Ẹ̀KỌ́ 14
Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Wà fún Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà
Ọjọ́ pẹ́ tí ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ ti jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ètò Ọlọ́run ṣètò ilé ẹ̀kọ́ lákànṣe fún àwọn tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n lè ‘ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láìkù síbì kan.’—2 Tímótì 4:5.
Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà. Tó bá ti pé ọdún kan tí ẹnì kan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́fà tó ṣeé ṣe kó wáyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí kò jìnnà sí agbègbè rẹ̀. Ilé ẹ̀kọ́ náà máa jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, á jẹ́ kó túbọ̀ mọ bí a ṣe ń wàásù, kó sì máa fi òtítọ́ bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lọ.
Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere. A dá ilé ẹ̀kọ́ olóṣù méjì yìí sílẹ̀ láti dá àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó nírìírí lẹ́kọ̀ọ́, àwọn tó ṣe tán láti fi agbègbè wọn sílẹ̀, kí wọ́n lè lọ sìn ní ibikíbi tí ètò Ọlọ́run bá ti nílò wọn. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń sọ pé, “Èmi nìyí! Rán mi!” Wọ́n fìwà jọ Ajíhìnrere tó ga jù lọ tó gbé ayé rí, ìyẹn Jésù Kristi. (Àìsáyà 6:8; Jòhánù 7:29) Wọ́n lè ní láti fi àwọn nǹkan kan du ara wọn torí pé ibi tí wọ́n wà jìnnà sí ìlú wọn. Àṣà ìbílẹ̀ ibi tí wọ́n kó lọ lè yàtọ̀ pátápátá, títí kan ojú ọjọ́ àti oúnjẹ. Ó sì lè pọn dandan pé kí wọ́n kọ́ èdè tuntun. Ilé ẹ̀kọ́ yìí máa jẹ́ kí àwọn àpọ́n, àwọn obìnrin tí kò lọ́kọ àti àwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23) sí márùndínláàádọ́rin (65) ní àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni tó máa wúlò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn. Wọ́n á tún kọ́ àwọn ohun táá jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àti ètò rẹ̀.
Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ní èdè Hébérù, “Gílíádì” túmọ̀ sí “Òkìtì Ẹ̀rí.” Láti ọdún 1943 tí a ti dá ilé ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀, a ti rán àwọn míṣọ́nnárì tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ (8,000) tí wọ́n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti lọ máa wàásù káàkiri “gbogbo ayé,” wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí lọ́pọ̀lọpọ̀. (Ìṣe 13:47) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn míṣọ́nnárì kọ́kọ́ dé orílẹ̀-èdè Peru, kò sí ìjọ kankan níbẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, ìjọ tó wà níbẹ̀ ti lé ní ẹgbẹ̀rún (1,000). Nígbà táwọn míṣọ́nnárì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní ilẹ̀ Japan, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ kò tó mẹ́wàá. Àmọ́ ní báyìí wọ́n ti lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000). Oṣù márùn-ún ni wọ́n fi ń lọ sí Ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ níbẹ̀. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní pápá, àwọn tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tàbí àwọn alábòójútó àyíká ló máa ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí kí wọ́n lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀ táá jẹ́ kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù fẹsẹ̀ múlẹ̀, kó sì gbòòrò sí i kárí ayé.
-
Kí nìdí tá a fi ṣètò Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà?
-
Àwọn wo ló lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere?