Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòkọ́ṣe—Lìdíà

Àwòkọ́ṣe—Lìdíà

Àwòkọ́ṣe—Lìdíà

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò tíì pẹ́ tí Lìdíà di Kristẹni, ó lo ìdánúṣe láti gba Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lálejò. (Ìṣe 16:14, 15) Ìyẹn jẹ́ kó lè sún mọ́ àwọn àpọ́sítélì wọ̀nyí dáadáa. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà jáde lẹ́wọ̀n, ibo ni wọ́n forí lé? Ilé Lìdíà ni!—Ìṣe 16:40.

Ṣé ìwọ náà lè máa lo ìdánúṣe láti mọ àwọn ẹlòmíì bíi ti Lìdíà? Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ibi kékeré ni kó o ti bẹ̀rẹ̀. Máa gbìyànjú láti bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan. O tiẹ̀ lè máa fi ṣe àfojúsùn ẹ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnì kan ni gbogbo ìgbà tó o bá ti ń wá sípàdé. Gbìyànjú láti máa rẹ́rìn-ín músẹ́. Bó ò bá mọ ohun tó o lè sọ, béèrè ìbéèrè tàbí kó o sọ nǹkan kan nípa ara ẹ. Máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Tó bá yá, wàá lè máa sọ̀rọ̀ púpọ̀ sí i. Àwọn èèyàn sábà máa ń fèsì dáadáa tá a bá sọ̀rọ̀ tútù tó dùn-ún gbọ́ létí wọn. (Òwe 16:24) Lìdíà láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà torí òun fúnra ẹ̀ ṣeé sún mọ́, ó sì máa ń kóòyàn mọ́ra. Bí ìwọ náà bá fara wé e, wàá láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà!