Bí Ilẹ̀ Ísírẹ́lì Ṣe Rí Nígbà Ayé Dáfídì àti Sólómọ́nì
ỌLỌ́RUN ṣèlérí pé òun á fún irú-ọmọ Ábúrámù ní ilẹ̀ náà “láti odò Íjíbítì dé odò . . . Yúfírétì.” (Jẹ 15:18; Ẹk 23:31; Di 1:7, 8; 11:24) Nǹkan bí irínwó ọdún kọjá lẹ́yìn ìgbà tí Jóṣúà wọ ilẹ̀ Kénáánì, kí Ilẹ̀ Ìlérí tó gbòòrò dé ibi ti Ọlọ́run ṣèlérí.
Dáfídì Ọba ṣẹ́gun ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Árámù ní Sóbà ń ṣàkóso, èyí tó fẹ̀ débi odò Yúfírétì ní ìhà àríwá Síríà. a Ní ìhà gúúsù, ṣíṣẹ́gun tí Dáfídì ṣẹ́gun àwọn Filísínì mú kí ilẹ̀ tó ń ṣàkóso gbòòrò dé ẹnubodè Íjíbítì.—2Sa 8:3; 1Kr 18:1-3; 20:4-8; 2Kr 9:26.
Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì ṣàkóso “láti Odò [Yúfírétì] dé ilẹ̀ àwọn Filísínì àti dé ààlà Íjíbítì.” Àkóso rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ àkóso alálàáfíà ti Mèsáyà náà. (1Ọb 4:21-25; 8:65; 1Kr 13:5; Sm 72:8; Sek 9:10) Síbẹ̀, ohun tí a sábà máa ń sọ ni pé Ísírẹ́lì gbòòrò láti “Dánì dé Bíá-ṣébà.”—2Sa 3:10; 2Kr 30:5.
Sólómọ́nì Ọba ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nípa kíkó àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin jọ. (Di 17:16; 2Kr 9:25) Ó rọrùn fún un láti kó ìwọ̀nyí gba àwọn ọ̀nà àti òpópó tó já síra kọjá. (Joṣ 2:22; 1Ọb 11:29; Ais 7:3; Mt 8:28) Ìwọ̀nba díẹ̀ la mọ̀ nípa àwọn ọ̀nà àti òpópó wọ̀nyí, irú bí “òpópó tí ó gòkè lọ láti Bẹ́tẹ́lì sí Ṣékémù àti síhà gúúsù Lẹ́bónà.”—Ond 5:6; 21:19.
Ìwé The Roads and Highways of Ancient Israel sọ pé: “Ìṣòro kan tí a sábà máa ń ní tí a bá ń ṣàyẹ̀wò bí àwọn ọ̀nà ṣe já síra ní ìlú Ísírẹ́lì ìgbàanì ni pé kò sí àmì tó ṣeé fojú rí mọ́, tí a lè fi mọ bí ojú ọ̀nà orílẹ̀-èdè náà ṣe rí nígbà Májẹ̀mú Láéláé, nítorí pé wọn kì í la títì [ní ìgbà yẹn].” Síbẹ̀, ìrísí àyíká àti àwọn àwókù tí àwọn awalẹ̀pìtàn hú jáde ní ìlú náà fi ẹ̀rí hàn pé ó ṣeé ṣe kí irú àwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀ wà tẹ́lẹ̀ rí.
Bí ọ̀nà bá ṣe rí ló ń pinnu ibi tí àwọn agbo ọmọ ogun á gbà kọjá. (1Sa 13:17, 18; 2Ọb 3:5-8) Kí àwọn Filísínì bàa lè gbógun ti Ísírẹ́lì, wọ́n gba Ékírónì àti Gátì kọjá lọ sí àgbègbè tó wà ní “àárín Sókóhì àti Ásékà.” Àwọn ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù sì pàdé wọn níbẹ̀ ní “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Éláhì.” Lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì, àwọn Filísínì sá padà lọ sí Gátì àti Ékírónì, Dáfídì sì gòkè padà lọ sí Jerúsálẹ́mù.—1Sa 17:1-54.
Ibi àwọn ojú ọ̀nà àdáyébá tó gba Ṣẹ́fẹ́là kọjá lọ sí àwọn òkè Jùdíà ni Lákíṣì (E10), Ásékà (E9) àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì (E9) wà. Ìyẹn ló mú kí àwọn ìlú wọ̀nyí jẹ́ ibi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lè bẹ́gi dínà àwọn ọ̀tá tí wọ́n bá gba Ojú Ọ̀nà Òkun kọjá láti wá gbógun ja ìlú wọn.—1Sa 6:9, 12; 2Ọb 18:13-17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Rúbẹ́nì gbòòrò dé ibi Aṣálẹ̀ Síríà. Ní ìkángun ìlà oòrùn aṣálẹ̀ yìí ni odò Yúfírétì wà.—1Kr 5:9, 10.
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 17]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Àwọn Àgbègbè àti Ojú Ọ̀nà Ní Àkókò Àwọn Ọba
Àwọn Ààlà (Lákòókò Sólómọ́nì)
Tífísà
Hámátì
Tádímórì
Bérótáì (Kúnì?)
Sídónì
Damásíkù
Tírè
Dánì
Jerúsálẹ́mù
Gásà
Áróérì
Bíá-ṣébà
Támárì
Esioni-gébérì
Élátì (Élótì)
[Àwọn Odò]
Yúfírétì
A. O. Íjíbítì
Dáfídì àti Sólómọ́nì (àwọn ọ̀nà)
B10 Gásà
D8 Jópà
D9 Áṣídódì
D10 Áṣíkẹ́lónì
D11 Síkílágì
D12 AGINJÙ PÁRÁNÌ
E5 Dórì
E6 Héfà
E8 Áfékì
E8 Rámà
E9 Ṣáálíbímù
E9 Gésérì
E9 Mákásì
E9 Ékírónì
E9 Bẹti-ṣémẹ́ṣì
E9 Gátì
E9 Ásékà
E10 Sókò(hì)
E10 Ádúlámù
E10 Kéílà
E10 Lákíṣì
E11 Játírì
E12 Bíá-ṣébà
Ẹ2 Tírè
Ẹ4 Kábúlù
Ẹ5 Jókínéámù (Jókíméámù?)
Ẹ5 Mẹ́gídò
Ẹ6 Táánákì
Ẹ6 Árúbótì
Ẹ7 Pírátónì
Ẹ8 Lébónà
Ẹ8 Sérédà
Ẹ8 Bẹ́tẹ́lì
Ẹ9 Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀
Ẹ9 Bẹti-hórónì Òkè
Ẹ9 Gébà
Ẹ9 Gíbéónì
Ẹ9 Gíbíà
Ẹ9 Kiriati-jéárímù
Ẹ9 Nóbù
Ẹ9 Baali-pérásímù
Ẹ9 Jerúsálẹ́mù
Ẹ9 Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
Ẹ10 Tékóà
Ẹ10 Hébúrónì
Ẹ11 Sífù
Ẹ11 Hóréṣì?
Ẹ11 Kámẹ́lì
Ẹ11 Máónì
Ẹ11 Éṣítémóà
F5 Ẹ́ń-dórì
F5 Ṣúnémù
F5 Jésíréélì
F6 Bẹti-ṣéánì
F7 Tírísà
F7 Ṣékémù
F8 Sárétánì
F8 Ṣílò
F8 Ọ́fírà?
F9 Jẹ́ríkò
F11 Ẹ́ń-gédì
G2 Ebẹli-bẹti-máákà
G2 Dánì
G3 Hásórì
G3 MÁÁKÀ
G5 Lo-débárì (Débírì)
G5 Rógélímù
G6 Ebẹli-méhólà
G7 Súkótù
G7 Máhánáímù
GB1 SÍRÍÀ
GB4 GÉṢÚRÌ
GB6 Ramoti-gílíádì
GB8 Rábà
GB9 Médébà
GB11 Áróérì
GB12 MÓÁBÙ
I4 Hélámù?
I9 ÁMÓNÌ
[Ojú Ọ̀nà Pàtàkì]
D10 Ojú Ọ̀nà Òkun
GB6 Ojú Ọ̀nà Ọba
[Àwọn Òkè]
F5 Òkè Gíbóà
[Omi]
D8 Òkun Mẹditaréníà (Òkun Ńlá)
F10 Òkun Iyọ̀ (Òkun Òkú)
G4 Òkun Gálílì
[Ìsun Omi tàbí Kànga]
Ẹ9 Ẹ́ń-rógélì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Lápá ọ̀tún: Àfonífojì Éláhì tó dojú kọ àwọn òkè Júdà tó wà ní ìhà ìlà oòrùn
Ìsàlẹ̀: Àwọn ojú ọ̀nà tó já síra mú kó ṣeé ṣe láti rìn yí ká Ilẹ̀ Ìlérí