Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Halfpoint Images/Moment via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Àwọn Elétò Ìlera Tó Jẹ́ Ọ̀gá Àgbà Kìlọ̀ Pé Ìkànnì Àjọlò Ń Ṣàkóbá Fáwọn Ọ̀dọ́​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Àwọn Elétò Ìlera Tó Jẹ́ Ọ̀gá Àgbà Kìlọ̀ Pé Ìkànnì Àjọlò Ń Ṣàkóbá Fáwọn Ọ̀dọ́​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Ní May 23, 2023, ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá àgbà tó ń bá àwọn elétò ìlera ṣiṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé ìkànnì àjọlò ń ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́.

  •   “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìkànnì àjọlò lè ṣe àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ láǹfààní, ẹ̀rí fi hàn pé ó tún lè wu wọ́n léwu, kó sì mú kí wọ́n máa rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí wọ́n máa ronú lọ́nà tí kò tọ́.”​—Social Media and Youth Mental Health: The U.S. Surgeon General’s Advisory, 2023.

 Àwọn elétò ìlera náà sọ ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀.

  •   Ó ṣeé ṣe káwọn ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìlá (12) sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) “tí wọ́n sì ń lo ohun tó lé ní wákàtí mẹ́ta lójúmọ́ lórí ìkànnì àjọlò ní ìrẹ̀wẹ̀sì, kí wọ́n sì máa kọ́kàn sókè gan-an.”

  •   Fáwọn ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14) “tó sábà máa ń lo ìkànnì àjọlò, ó ṣeé ṣe kó ṣòro fún wọn láti máa rí oorun sùn, kí wọ́n sì máa ro ara wọn pin. Wọ́n tún lè máa halẹ̀ mọ́ wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kí wọ́n sì máa rẹ̀wẹ̀sì. Àwọn ọ̀dọ́bìnrin máa ń níṣòro yìí ju àwọn ọ̀dọ́kùnrin lọ.”

 Kí làwọn òbí lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ ewu yìí? Bíbélì sọ àwọn ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ohun táwọn òbí lè ṣe

 Ṣe ìpinnu tó yẹ. Ó yẹ káwọn òbí mọ ewu tó wà nínú lílo ìkànnì àjọlò, kí wọ́n sì pinnu bóyá kí ọmọ wọn lò ó tàbí kó má lò ó.

 Tó o bá gbà kí ọmọ rẹ máa lo ìkànnì àjọlò, o gbọ́dọ̀ wà lójúfò sáwọn nǹkan tó lè ṣàkóbá fún un, kó o sì máa kíyè sí àwọn ohun tó ń ṣe. Àmọ́ báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

 Má ṣe jẹ́ kí ọmọ rẹ máa wo àwọn nǹkan tó lè ṣàkóbá fún un. Kọ́ ọmọ rẹ kó lè mọ àwọn ìkànnì àtàwọn ìlujá tó lè ṣàkóbá fún un.

  •   Ìlànà Bíbélì: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ìṣekúṣe àti ìwà àìmọ́ èyíkéyìí tàbí ojúkòkòrò láàárín yín, . . . bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà àìnítìjú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ẹ̀fẹ̀ rírùn.”​—Éfésù 5:3, 4.

  •   Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó o lè ṣe, ka àpilẹ̀kọ náà “Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò.”

 Pinnu bá a ṣe máa lò ó. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ ìgbà tó lè lo ìkànnì àjọlò àti bó ṣe máa pẹ́ tó lórí ẹ̀.

  •   Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.”​—Éfésù 5:15, 16.

  •   Lo eré ojú pátákò náà Máa Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò kí ọmọ ẹ lè rí ìdí tó fi yẹ kóun fọgbọ́n lo ìkànnì àjọlò.