Ẹ̀KỌ́ 2
Ta Ni Ọlọ́run?
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká sin Ọlọ́run?
Ọlọ́run tòótọ́ ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Kò ní ìbẹ̀rẹ̀, kò sì lè ní òpin láé. (Sáàmù 90:2) Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì ti wá. (1 Tímótì 1:11) Torí pé Ọlọ́run ló jẹ́ ká wà láàyè, òun nìkan ló yẹ ká máa sìn.—Ka Ìfihàn 4:11.
2. Irú ẹni wo ni Ọlọ́run?
Kò sí èèyàn kankan tó rí Ọlọ́run rí torí pé Ẹ̀mí ni. Èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ga ju gbogbo àwọn nǹkan tó dá sí ayé. (Jòhánù 1:18; 4:24) Àmọ́, a lè mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ látinú àwọn nǹkan tó dá. Bí àpẹẹrẹ, oríṣiríṣi èso àtàwọn òdòdó tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní ìfẹ́ àti ọgbọ́n. Bí ayé yìí ṣe tóbi àti bí ojú ọ̀run ṣe lọ salalu jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní agbára.—Ka Róòmù 1:20.
A tún lè mọ púpọ̀ sí i nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ tá a bá ń ka Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́, bó ṣe máa ń ṣe sí àwa èèyàn àti ohun tó máa ń ṣe nínú àwọn ipò tó yàtọ̀ síra.—Ka Sáàmù 103:7-10.
3. Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ?
Jésù sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, orúkọ kan ṣoṣo ló ní. Bí àwọn èèyàn ṣe máa ń pe orúkọ yìí ní èdè kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Ní èdè Yorùbá, a máa ń pè é ní “Jèhófà.” Àmọ́ àwọn míì máa ń pè é ní “Yahweh.”—Ka Sáàmù 83:18.
Àwọn kan ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, wọ́n sì fi orúkọ oyè bí Olúwa tàbí Ọlọ́run rọ́pò rẹ̀. Àmọ́, nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Bíbélì. Jésù jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run nígbà tó kọ́ wọn nípa Ọlọ́run.—Ka Jòhánù 17:26.
Wo Fídíò náà Ṣé Ọlọ́run ní Orúkọ?
4. Ǹjẹ́ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa?
Ṣé bí ìyà ṣe ń jẹ àwọn èèyàn fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ wa? Àwọn kan sọ pé ṣe ni Ọlọ́run ń fi ìyà tó ń jẹ wá dán wa wò, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá.—Ka Jémíìsì 1:13.
Ọlọ́run pọ́n àwa èèyàn lé, ó gbà wá láyè pé ká pinnu ohun tó wù wá. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé Ọlọ́run fún wa láǹfààní láti pinnu bóyá a máa sin òun tàbí a ò ní sin òun? (Jóṣúà 24:15) Àmọ́, ọ̀pọ̀ ló yàn láti máa ṣe ohun tó burú sí àwọn ẹlòmíì, ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń jìyà. Inú Jèhófà ò dùn rárá sí ìwà àìtọ́ tí wọ́n ń hù yìí.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6.
Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ó fẹ́ ká gbádùn ayé wa dáadáa. Láìpẹ́, ó máa gbà wá lọ́wọ́ ìyà, ó sì máa pa àwọn tó ń fìyà jẹ aráyé run. Àmọ́, ó ní ìdí pàtàkì tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé fúngbà díẹ̀. A máa mọ ohun tó fà á ní Ẹ̀kọ́ 8.—Ka 2 Pétérù 2:9; 3:7, 13.
5. Báwo ni a ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?
Jèhófà ní ká máa gbàdúrà sí òun ká lè sún mọ́ òun. Ó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Sáàmù 65:2; 145:18) Ó ṣe tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Ó rí gbogbo bá a ṣe ń sapá ká lè ṣe ohun tó wu òun, kódà bá a tiẹ̀ ṣàṣìṣe láwọn ìgbà míì. Torí náà, bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, a ṣì lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.—Ka Sáàmù 103:12-14; Jémíìsì 4:8.
Torí pé Jèhófà ló jẹ́ ká wà láàyè, òun ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ju ẹnikẹ́ni lọ. (Máàkù 12:30) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run, tó o sì ń ṣe ohun tó fẹ́, èyí ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wàá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn.—Ka 1 Tímótì 2:4; 1 Jòhánù 5:3.