ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ
Iroyin Nipa Awon Ejo
ORÍLẸ̀-ÈDÈ ÀMÉNÍÀ Ìjọba Fún Àwọn Kristẹni Láǹfààní Láti Ṣe Iṣẹ́ Àṣesìnlú Tí Kò Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Lọ́wọ́ sí Ogun
Ní ọdún 2013, ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà dá ètò iṣẹ́ àṣesìnlú sílẹ̀, èyí tó fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè náà láǹfààní láti yan iṣẹ́ àṣesìnlú dípò kí wọ́n lọ sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun. Ní oṣù January ọdún 2014, ẹ̀ka ọ́fíìsì ròyìn pé àwọn arákùnrin mọ́kànléláàádọ́rin [71] ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àṣesìnlú tí ìjọba ṣẹ̀sẹ̀ dá sílẹ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ìjọba ní kí àwọn arákùnrin kan máa ṣiṣẹ́ nílé ìdáná, kí àwọn kan sì máa ran àwọn nọ́ọ̀sì lọ́wọ́ nílé ìwòsàn. Àwọn ọ̀gá tí ìjọba yàn láti máa ṣe kòkáárí iṣẹ́ náà sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wúni lórí nípa irú ọwọ́ tí àwọn arákùnrin wa fi mú àwọn iṣẹ́ tó sábà máa ń nira tí wọ́n yàn fún wọn àti bí wọ́n ṣe máa ń ṣiṣẹ́ kára. Àwọn arákùnrin yìí mọyì bí wọ́n ṣe fún wọn láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú kí wọ́n lè máa bá a nìṣó láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. * Ọ̀kan lára wọn sọ pé, “A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé a láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú tí kò mú ká lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ológun tó sì tún jẹ́ ká lómìnira láti máa sìn ín.”
ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN Fún Ìgbà Àkọ́kọ́, Ìjọba Fọwọ́ Sí Ìgbéyàwó Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣe, Yàtọ̀ sí Ti Àwọn Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì
Lọ́dún 1954, ìjọba Orílẹ̀-èdè Dominican tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkí, wọ́n sì fàṣẹ sí i pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nìkan ni ẹ̀sìn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti so tọkọtaya pọ̀ lábẹ́ òfin. Bí tọkọtaya kan kò bá ṣègbéyàwó wọn ní Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, aṣojú ìjọba ní ọ́fíìsì tí wọ́n ti ń forúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ ló tún lè so wọ́n pọ̀. Àmọ́ lọ́dún 2010, ìjọba fọwọ́ sí òfin tuntun kan tó fún àwọn aṣojú tó bá kúnjú ìwọ̀n látinú àwọn ẹ̀sìn míì láṣẹ láti so tọkọtaya pọ̀. Ìjọba sì ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn tó bá fẹ́ gba àṣẹ yìí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Orílẹ̀-èdè Dominican yan ọgbọ̀n [30] alàgbà láti lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà. Àmọ́ àwọn méjìlélọ́gbọ̀n [32] péré ni ìjọba fọwọ́ sí pé wọ́n kúnjú ìwọ̀n lára ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] èèyàn tó wá fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà. Gbogbo ọgbọ̀n [30] alàgbà tó lọ sì wà lára àwọn tí ìjọba fún láṣẹ láti máa so tọkọtaya tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí pọ̀ lábẹ́ òfin.
ORÍLẸ̀-ÈDÈ ÍŃDÍÀ Wọ́n Pinnu Láti Máa Fìgboyà Wàásù
Ní January 27, ọdún 2014, Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Ìpínlẹ̀ Karnataka kéde pé Ọ̀gá Ọlọ́pàá Kékeré kan ní Àgọ́ Ọlọ́pàá ti ìlú Old Hubli ní ìpínlẹ̀ Karnataka ti fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du Arákùnrin Sundeep Muniswamy torí pé kò dáàbò bo arákùnrin náà nígbà táwọn jàǹdùkú gbéjà kò ó ní June 28, ọdún 2011. Àjọ náà dá ọ̀gá ọlọ́pàá yìí lẹ́bi fún bí wọ́n ṣe fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du arákùnrin
yìí, ó pàṣẹ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Karnataka pé kí wọ́n fi ìyà tó tọ́ jẹ ọ̀gá ọlọ́pàá náà, ó sì tún ní kí wọ́n san ọ̀kẹ́ kan [20,000] owó rupee (nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000] náírà) gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn fún Arákùnrin Muniswamy. Àjọ náà pàṣẹ pé kí ìjọba yọ owó ìtanràn yìí nínú owó oṣù ọ̀gá ọlọ́pàá náà.Arákùnrin Muniswamy sọ pé òun àti ìdílé òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìdájọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí, àwọn sì pinnu láti máa fìgboyà bá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà nìṣó. Ìdájọ́ yìí ti fún ìgbàgbọ́ àwọn ará lókun, ó sì jẹ́ kó túbọ̀ dá wọn lójú pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. Ìkìlọ̀ tó lágbára ló tún jẹ́ fún àwọn aláṣẹ láti máa rí sí i pé ẹnikẹ́ni kò fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìpínlẹ̀ Karnataka. Ọ̀ràn nípa ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Muniswamy àti arákùnrin míì, lórí ọ̀rọ̀ kan náà ṣì wà nílé ẹjọ.
ORÍLẸ̀-ÈDÈ KYRGYZSTAN Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Fọwọ́ sí Ẹ̀tọ́ Láti Kọ Ohun Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ẹni Kò Gbà Láyè
Ọjọ́ mánigbàgbé ni November 19, ọdún 2013 jẹ́ fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti wọṣẹ́ ológun. Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dá ẹjọ́ tó kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́kànlá [11], wọ́n sì kéde pé ètò tí ìjọba orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ṣe fún iṣẹ́ àṣesìnlú kò bófin mu. Òfin tí wọ́n gbé kalẹ̀ lórílẹ̀-èdè yìí ni pé àwọn tó bá ń ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú ní láti máa san owó sínú àpò àwọn ológun láti ti iṣẹ́ ológun lẹ́yìn. Òfin náà tún sọ pé tí gbogbo àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun bá ti parí iṣẹ́ àṣesìnlú, wọ́n tún gbọ́dọ̀ lọ forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ológun gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun tí wọ́n lè ké sí bí lílò bá kàn wọ́n. Ìgbìmọ̀ Aṣòfin yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ṣe ni wọ́n fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn láti ṣe ẹ̀sìn tó wu kálukú du àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun tí wọ́n bá fipá mú wọn ṣiṣẹ́ sin ìlú lọ́nà tí wọ́n là kalẹ̀ yẹn. Torí náà, ní àwọn oṣù tó bẹ̀rẹ̀ ọdún 2014, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Kyrgyzstan tẹ̀ lé ohun tí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin sọ yìí, wọ́n sì dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìnlá [14] tí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn lábẹ́ òfin sílẹ̀. Bí wọ́n ṣe dá wa láre yìí fòpin sí ẹjọ́ tó ti wà nílẹ̀ fún ọdún méje gbáko torí ká lè ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wá àti ohun tí ẹ̀rí ọkàn wa gbà wá láyè. Bí àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n lẹ́mìí àlàáfíà yìí ṣe rọ̀ mọ́ ìpinnu wọn ti gbé orúkọ Jèhófà ga, ó sì jẹ́ ká túbọ̀ ní òmìnira láti máa bá ìjọsìn wa lọ lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan.
ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ “Jèhófà Ti San Mí Lẹ́san”
Ní Ìpínlẹ̀ Abia, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, wọ́n sábà máa ń halẹ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọn kì í sì í fẹ́ bá wọn da nǹkan pọ̀ torí pé wọ́n kọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ orí-ò-jorí tí wọ́n ń pè ní age-grade. * Ìwà ipá àti ààtò ẹ̀sìn ẹ̀mí òkùnkùn máa ń wà lára ohun táwọn ẹgbẹ́ yìí ń ṣe. Ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kan lóṣù November ọdún 2005, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yìí tó wà ní abúlé Asaga Ohafia digun lọ sílé Arákùnrin Emmanuel Ogwo àti ìyàwó rẹ̀, wọ́n sì fipá gba gbogbo ohun ìní wọn. Wọ́n ní ẹrù wọn làwọn máa fi dí gbogbo owó ẹgbẹ́ tó ti yẹ kí wọ́n san. Gbogbo ohun tó kù tí tọkọtaya náà ní kò ju ẹ̀wù ọrùn wọn lọ. Nígbà tó fi máa di ọdún 2006, wọ́n lé Arákùnrin Ogwo kúrò ní ilé rẹ̀ àti ní abúlé náà. Arákùnrin kan ní abúlé míì ló gba Arákùnrin àti Arábìnrin Ogwo sílé, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti ń tọ́jú wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arákùnrin Ogwo pa dà sí ilé rẹ̀ lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọn ò yéé fúngun mọ́ ọn pé kó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà, wọ́n sì tún kọ̀ jálẹ̀ láti dá ẹrù rẹ̀ pa dà.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ilé Ẹjọ́ Gíga ti Ìpínlẹ̀ Abia dá Arákùnrin Ogwo láre ní April 15, ọdún 2014, wọ́n sì gbèjà ẹ̀tọ́ tó ní lábẹ́ òfin láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àti ẹ̀sìn tó bá wù ú. Wọ́n ti dá àwọn ẹrù Arákùnrin Ogwo tí wọ́n fipá gbà pa dà. Wọn kì í sì í yẹra fún àwọn Ẹlẹ́rìí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ ní abúlé náà. Ní báyìí àwọn ará wa ti ń wàásù fàlàlà ní abúlé Asaga Ohafia.
Nígbà tí ilé ẹjọ́ kéde ìdájọ́ wọn, Arákùnrin Ogwo sọ pé: “Inú mi dùn gan-an. Mo fò sókè. Mo sọ lọ́kàn mi pé Jèhófà ti jàre ẹjọ́ náà àti pé àwọn ańgẹ́lì ò fi mí sílẹ̀. Jèhófà ti san mí lẹ́san.”
ORÍLẸ̀-ÈDÈ RỌ́ṢÍÀ Ilé Ẹjọ́ Mú Òfin Tí Wọ́n Fi De Ìkànnì jw.org Kúrò
Ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kan àwọn ará wa lábẹ́ òfin nílẹ̀ Rọ́ṣíà “ti yọrí sí ìlọsíwájú ìhìn rere” lórílẹ̀-èdè náà. (Fílí. 1:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan àtàwọn olórí ẹ̀sìn ń ṣàtakò tó gbóná janjan sí ìjọsìn wa, àwọn ará wa nílẹ̀ Rọ́ṣíà ń pa ìwà títọ́ wọn mọ́, Jèhófà sì ń bù kún ìsapá wọn.
Ẹjọ́ tá a jàre rẹ̀ nílùú Tver jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn. Lọ́dún 2013, agbẹjọ́rò ìjọba nílùú Tver mú ẹ̀sùn lọ sílé ẹjọ́ kan ní àdúgbò kí ìjọba lè fòfin de ìkànnì jw.org jákèjádò orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ilé ẹjọ́ dá agbẹjọ́rò náà láre láìfi ọ̀rọ̀ ìgbẹ́jọ́ náà tó èyíkéyìí lára àwọn aṣojú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà létí. Nígbà tí àwọn ará wa gbọ́ nípa ìdájọ́ yìí, wọ́n pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Ní January 22, ọdún 2014, Ilé Ẹjọ́ Ẹlẹ́kùnjẹkùn ti Ìlú Tver yí ìdájọ́ wọ́n sì dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti ẹgbẹ́ ará kárí ayé tí wọn ò dákẹ́ àdúrà. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará wa nílẹ̀ Rọ́ṣíà ti wá láǹfààní láti máa lọ sórí ìkànnì jw.org, wọ́n sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìbùkún tẹ̀mí tí wọ́n ń rí níbẹ̀.
tí ilé ẹjọ́ àdúgbò náà kéde pa dà,ORÍLẸ̀-ÈDÈ TỌ́KÌ Ìjọba Kò Tíì Gbà Pé Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Kò Gbà Láyè Láti Ṣiṣẹ́ Ológun Ní Ẹ̀tọ́ Lábẹ́ Òfin
Ó lé ní ọdún mẹ́rin tí Arákùnrin Bariş Görmez, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Tọ́kì lò lẹ́wọ̀n torí pé ó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun. Nígbà tó wà ní àtìmọ́lé, àwọn ẹ̀ṣọ́ ológun fojú rẹ̀ rí màbo, wọ́n máa ń gbá a nípàá, wọ́n sì máa ń fi kóńdó lù ú. Ó tún jìyà gan-an nígbà tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Torí pé Arákùnrin Görmez ga gan-an, kò lè sùn sórí ibùsùn tí wọ́n fún un, ìdábùú ló máa ń wà lórí ibùsùn méjì, tó sì máa ń ká kò. Nígbà tó yá, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà gbà pé kí wọ́n fún un ní ibùsùn tó gùn dáadáa. Àwọn ará ló sì gbé ibùsùn náà wá fún un.
Lọ́dún 2008, Arákùnrin Görmez àtàwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta míì gbé ẹjọ́ lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, wọ́n sì fẹ̀sùn kan orílẹ̀-èdè Tọ́kì pé ó fi ẹ̀tọ́ du àwọn láti ṣe ẹ̀sìn táwọn fẹ́ káwọn sì kọ ohun tí kò bá ẹ̀rí ọkàn àwọn mu. Ní June 3, ọdún 2014, Ilé Ẹjọ́ dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin * láre, ó sì pàṣẹ fún ìjọba orílẹ̀-èdè Tọ́kì pé kó san owó ìtanràn àtàwọn owó míì táwọn ará ti ná pa dà fún wọn. Ìgbà kẹta nìyí tí Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù máa dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre tó sì dá orílẹ̀-èdè Tọ́kì lẹ́bi lórí ọ̀rọ̀ yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan kò sí lẹ́wọ̀n báyìí lórílẹ̀-èdè Tọ́kì, ọ̀rọ̀ yìí kò tíì lè yanjú pátápátá, àyàfi tí ìjọba orílẹ̀-èdè náà bá gbà pé àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin.
Ibi Tí Ọ̀rọ̀ Dé Lórí Àwọn Ẹjọ́ Tá A Mẹ́nu Bà Tẹ́lẹ̀
Orílẹ̀-Èdè Azerbaijan: Àwọn ọlọ́pàá ò yéé da ìpàdé wa rú lórílẹ̀-èdè Azerbaijan, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe lámèyítọ́ àwọn ìwé wa, tí wọ́n ń mú àwọn ará wa lóde ẹ̀rí, tí wọ́n sì ń fi àwọn ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin dù wọ́n. Síbẹ̀, ìjọba orílẹ̀-èdè náà ṣì kọ̀ jálẹ̀ láti tún orúkọ Ẹ̀sìn Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Ẹjọ́ mọ́kàndínlógún [19] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti wà ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù torí ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan ń ṣe yìí. Láìka gbogbo ìṣòro yìí sí, à ń rí ìbùkún Jèhófà lórí wa torí pé àwọn akéde túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a mú jáde lódindi ní èdè Azerbaijani tún wà lára ohun tó ń fún wa láyọ̀.
Orílẹ̀-Èdè Eritrea: Àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè yìí ń bá a nìṣó láti sin Jèhófà tọkàntọkàn bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń dojú kọ inúnibíni tó le koko. Ó ti tó ogún [20] ọdún báyìí tí àwọn arákùnrin mẹ́ta ti wà lẹ́wọ̀n, orúkọ wọn ni Paulos Eyassu, Isaac Mogos àti Negede Teklemariam. Wọ́n ti wà níbẹ̀ láti September 24, ọdún 1994. Nǹkan bí àádọ́jọ [150] Ẹlẹ́rìí àtàwọn olùfìfẹ́hàn ni ìjọba ilẹ̀ Eritrea mú nígbà Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe ní April 14, 2014. Àwọn tí wọ́n mú bẹ̀rẹ̀ látorí ọmọ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin títí dórí àgbàlagbà ẹni ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún [85]. Wọ́n tún mú nǹkan bí ọgbọ̀n [30] àwọn ará wa àtàwọn olùfìfẹ́hàn nígbà àkànṣe àsọyé ní April 27 ọdún 2014. Àmọ́ wọ́n ti tú ọ̀pọ̀ nínú wọn sílẹ̀.
Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan: Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn kò gbà ká kó mẹ́rìnlá lára àwọn ìtẹ̀jáde wa wọlé tàbí ká pín wọn lórílẹ̀-èdè Kazakhstan. Wọn ò gbà káwọn ará máa wàásù láwọn ibòmíì yàtọ̀ sí àwọn ilé ìjọsìn wa tí ìjọba fọwọ́ sí. Nǹkan bí àádọ́ta [50] àwọn ará wa sì ni wọ́n ti mú, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ ìwàásù tí kò bófin mu. Láti gbèjà òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tá a ní, a ti gbé ẹjọ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] lọ sí ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.
^ ìpínrọ̀ 1 Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bóyá kí òun ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú tàbí kí òun má ṣe é.
^ ìpínrọ̀ 1 Àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ jẹ́ ojúgbà ní abúlé kan náà ló sábà máa ń wà nínú àwọn ẹgbẹ́ orí-ò-jorí.
^ ìpínrọ̀ 2 Ẹjọ́ tó wà láàárín Buldu àti Àwọn Míì Pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Tọ́kì, No. 14017/08, June 3, ọdún 2014.