Ẹ̀KỌ́ 7
Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
1. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?
Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan ní ọ̀run. Òun ló máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn, á sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ọ̀run àti ayé. Ìròyìn ayọ̀ lọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run jẹ́. Ìjọba Ọlọ́run máa tó ṣe gbogbo ohun tí àwa èèyàn ń fẹ́ kí ìjọba rere ṣe fún wa. Ó máa mú kí gbogbo èèyàn tó wà láyé wà níṣọ̀kan.—Ka Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10; 24:14.
Ìlú kì í wà láìní olórí. Jèhófà ti yan Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run.—Ka Ìfihàn 11:15.
Wo Fídíò náà Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
2. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù ni Ọba tọ́ sí?
Ọmọ Ọlọ́run ni Ọba tọ́ sí torí pé ó jẹ́ onínúure, ó sì máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo. (Mátíù 11:28-30) Yàtọ̀ síyẹn, ó lágbára láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ torí pé ọ̀run ló ti máa ṣàkóso ayé. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run jí i dìde, ó lọ sí ọ̀run ó sì jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà. (Hébérù 10:12, 13) Nígbà tó yá, Ọlọ́run fún un láṣẹ pé kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso.—Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14.
3. Àwọn wo ló máa bá Jésù jọba?
Àwọn kan tí Bíbélì pè ní àwọn “ẹni mímọ́” máa bá Jésù jọba ní ọ̀run. (Dáníẹ́lì 7:27) Àwọn àpọ́sítélì Jésù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ni àwọn ẹni mímọ́ tí Ọlọ́run kọ́kọ́ yàn. Títí di àkókò wa yìí, Jèhófà ń yan àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àti obìnrin kí wọ́n lè wà lára àwọn ẹni mímọ́. Bíi ti Jésù, Ọlọ́run ń jí wọn dìde gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí.—Ka Jòhánù 14:1-3; 1 Kọ́ríńtì 15:42-44.
Lúùkù 12:32) Iye wọn máa jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000). Wọ́n máa bá Jésù jọba lórí ayé.—Ka Ìfihàn 14:1.
Àwọn mélòó ló máa lọ sí ọ̀run? Jésù pè wọ́n ní “agbo kékeré.” (4. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í jọba?
Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọdún 1914. * Ohun tí Jésù kọ́kọ́ ṣe lẹ́yìn tó di Ọba ni pé ó lé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀run wá sí ayé. Inú bí Sátánì gan-an, ó sì wá ń dá wàhálà sílẹ̀ ní gbogbo ayé. (Ìfihàn 12:7-10, 12) Látìgbà yẹn, ìṣòro tó ń bá aráyé fínra kọjá àfẹnusọ. Ogun, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìmìtìtì ilẹ̀ wà lára “àmì” tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé pátá.—Ka Lúùkù 21:7, 10, 11, 31.
5. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe?
Ìjọba Ọlọ́run ń lo iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe kárí ayé láti mú kí ogunlọ́gọ̀ èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè wà níṣọ̀kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn tútù ti ń fi ara wọn sábẹ́ àkóso Jésù. Ìjọba Ọlọ́run máa dáàbò bò wọ́n nígbà tó bá pa ayé búburú yìí run. Torí náà, gbogbo àwọn tó bá fẹ́ wọnú Ìjọba Ọlọ́run ní láti máa ṣègbọràn sí Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run.—Ka Ìfihàn 7:9, 14, 16, 17.
Láàárín ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún, Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ fún aráyé. Gbogbo ayé máa di Párádísè. Níkẹyìn, Jésù á dá Ìjọba náà pa dà fún Baba rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:24-26) Ǹjẹ́ ẹnì kan wà tó wù ẹ́ kó o sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún?—Ka Sáàmù 37:10, 11, 29.
^ ìpínrọ̀ 6 Tó o bá fẹ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe tọ́ka sí ọdún 1914, wo ojú ìwé 217 sí 220 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?