Sún Mọ́ Jèhófà
Ọlọ́run ń rọ̀ ẹ́ pé kó o sún mọ́ òun. Ìwé yìí á jẹ́ kó o mọ ohun tí Bíbélì sọ pé o lè ṣe kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.
Ọ̀rọ̀ ìṣáájú
O lè di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run títí ayé.
ORÍ 1
“Wò Ó! Ọlọ́run Wa Nìyí!”
Kí nìdí tí Mósè fi béèrè orúkọ Ọlọ́run nígbà tó jẹ́ pé ó ti mọ orúkọ náà tẹ́lẹ̀?
ORÍ 2
Ṣé Òótọ́ Ni Pé O Lè “Sún Mọ́ Ọlọ́run”?
Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó dá ọ̀run àti ayé ń rọ̀ ẹ́ pé kó o sún mọ́ òun, ó sì ṣèlérí pé òun máa bù kún ẹ.
ORÍ 3
“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”
Kí nìdí tí Bíbélì fi máa ń fi ohun tó jẹ́ mímọ́ wé ohun tó rẹwà?
ORÍ 4
‘Agbára Jèhófà Pọ̀’
Ṣó yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run torí pé ó jẹ́ alágbára? A lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, a sì tún lè sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́.
ORÍ 5
Agbára Ìṣẹ̀dá—“Aṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ayé”
Látorí oòrùn tó ń tú ibú agbára jáde dórí ẹyẹ akùnyùnmù kékeré, a lè kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa Jèhófà látara àwọn ohun tó dá.
ORÍ 6
Agbára Ìparun—“Jagunjagun Tó Lágbára Ni Jèhófà”
Tó bá jẹ́ pé “Ọlọ́run àlàáfíà” ni Jèhófà lóòótọ́, kí nìdí tó fi ń jagun?
ORÍ 7
Agbára Ààbò—“Ọlọ́run Ni Ibi Ààbò Wa”
Ọ̀nà méjì ni Ọlọ́run ń gbà dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ ọ̀nà kan ṣe pàtàkì ju ìkejì lọ.
ORÍ 8
Agbára Ìmúbọ̀sípò—Jèhófà “Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”
Jèhófà ti mú ìjọsìn mímọ́ bọ̀ sípò. Àwọn nǹkan wo ló máa mú bò sípò lọ́jọ́ iwájú?
ORÍ 9
“Kristi Ni Agbára Ọlọ́run”
Kí làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe àtàwọn ohun tó fi kọ́ni jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
ORÍ 10
“Ẹ Máa Fara Wé Ọlọ́run” Bẹ́ Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára
Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti rí i pé ìwọ náà lágbára láti ṣe àwọn nǹkan kan. Báwo lo ṣe lè lo agbára tó o ní yìí lọ́nà tó dáa?
ORÍ 11
“Ó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Ní Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀”
Kí nìdí tí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run fi mú kó wù wá láti sún mọ́ ọn?
ORÍ 12
“Ṣé Ọlọ́run Jẹ́ Aláìṣòdodo Ni?”
Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Jèhófà kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ, kí nìdí tí ìwà ìrẹ́jẹ fi pọ̀ láyé lónìí?
ORÍ 14
Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn”
Ẹ̀kọ́ tó rọrùn tó sì bọ́gbọ́n mu táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.
ORÍ 15
Jésù “Fìdí Ìdájọ́ Òdodo Múlẹ̀ ní Ayé”
Àwọn nǹkan wo ni Jésù ti ṣe láti fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀? Àwọn nǹkan wo ló ń ṣe ní báyìí? Báwo ló sì ṣe máa fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
ORÍ 16
Máa “Ṣe Ìdájọ́ Òdodo” Bó O Ṣe Ń Bá Ọlọ́run Rìn
Ọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ òdodo kan ojú tá a fi ń wo ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ó tún kan bá a ṣe ń hùwà sáwọn èèyàn.
APÁ 3
“Ọlọ́gbọ́n ni”
ORÍ 18
Ọgbọ́n Wà Nínú “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi lo àwọn èèyàn láti kọ èrò ẹ̀ sínú ìwé kan, kí nìdí tó fi jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn ohun kan sílẹ̀ tí kò sì jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn ohun mí ì?
ORÍ 20
“Ọlọ́gbọ́n Ni”—Síbẹ̀ Ó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
Jèhófà ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, kí wá nìdí tó tún fi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.
ORÍ 21
Jésù Fi “Ọgbọ́n Ọlọ́run” Hàn
Ọ̀rọ̀ Jésù máa ń wọni lọ́kàn débi pé nígbà kan tí wọ́n rán àwọn ọmọ ogun láti lọ mú Jésù, ńṣe ni wọ́n pa dà lọ́wọ́ òfo!
ORÍ 22
Ṣé Ò Ń Jẹ́ Kí “Ọgbọ́n Tó Wá Láti Òkè” Darí Rẹ?
Bíbélì sọ àwọn nǹkan mẹ́rin tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ ní ọgbọ́n Ọlọ́run.
APÁ 4
“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
ORÍ 24
Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”
Sátánì máa ń parọ́ pé a ò wúlò àti pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ wa, àmọ́ má ṣe gba irọ́ yìí gbọ́ rárá.
ORÍ 25
“Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”
Tá a ba ronú nípa bí ọ̀rọ̀ ọmọ kan ṣe rí lára ìyá ẹ̀, báwo ló ṣe jọra pẹ̀lú bọ́rọ̀ wa ṣe rí lára Ọlọ́run?
ORÍ 26
Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”
Nígbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni pípé tí kì í gbàgbé nǹkan, báwo ló ṣe wá jẹ́ pé tó bá ti dárí jini, kì í rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́?
ORÍ 28
“Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ adúróṣinṣin ṣe pàtàkì ju bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ tàbí ẹni tó ṣeé gbára lé?
ORÍ 29
Kí Ẹ Lè “Mọ Ìfẹ́ Kristi”
Tá a bá ronú nípa ọ̀nà mẹ́ta tí Jésù gbà fìfẹ́ hàn, àá rí i pé ó fara wé ìfẹ́ Jèhófà lọ́nà tó pé.
ORÍ 31
“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Á sì Sún Mọ́ Yín”
Ìbéèrè pàtàkì wo ló yẹ kó o bi ara rẹ? Kí sì ni ìdáhùn rẹ?