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lọ́mọdé àti lágbà láti lè máa yanjú àwọn ìṣòro tó o bá ní.
Tó bá jẹ́ pé bíbá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ kọ́ ni ìṣòro tìẹ, àmọ́ tẹ́ ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀ ṣe lẹ máa ń jiyàn, kí lo lè ṣe?
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Mo sọ̀rọ̀ tààràtà láti inú ọkàn mi láìfi ohunkóhun pa mọ́.”—Jóòbù 33:3, Bíbélì The Holy Bible in the Language of Today, látọwọ́ William Beck.
ÌMỌ̀RÀN
Tó bá ń ṣòro fún ẹ láti jókòó pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan, o lè bá wọn sọ ọ́ nígbà tẹ́ ẹ bá jọ ń rìn lọ síbì kan, tẹ́ ẹ bá jọ wà nínú mọ́tò tàbí nígbà tẹ́ ẹ bá jọ ń lọ sí ọjà.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Bó ṣe lè ṣòro fún ẹ láti bá àwọn òbí rẹ sọ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì, ló ṣe lè má rọrùn fún àwọn náà tí wọ́n bá fẹ́ bá ẹ sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, tàbí kí wọ́n má mọ bí wọ́n tiẹ̀ ṣe máa sọ ọ́.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Tó bá ń ṣe mí bíi pé kí n má sọ nǹkan kan fún àwọn òbí mi, màá ․․․․․
Tí àwọn òbí mi bá ṣáà fẹ́ kí n sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí kò wù mí sọ, màá sọ pé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Tó o bá fẹ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀, kí nìdí tó fi yẹ kó o sọ ọ́ ní àkókò tí ó tọ́?—Òwe 25:11.
● Kí nìdí tó fi yẹ kó o rí i pé ò ń bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀?—Jóòbù 12:12.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]
“Gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń rọrùn láti sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni fún àwọn òbí ẹni, àmọ́ téèyàn bá ti wá sọ ọ́, ṣe lọkàn èèyàn máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ bíi pé èèyàn gbé ẹrù tó wúwo kúrò lọ́kàn.”—Devenye
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Tí wọ́n bá fi nǹkan dí ojú ọ̀nà níbì kan, o ò ní torí ìdènà yẹn pa dà sílé, bákan náà, o ṣì lè wá ọ̀nà míì láti ṣàlàyé ara rẹ fáwọn òbí rẹ!