Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ 2

Rèbékà Mú Inú Jèhófà Dùn

Rèbékà Mú Inú Jèhófà Dùn

Obìnrin tó fẹ́ràn Jèhófà ni Rèbékà. Ísákì ni orúkọ ọkọ rẹ̀. Òun náà fẹ́ràn Jèhófà. Báwo ni Rèbékà àti Ísákì ṣe pàdé ara wọn? Báwo sì ni Rèbékà ṣe mú inú Jèhófà dùn? Ó yá, jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Rèbékà.

Ábúráhámù àti Sárà ló bí Ísákì. Ilẹ̀ Kénáánì ni gbogbo wọn ń gbé, àwọn èèyàn ibẹ̀ kì í jọ́sìn Jèhófà. Àmọ́, obìnrin tó ń sin Jèhófà ni Ábúráhámù fẹ́ kí Ísákì ọmọ òun. Torí náà, ó rán ọmọ iṣẹ́ rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Élíésérì, pé kó lọ wá ìyàwó wá fún Ísákì ní ìlú kan tó ń jẹ́ Háránì. Ìlú yìí ni àwọn kan lára mọ̀lẹ́bí Ábúráhámù ń gbé.

Rèbékà fi tinútinú ṣiṣẹ́ kára, ó pọn omi fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mu

Élíésérì àti àwọn ọmọọṣẹ́ Ábúráhámù míì ni wọ́n jọ lọ sí ìlú náà. Ìlú yẹn jìnnà gan-an torí náà, Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá ni wọ́n kó dání, wọ́n tún di oúnjẹ àti ẹ̀bùn sórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. Báwo wá ni Élíésérì ṣe fẹ́ mọ obìnrin tó máa mú wálé kí Ísákì lè fi ṣe aya? Nígbà tí Élíésérì àti àwọn ọmọọṣẹ́ yòókù dé Háránì, wọ́n dúró sí ẹ̀gbẹ́ kànga kan, torí Élíésérì mọ̀ pé àwọn èèyàn ò ní pẹ́ wá pọn omi níbẹ̀. Ló bá gbàdúrà sí Jèhófà, ó ní: ‘Ọ̀dọ́bìnrin tí mo bá sọ fún pé kó fún mi ní omi, tí ó sì fún èmi àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi lómi, a jẹ́ pé òun ni obìnrin tí o yàn.’

Lẹ́yìn náà, obìnrin kan tó ń jẹ́ Rèbékà wá síbi kànga yẹn, ó wá pọn omi. Bíbélì sọ pé ọ̀dọ́bìnrin náà rẹwà gan-an. Élíésérì sọ fún un pé kí ó fún òun ni omi mu, Rèbékà sọ pé: ‘Kò sí ìṣòro. Mo máa fún yín ní omi, màá sì tún fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín lómi.’ Ṣé o mọ̀ pé tí òùngbẹ bá gbẹ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n máa ń mu omi tó pọ̀ gan-an. Torí náà, léraléra ni Rèbékà sáré lọ fa omi ní kànga. Ṣé o rí i nínú àwòrán bó ṣe ń ṣiṣẹ́ kára?— Ó ya Élíésérì lẹ́nu gan-an bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà tó gbà.

Élíésérì fún Rèbékà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn. Rèbékà wá sọ pé kí Élíésérì àti àwọn ọmọọṣẹ́ yòókù máa bọ̀ ní ilé òun. Nígbà tí Élíésérì dé ibẹ̀, ó ṣàlàyé iṣẹ́ tí Ábúráhámù rán òun àti bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà òun. Inú àwọn ìdílé Rèbékà dùn, bí wọ́n ṣe gbà pé kó fẹ́ Ísákì nìyẹn.

Rèbékà bá Élíésérì lọ sí Kénáánì, ó sì fẹ́ Ísákì

Àmọ́, ṣé o rò pé ó wu Rèbékà pé kó fẹ́ Ísákì?— Rèbékà mọ̀ pé Jèhófà ló rán Élíésérì wá. Nígbà tí àwọn ìdílé Rèbékà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó wù ú láti tẹ̀ lé Élíésérì lọ sí Kénáánì kó lè lọ fẹ́ Ísákì, ó sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ lọ.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó bá Élíésérì lọ. Nígbà tí wọ́n dé Kénáánì, ó fẹ́ Ísákì.

Jèhófà bù kún Rèbékà torí pé ó ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n bí Jésù sínú ìdílé Rèbékà! Tó o bá fara wé Rèbékà, tó o sì ṣe ohun tó mú inú Jèhófà dùn, Jèhófà máa bù kún ìwọ náà.

KÀ Á NÍNÚ BÍBÉLÌ RẸ