Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 80

Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá

Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá

Ní báyìí tí Jésù ti ń wàásù fún nǹkan bí ọdún kan àti ààbọ̀, ó ti tó àkókò pé kó yan àwọn tí wọ́n á jọ máa ṣiṣẹ́, ìpinnu ńlá sì nìyẹn. Àwọn wo ló máa wá yàn? Àwọn wo ló sì máa dá lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa mú ipò iwájú nínú ìjọ Kristẹni? Jésù ò fẹ́ dá ṣe àwọn ìpinnu yẹn, ó fẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà. Torí náà, ó lọ sórí òkè kan kó lè dá wà, ó sì gbàdúrà ní gbogbo òru mọ́jú. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jésù pe àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì yan méjìlá [12] lára wọn láti di àpọ́sítélì. Èwo nínú wọn lo rántí orúkọ rẹ̀? Ó dára, orúkọ wọn ni Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù, Jòhánù, Fílípì, Bátólómíù, Tọ́másì, Mátíù, Jákọ́bù ọmọ Álífíọ́sì, Tádéọ́sì, Símónì àti Júdásì Ísíkáríótù.

Áńdérù, Pétérù, Fílípì, Jákọ́bù

Àwọn Méjìlá [12] yìí lá máa rìnrìn-àjò pẹ̀lú Jésù. Lẹ́yìn tí Jésù ti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó rán wọn jáde pé kí wọ́n lọ wàásù. Jèhófà fún wọn ní agbára láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kí wọ́n sì wo àwọn aláìsàn sàn.

Jòhánù, Mátíù, Bátólómíù, Tọ́másì

Jésù pe àwọn Méjìlá [12] yìí ní ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì fọkàn tán wọn. Àwọn Farisí gbà pé àwọn àpọ́sítélì yẹn kò lọ sí ilé ìwé àti pé tálákà ni wọ́n. Àmọ́, Jésù kọ́ wọn dáadáa kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ wọn ní àṣeyọrí. Àwọn ló wà pẹ̀lú rẹ̀ ní àwọn àsìkò tó ṣe pàtàkì jù ní ìgbésí ayé rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ kó tó kú, wọ́n sì tún wà pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìn tó jíǹde. Gálílì tó jẹ́ ìlú Jésù ni èyí tó pọ̀ jù lára wọn ti wá, àwọn kan sì ti ní ìyàwó.

Jákọ́bù ọmọ Álífíọ́sì, Júdásì Ísíkáríótù, Tádéọ́sì, Símónì

Àwọn àpọ́sítélì yìí kì í ṣe ẹni pípé, torí náà wọ́n máa ń ṣe àṣìṣe. Nígbà míì, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ láìronú, wọ́n máa ń ṣe àwọn ìpinnu tí kò dáa, wọn ò ní sùúrù, wọ́n sì máa ń jiyàn nípa ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọ̀gá láàárín wọn. Àmọ́, èèyàn dáadáa ni wọ́n, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àwọn ló máa bẹ̀rẹ̀ ìjọ Kristẹni lẹ́yìn tí Jésù bá lọ sí ọ̀run.

“Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí pé gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi ni mo ti sọ di mímọ̀ fún yín.”​—Jòhánù 15:15