Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 11

Kí Nìdí Tí A Fi Ń Lọ sí Àwọn Àpéjọ Ńlá?

Kí Nìdí Tí A Fi Ń Lọ sí Àwọn Àpéjọ Ńlá?

Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

Orílẹ̀-èdè Jámánì

Orílẹ̀-èdè Botswana

Orílẹ̀-èdè Nicaragua

Orílẹ̀-èdè Ítálì

Kí nìdí tínú àwọn èèyàn yìí fi ń dùn? Torí pé wọ́n wà ní ọ̀kan lára àwọn àpéjọ wa ni. Bíi ti àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́, tí Ọlọ́run sọ fún pé kí wọ́n máa pé jọ lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún, àwa náà máa ń fojú sọ́nà fún àwọn ìgbà tá a máa ń lọ sí àpéjọ ńlá. (Diutarónómì 16:16) Àpéjọ mẹ́ta la máa ń ṣe lọ́dọọdún, àwọn ni: àpéjọ àyíká ọlọ́jọ́ kan, tó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀méjì àti àpéjọ agbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta. Báwo ni àwọn àpéjọ yìí ṣe ń ṣe wá láǹfààní?

Wọ́n ń mú kí ẹgbẹ́ ará wa túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Bí inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń yin Jèhófà ní “àwọn àpéjọ,” bẹ́ẹ̀ náà ni inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá ń jọ́sìn rẹ̀ láwọn àpéjọ pàtàkì. (Sáàmù 26:12, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé; 111:1) Àwọn àpéjọ yìí máa ń jẹ́ ká lè pàdé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti àwọn ìjọ míì tàbí àwọn orílẹ̀-èdè míì pàápàá, ká sì jọ fara rora. Ní ọ̀sán, a máa ń jẹun pa pọ̀ ní gbọ̀ngàn àpéjọ wa, èyí sì ń jẹ́ ká túbọ̀ gbádùn àjọṣe alárinrin láwọn àpéjọ náà. (Ìṣe 2:42) Láwọn àpéjọ yìí, a máa ń fojú ara wa rí ìfẹ́ tó so “gbogbo àwọn ará” wa pọ̀ kárí ayé.​—1 Pétérù 2:17.

Wọ́n ń mú ká tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jàǹfààní torí pé ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ṣàlàyé fún wọn “yé wọn.” (Nehemáyà 8:8, 12) Àwa náà mọyì ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a máa ń kọ́ láwọn àpéjọ wa. Inú Bíbélì la ti mú àwọn ẹ̀kọ́ náà. À ń kọ́ bá a ṣe lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láyé wa látinú àwọn àsọyé alárinrin, àpínsọ àsọyé àtàwọn àṣefihàn ohun tó ṣẹlẹ̀. Tá a bá gbọ́ bí àwọn ará wa ṣe ń fara da ìṣòro tó ń dé bá àwọn Kristẹni tòótọ́ lásìkò tí nǹkan nira yìí, ó máa ń fún wa ní ìṣírí. Ní àwọn àpéjọ agbègbè wa, àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ máa ń mú kí àwọn ìtàn inú Bíbélì túbọ̀ ṣe kedere, wọ́n sì ń kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò. Ní gbogbo àpéjọ, a máa ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn tó fẹ́ fi hàn pé àwọn ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

  • Kí nìdí tí àwọn àpéjọ wa fi máa ń fún wa láyọ̀?

  • Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá wá sí àpéjọ wa?