Ẹ̀KỌ́ 15
Báwo Ni Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Ran Ìjọ Lọ́wọ́?
A kò ní àwọn àlùfáà tó ń gba owó nínú ètò wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a yan àwọn alábòójútó tó kúnjú ìwọ̀n sípò “láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run” bíi ti ìgbà tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 20:28) Àwọn alàgbà yìí jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run gan-an, wọ́n ń mú ipò iwájú nínú ìjọ, wọ́n sì ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn, ‘kì í ṣe tipátipá àmọ́ tinútinú níwájú Ọlọ́run; kì í ṣe nítorí èrè tí kò tọ́, àmọ́ wọ́n ń fi ìtara ṣe é látọkàn wá.’ (1 Pétérù 5:1-3) Àwọn iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe nítorí wa?
Wọ́n ń bójú tó wa, wọ́n sì ń dáàbò bò wá. Àwọn alàgbà ń tọ́ wa sọ́nà, wọ́n sì ń mú kí ìjọ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn alàgbà mọ̀ pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé àwọn lọ́wọ́ ṣe pàtàkì, torí náà wọn kì í jọ̀gá lé àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń mú kí àlàáfíà àti ayọ̀ wa pọ̀ sí i. (2 Kọ́ríńtì 1:24) Bí olùṣọ́ àgùntàn kan ṣe ń tọ́jú àwọn àgùntàn rẹ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn alàgbà ṣe ń sapá láti mọ gbogbo ará ìjọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Òwe 27:23.
Wọ́n ń kọ́ wa bí a ṣe lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn alàgbà máa ń darí àwọn ìpàdé ìjọ láti mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. (Ìṣe 15:32) Àwọn ọkùnrin tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn yìí tún máa ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wa lóde ẹ̀rí, wọ́n sì ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nínú gbogbo ọ̀nà tí à ń gbà wàásù.
Wọ́n ń fún wa ní ìṣírí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Nítorí kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, àwọn alàgbà máa ń bẹ̀ wá wò ní ilé wa tàbí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láti fi Ìwé Mímọ́ tù wá nínú, kí wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́.—Jémíìsì 5:14, 15.
Yàtọ̀ sí iṣẹ́ wọn nínú ìjọ, ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà tún ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ojúṣe nínú ìdílé tó ń gba àkókò àti àfiyèsí wọn. Ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn arákùnrin wa tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára yìí.—1 Tẹsalóníkà 5:12, 13.
-
Kí ni iṣẹ́ àwọn alàgbà ìjọ?
-
Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà ń gbà fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?