ORÍ KỌKÀNLÉLÓGÚN
Ó Borí Ìbẹ̀rù àti Iyè Méjì
1-3. Àwọn nǹkan wo ló ti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ níṣojú Pétérù kí ilẹ̀ tó ṣú lọ́jọ́ yẹn? Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Pétérù lóru mọ́jú?
PÉTÉRÙ tó ti fi ọ̀pọ̀ wákàtí tukọ̀ ń tiraka láti wa àjẹ̀ rẹ̀. Ó wá gbójú sókè láti wo ọ̀ọ́kán, ó sì rí ohun tó dà bí ìmọ́lẹ̀ fírífírí lápá ìlà-oòrùn, tó fi hàn pé ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀. Bí ẹ̀yìn àti èjìká ṣe ń ro ó gan-an ni atẹ́gùn tó mú kí Òkun Gálílì máa ru gùdù tún ń fẹ́ irun orí rẹ̀. Ìjì tó ń rọ́ lu ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wà léraléra ń fọ́n omi tútù sí i lára, ara rẹ̀ sì rin gbingbin. Síbẹ̀ Pétérù ń tukọ̀ lọ.
2 Nígbà tí Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù kúrò ní etíkun, wọ́n fi Jésù sílẹ̀ lóun nìkan níbẹ̀. Lọ́jọ́ yẹn, ìṣojú wọn ni Jésù fi ìṣù búrẹ́dì àti ẹja díẹ̀ bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tí ebi ń pa. Àwọn èèyàn yẹn wá fẹ́ fi Jésù jọba. Àmọ́ Jésù kò fẹ́ bá wọn lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú rárá, ó sì fẹ́ rí i dájú pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun pàápàá kò lọ́wọ́ sírú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ló bá yẹra fún àwọn èèyàn yẹn, ó sì ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n lọ sí èbúté tó wà ní òdì kejì. Ó wá dá lọ sórí òkè láti gbàdúrà.—Máàkù 6:35-45; ka Jòhánù 6:14-17.
3 Ṣe ni òṣùpá àrànmọ́jú mọ́lẹ̀ rokoṣo nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbéra ìrìn wọn lórí omi lálẹ́, àmọ́ òṣùpá ti ń pajú dé lọ báyìí, ilẹ̀ sì ti fẹ́ mọ́ bá wọn lórí ìrìn. Síbẹ̀ wọn kò tíì rìn ju kìlómítà mélòó kan lọ. Wàhálà tí wọ́n sì ń ṣe bí wọ́n ṣe ń tukọ̀ àti ariwo ìgbì òkun kò jẹ́ kí wọ́n lè máa bára wọn sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kí Pétérù ti ronú lọ jìnnà.
Láàárín ọdún méjì, Pétérù ti kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Jésù, síbẹ̀ ó ṣì ní ohun púpọ̀ gan-an láti kọ́
4. Àwọn nǹkan wo ni Pétérù sa gbogbo ipá rẹ̀ láti borí tó mú kó jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún wa?
4 Àìmọye nǹkan ni Pétérù á máa ronú lé lórí. Ó ti lé lọ́dún méjì tó ti ń bá Jésù ará Násárétì rìn, oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ ló sì ti ṣojú rẹ̀.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ló ti kọ́, síbẹ̀ ó ṣì ní ohun púpọ̀ gan-an láti kọ́. Bó ṣe sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé òun borí iyè méjì àti ìbẹ̀rù mú kó jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún wa. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.“Àwa Ti Rí Mèsáyà Náà”!
5, 6. Irú ìgbésí ayé wo ni Pétérù ń gbé tẹ́lẹ̀?
5 Pétérù ò jẹ́ gbàgbé ọjọ́ tó rí Jésù. Áńdérù arákùnrin rẹ̀ ló kọ́kọ́ wá fi ìròyìn ayọ̀ yìí tó o létí. Ó ní: “Àwa ti rí Mèsáyà náà.” Ọ̀rọ̀ tí Pétérù gbọ́ yìí mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó yí pa dà pátápátá.—Jòh. 1:41.
6 Ìlú Kápánáúmù ni Pétérù ń gbé. Ìlú yìí wà ní etíkun àríwá adágún omi tí wọ́n ń pè ní Okùn Gálílì. Òun àti Áńdérù jọ dòwò ẹja pípa pọ̀ pẹ̀lú Jákọ́bù àti Jòhánù tí wọ́n jẹ́ ọmọ Sébédè. Ọ̀dọ̀ Pétérù àti aya rẹ̀ ni ìyá ìyàwó rẹ̀ àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀ ń gbé. Kí Pétérù tó lè máa fi iṣẹ́ ẹja pípa gbọ́ bùkátà àgbo ilé rẹ̀ yìí, ó dájú pé ó ní láti jẹ́ akíkanjú ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára gan-an. A lè fojú inú wo àìmọye ìgbà tí òun àti àwọn tí wọ́n jọ ń pẹja á máa ṣiṣẹ́ kára fún àkókò gígùn lóru, tí wọ́n á ta àwọ̀n wọn sáàárín ọkọ̀ méjì, tí wọ́n á sì máa fa àwọ̀n náà sínú ọkọ̀ tòun ti ẹja tí wọ́n bá rí pa nínú adágún náà. A tún lè fojú inú wo bí wọ́n á ṣe máa ṣiṣẹ́ àṣelàágùn láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń ya àwọn ẹja náà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì ń tà wọ́n, lẹ́yìn èyí tí wọ́n á wá tún àwọ̀n wọn ṣe, tí wọ́n á sì fọ̀ ọ́.
7. Kí ni Pétérù gbọ́ nípa Jésù, kí sì nìdí tó fi jẹ́ ìròyìn ayọ̀?
7 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù Oníbatisí ni Áńdérù tẹ́lẹ̀. Ó dájú pé Pétérù máa ń fi ọkàn sí ohun tí arákùnrin rẹ̀ máa ń sọ nípa ìwàásù Jòhánù. Lọ́jọ́ kan, Jòhánù wá nawọ́ sí Jésù ará Násárétì níṣojú Áńdérù ó sì sọ pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run!” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Áńdérù di ọmọlẹ́yìn Jésù, ó sì fi ìtara sọ ìròyìn ayọ̀ yìí fún Pétérù pé, Mèsáyà ti dé! (Jòh. 1:35-40) Lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé lọ́gbà Édẹ́nì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí pé ẹni pàtàkì kan ń bọ̀ tó máa mú kí aráyé ní ìrètí tó dájú. (Jẹ́n. 3:15) Olùgbàlà náà sì ni Áńdérù rí yìí, ìyẹn Mèsáyà fúnra rẹ̀! Ni Pétérù náà bá gbéra kíá láti lọ bá Jésù.
8. Kí ni ìtumọ̀ orúkọ tí Jésù fún Pétérù, kí sì nìdí tí àwọn kan fi sọ pé orúkọ yẹn kò bá a mu?
8 Ṣáájú ìgbà náà, Símónì tàbí Síméónì ni orúkọ tí àwọn èèyàn mọ Pétérù sí. Àmọ́ nígbà tí Jésù rí i, ó sọ fún un pé: “‘Ìwọ ni Símónì ọmọkùnrin Jòhánù; a óò máa pè ọ́ ní Kéfà’ (èyí tí a túmọ̀ sí Pétérù).” (Jòh. 1:42) “Kéfà” túmọ̀ sí “òkúta,” tàbí “àpáta.” Ẹ̀rí fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí. Ó ti rí i pé Pétérù máa dà bí àpáta, ìyẹn ni pé ó máa dúró digbí, ó máa fẹsẹ̀ múlẹ̀, ó sì máa nípa rere lórí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Ǹjẹ́ Pétérù nírú èrò yìí nípa ara rẹ̀? Kò dájú. Kódà, àwọn kan tí wọ́n ń ka àwọn ìwé Ìhìn Rere lóde òní kò gbà pé Pétérù dà bí àpáta. Àwọn kan tiẹ̀ ní ó dà bíi pé ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ fi hàn pé kì í ṣe ẹni tó ṣeé gbára lé, pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò láyọ̀lé, ó sì máa ń ṣiyè méjì.
9. Kí ni Jèhófà àti Jésù máa ń wò lára àwa èèyàn, kí sì nìdí tó o fi rò pé ó yẹ ká fọkàn tán wọn?
9 Lóòótọ́, Pétérù ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tirẹ̀, Jésù náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ibi tí èèyàn dáa sí ni Jésù máa ń wo bíi ti Jèhófà, Baba rẹ̀. Jésù rí i pé Pétérù ní àwọn ìwà tó dáa, ó sì wá bó ṣe máa ràn án lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ tẹra mọ́ ìwà dáadáa rẹ̀. Ibi tí àwa náà dáa sí ni Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ máa ń wò lára wa lónìí. Ó lè ṣòro fún wa láti gbà pé wọ́n á rí nǹkan rere lára wa. Àmọ́, ṣe ni ká fọkàn tán wọn, ká sì fi hàn pé a ṣe tán láti gbẹ̀kọ́ àti láti jẹ́ kí Jèhófà sọ wá di irú ẹni tó fẹ́ bíi ti Pétérù.—Ka 1 Jòhánù 3:19, 20.
“Dẹ́kun Fífòyà”
10. Kí láwọn nǹkan tó jọ pé ó ṣojú Pétérù, síbẹ̀ ibo ló pàpà pa dà sí?
10 Ó jọ pé Pétérù tẹ̀ lé Jésù lọ sí àwọn ibì kan tó ti lọ wàásù lẹ́yìn ìgbà tí òun àti Jésù mọra. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn ìgbà tó sọ omi di ọtí wáìnì níbi àsè ìgbéyàwó tó wáyé ní ìlú Kánà. Ní pàtàkì, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àgbàyanu tó ń fúnni nírètí tí Jésù ń sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀síbẹ̀, ó pàpà fi Jésù sílẹ̀, ó pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ẹja pípa. Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, Pétérù àti Jésù tún pàdé, Jésù sì wá sọ fún un lọ́tẹ̀ yìí pé òun fẹ́ kó di ọmọ ẹ̀yìn òun.
11, 12. (a) Iṣẹ́ wo ni Pétérù ṣe lóru mọ́jú? (b) Àwọn èrò wo ló lè máa wá sọ́kàn Pétérù bó ṣe ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù?
11 Bó ṣe ṣẹlẹ̀ ni pé, Pétérù àti àwọn tí wọ́n jọ ń pẹja fi gbogbo òru dẹ odò léraléra, àmọ́ wọn kò rí ẹja pa. Ó dájú pé Pétérù á ti lo gbogbo ọgbọ́n àti ìrírí tó ní lẹ́nu iṣẹ́ ẹja pípa, kó sì ti gbìyànjú onírúurú ibi tó ṣeé ṣe kí àwọn ẹja ti máa jẹun nínú adágún náà. Ó tiẹ̀ lè máa wù ú, bó ṣe máa ń wu ọ̀pọ̀ àwọn apẹja, pé ì bá dáa ká ní òun lè rí ìsàlẹ̀ òkun ni láti mọ ibi tí àwọn ẹja wọ́ jọ pọ̀ sí nínú agbami tó rú yìí, tàbí kí òun tiẹ̀ lágbára láti pàṣẹ pé kí àwọn ẹja rọ́ wá sínú àwọ̀n òun. Ṣùgbọ́n ṣe ni irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ á kàn jẹ́ kó túbọ̀ máa ká a lára bí kò ṣe rí ẹja pa. Ọ̀ràn ńlá ló jẹ́ fún Pétérù bí kò ṣe rí ẹja pa yìí, torí ìyẹn ló fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Nígbà tó yá ṣá, ó pa dà sí èbúté lọ́wọ́ òfo. Síbẹ̀ wọ́n ṣì ní láti fọ àwọ̀n tí wọ́n lò. Ẹnu ìyẹn ló wà nígbà tí Jésù dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní etíkun.
Kì í sú Pétérù láti máa gbọ́ àlàyé Jésù nípa Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ lájorí ìwàásù rẹ̀
12 Nígbà yẹn, èrò rẹpẹtẹ yí Jésù ká, wọ́n fẹ́ máa gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀. Torí pé èrò náà pọ̀, Jésù wọ inú ọkọ̀ Pétérù, ó ní kó wa Lúùkù 5:1-3.
ọkọ̀ náà síwájú díẹ̀ sínú omi. Àwọn èèyàn wá ń gbọ́ ohùn Jésù ketekete bó ṣe ń kọ́ wọn látorí omi. Pétérù pàápàá tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ bíi ti àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ní etíkun náà. Kì í sú u láti máa gbọ́ àlàyé Jésù nípa Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ lájorí ìwàásù rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Pétérù ronú pé, àǹfààní ńlá ló máa jẹ́ fún òun láti bá Kristi tan ìhìn rere tó ń fún àwọn èèyàn nírètí yìí káàkiri! Àmọ́, ǹjẹ́ á ṣeé ṣe fún òun láti ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí? Àbí báwo lòun á ṣe máa gbọ́ bùkátà ìdílé òun? Bóyá á tiẹ̀ wá máa rántí gbogbo òru tó fi ṣe wàhálà láìrí ẹja pa bó ṣe ń ro ọ̀rọ̀ yìí.—13, 14. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù ṣe fún Pétérù, kí ni Pétérù sì ṣe?
13 Nígbà tí Jésù bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Pétérù pé: “Wa ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi tí ó jindò, kí ẹ sì rọ àwọn àwọ̀n yín sísàlẹ̀ fún àkópọ̀ ẹja.” Àmọ́ Pétérù ṣiyè méjì nípa èyí. Ó ní: “Olùkọ́ni, ní gbogbo òru ni àwa ṣe làálàá, a kò sì mú nǹkan kan, ṣùgbọ́n nítorí àṣẹ àsọjáde rẹ, ṣe ni èmi yóò rọ àwọn àwọ̀n náà sísàlẹ̀.” Pétérù ṣẹ̀ṣẹ̀ fọ àwọ̀n rẹ̀ tán ni. Ó sì dájú pé kò tún fẹ́ dà á sódò mọ́, pàápàá nígbà tí kì í ṣe àkókò tí àwọn ẹja máa ń jẹ̀ kiri! Síbẹ̀, ó ṣe bí Jésù ṣe sọ, bóyá ó sì tún pe àwọn tó wà nínú ọkọ̀ kejì tí wọ́n jọ ń pẹja pé kí wọ́n ká lọ.—Lúùkù 5:4, 5.
14 Ohun tí Pétérù kò retí ṣẹlẹ̀. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fa àwọ̀n rẹ̀, ńṣe ló wúwo gan-an. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un! Bó ṣe wá túbọ̀ ń fi tagbára-tagbára fà á, kò pẹ́ tó fi rí i pé ẹja rẹpẹtẹ ń ta pàrà nínú àwọ̀n náà! Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í juwọ́ sí àwọn tó wà nínú ọkọ̀ kejì pé kí wọ́n wá ran òun lọ́wọ́. Bí wọ́n ṣe ń kó àwọ̀n ẹja náà sínú ọkọ̀, wọ́n rí i pé ọkọ̀ kan kò ní lè gbà á. Ni wọ́n bá ń kó o sínú ọkọ̀ méjèèjì. Síbẹ̀ ẹja náà pọ̀ débi pé ọkọ̀ méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Èyí ya Pétérù lẹ́nu púpọ̀ jù. Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tó máa rí i pé Kristi ṣe iṣẹ́ ìyanu o, àmọ́ òun gan-an ni Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu fún lọ́tẹ̀ yìí. Ó yà á lẹ́nu gan-an pé Jésù tiẹ̀ tún lágbára láti darí àwọn ẹja sínú àwọ̀n! Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í bà á. Ló bá kúnlẹ̀, ó ní: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Olúwa.” Ó ronú pé òun kò yẹ lẹ́ni tó ń sún mọ́ Ẹni tó ń lo agbára Ọlọ́run lọ́nà tó pọ̀ tó báyìí.—Ka Lúùkù 5:6-9.
15. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ kí Pétérù mọ̀ pé kò yẹ kó ṣe iyè méjì tàbí kó máa bẹ̀rù?
15 Jésù rọra sọ fún un pé: “Dẹ́kun fífòyà. Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.” (Lúùkù 5:10, 11) Ìgbà ìbẹ̀rù tàbí ìgbà iyè méjì kọ́ nìyí. Kò sídìí tó fi yẹ kí Pétérù máa ṣiyè méjì mọ́ nípa bí á ṣe máa rí ẹja pa, kò sì yẹ kó máa bẹ̀rù nítorí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ̀ tàbí pé òun kò kúnjú ìwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ìwàásù. Iṣẹ́ bàǹtàbanta ni Jésù ní láti ṣe, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tó máa nípa lórí ọjọ́ ọ̀la aráyé. Ọlọ́run tó máa ń “dárí jì lọ́nà títóbi” ni Jésù ń sìn. (Aísá. 55:7) Bákan náà, Jèhófà máa pèsè àwọn ohun tí Pétérù yóò fi gbọ́ bùkátà rẹ̀ nípa tara àti nípa tẹ̀mí fún un.—Mát. 6:33.
16. Kí ni Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù ṣe nígbà tí Jésù pè wọ́n, kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé ìpinnu tó dáa jù nìyẹn?
16 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Pétérù tẹ̀ lé Jésù, ohun tí Jákọ́bù àti Jòhánù náà sì ṣe nìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Wọ́n dá àwọn ọkọ̀ náà padà wá sí ilẹ̀, wọ́n sì pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.” (Lúùkù 5:11) Pétérù tipa báyìí fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nínú Jésù àti Ọlọ́run tó rán an. Ìpinnu tó dáa jù ni Pétérù ṣe yìí. Lónìí, ṣe ni àwọn Kristẹni tí wọ́n borí iyè méjì àti ìbẹ̀rù, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run ń fi hàn pé àwọn náà nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Téèyàn bá sì ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ nínú Jèhófà, kì í já sófo.—Sm. 22:4, 5.
“Èé Ṣe Tí Ìwọ Fi Bẹ̀rẹ̀ Sí Ṣe Iyèméjì?”
17. Àwọn nǹkan wo ni Pétérù lè máa rántí lẹ́yìn ọdún méjì tó ti ń bá Jésù rìn?
17 Ẹ̀yìn nǹkan bí ọdún méjì tí Pétérù ti ń bá Jésù rìn, ló fi gbogbo òru tukọ̀ nínú Òkun Gálílì tó ń ru gùdù bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Ká sòótọ́, a kò lè mọ àwọn nǹkan tí Pétérù ń rò lọ́kàn nígbà yẹn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè wà lọ́kàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù ti wo ìyá ìyàwó Pétérù sàn. Ó ti wàásù lórí òkè. Ó ti fi hàn léraléra nípasẹ̀ àwọn ohun tó ń kọ́ni àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe pé òun ni Mèsáyà, Ẹni Tí Jèhófà Yàn. Bí Pétérù ṣe máa ń dédé bẹ̀rù, táá sì máa ṣiyè méjì, ti wá ń dín kù bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Àní Jésù tiẹ̀ ti yan Pétérù sí ara àwọn àpọ́sítélì méjìlá! Síbẹ̀, Pétérù ṣì máa rí i pé òun kò tíì borí ìbẹ̀rù àti iyè méjì òun tán pátápátá.
18, 19. (a) Sọ ohun tí Pétérù rí lórí Òkun Gálílì. (b) Kí ni Jésù fi dá Pétérù lóhùn?
18 Ní ìṣọ́ kẹrin òru ọjọ́ yẹn, ìyẹn láàárín aago mẹ́ta ìdájí sí àfẹ̀mọ́jú, Pétérù ṣàdédé dáwọ́ ọkọ̀ tó ń wà dúró, ó sì jókòó dáadáa, ó wá gbójú sókè. Ó rí i pé nǹkan kan ń gba orí ìgbì òkun bọ̀! Àbí omi tó ń ta sókè látinú ìgbì òkun ni ìmọ́lẹ̀ òṣùpá ń tàn sí tó fi rí bẹ́ẹ̀ lójú òun ni? Kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, torí ṣe ni nǹkan ọ̀hún dúró ṣánṣán! Èèyàn ni o! Ọkùnrin sì ni, ó ń rìn lórí òkun! Bí ẹni náà ṣe ń sún mọ́ wọn, ó dà bíi pé ó fẹ́ gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí gan-an, torí wọ́n rò pé ìran abàmì kan ni àwọn ń rí. Ni ọkùnrin náà bá sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ mọ́kànle, èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.” Àṣé Jésù ni!—Mát. 14:25-28.
19 Pétérù wá fèsì pé: “Olúwa, bí ìwọ bá ni, pàṣẹ fún mi láti wá bá ọ lórí omi.” Ohun tó kọ́kọ́ ṣe yìí fi hàn pé ó nígboyà. Orí Pétérù yá gágá sí iṣẹ́ ìyanu tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí, ó wá fẹ́ wò ó bóyá òun náà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Òun náà fẹ́ rìn lórí omi, kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lè túbọ̀ fìdí múlẹ̀. Ni Jésù bá sọ pé kó máa bọ̀. Pétérù wá gun etí ọkọ̀, ó sì sọ̀ kalẹ̀ sórí òkun tó ń ru gùdù náà. Fojú inú wo bó ṣe máa rí lára Pétérù nìgbà tó rí i pé òun lé téńté sórí omi láì rì. Ó dájú pé ìyàlẹ́nu gbáà ló máa jẹ́ fún un bó ṣe ń rìn lórí omi lọ sọ́dọ̀ Jésù. Àmọ́ ṣá, èrò míì tún dédé gbà á lọ́kàn.—Ka Mátíù 14:29.
20. (a) Kí ló fà á tí Pétérù fi ní ìpínyà ọkàn, kí ló sì wá ṣẹlẹ̀? (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Jésù tẹ̀ mọ́ Pétérù lọ́kàn?
20 Jésù ló yẹ kí Pétérù gbájú mọ́, láì jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ pínyà. Torí òun ló ń lo agbára Jèhófà láti jẹ́ kí Pétérù rìn lórí ìgbì òkun tó ń ru gùdù yẹn. Ìgbàgbọ́ tí Pétérù ní nínú Jésù sì ni Jésù fi ní kó Mát. 14:30, 31.
máa bọ̀. Àmọ́ Pétérù wá jẹ́ kí nǹkan míì gba òun lọ́kàn. Bíbélì sọ pé: “Ní wíwo ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà, ó fòyà.” Bí Pétérù ṣe ń wo ìgbì òkun ńlá tó ń rọ́ lu ọkọ̀ wọn, tó sì ń fọ́n omi dà sínú afẹ́fẹ́, ẹ̀rù bà á. Bóyá ó tiẹ̀ ti ń rò ó pé òun máa rì sínú òkun yẹn, tóun á sì mumi yó. Bí ẹ̀rù ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bà á, ìgbàgbọ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù. Ni ọkùnrin tí Jésù pè ní Àpáta torí ẹ̀mí tó ní láti dúró digbí bá bẹ̀rẹ̀ sí í rì bí òkúta, ìdí sì ni pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ mì. Pétérù mọ odò wẹ̀ dáadáa, àmọ́ kò fi tìyẹn ṣe báyìí. Ńṣe ló pariwo pé: “Olúwa, gbà mí là!” Ni Jésù bá dì í lọ́wọ́ mú, ó sì fà á sókè. Nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí omi níbẹ̀ Jésù tẹ ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí mọ́ Pétérù lọ́kàn, ó ní: “Ìwọ tí o ní ìgbàgbọ́ kíkéré, èé ṣe tí ìwọ fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iyèméjì?”—21. Kí nìdí tí iyè méjì fi burú, kí la sì lè ṣe tá ò fi ní gbà á láyè?
21 Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, pé Pétérù “bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iyèméjì,” bá a mu gan-an ni! Iyè méjì burú, ó lè ba ayé ẹni jẹ́. Tá a bá gbà á láyè, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́, kó sì tẹ ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì. Torí náà, a kò gbọ́dọ̀ gbà á láyè rárá! Kí la máa ṣe tá ò fi ní gbà á láyè? A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà. Tá a bá ń ronú ṣáá nípa ohun tó ń bà wá lẹ́rù, ohun tó ń mú wa rẹ̀wẹ̀sì tàbí ohun tó ń pín ọkàn wa níyà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, ṣe ni a ó túbọ̀ máa ṣiyè méjì. Ṣùgbọ́n tá a bá gbájú mọ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, tá à ń ronú lórí àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe, èyí tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ àti èyí tí wọ́n máa ṣe fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wọn, iyè méjì kò ní lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́.
22. Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Pétérù?
22 Bí Pétérù ṣe tẹ̀ lé Jésù lọ sínú ọkọ̀, ó rí i pé ìjì tó ń jà náà dáwọ́ dúró, Òkun Gálílì sì pa rọ́rọ́. Pétérù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù wá sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ jẹ́ ní ti tòótọ́.” (Mát. 14:33) Bí ilẹ̀ ṣe ń mọ́ bọ̀ lórí adágún omi náà, ó dájú pé inú Pétérù á máa dùn gan-an nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí. Ó ti sapá láti borí ìbẹ̀rù àti iyè méjì. Lóòótọ́, ó ṣì ní ọ̀pọ̀ ìyípadà láti ṣe kó tó lè di Kristẹni tó dà bí àpáta tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ó pinnu pé òun á máa sapá, òun á sì máa tẹ̀ síwájú. Ṣé ìwọ náà nírú ìpinnu yẹn? Tó o bá ní irú ìpinnu bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ó yẹ kéèyàn tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Pétérù lóòótọ́.