“Owó Kéékèèké Méjì”
Wà á jáde:
1. Nígbà kan
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mò ń ṣe.
Mo máa ń lọ
Sóde ẹ̀rí, mò ń ṣiṣẹ́ ìrànwọ́.
Lásìkò yìí,
Mi ò lè ṣe tó bẹ́ẹ̀ mọ́.
Ṣé Jèhófà mọyì
Ohun tí agbára mi gbé?
(ÈGBÈ)
Ohun tí mò ń ṣe,
Jọ ẹyọ owó,
Tí opó kan fi ṣe ọrẹ.
Eyọ méjì péré
Jèhófà mọyì mi
Torí ó mọyì owó
Tó fi tọrẹ.
2. Gbogbo ohun
Tó ní ló fi ṣe ọrẹ
Àwọn ọlọ́rọ̀
Ń ṣe ọrẹ tó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ gan-an.
Jésù wa sọ pé,
ẹ̀bùn rẹ̀ ṣeyebíye.
Ó kéré lójú wa,
Sùgbọ́n Baba mọyì ẹ̀bùn yẹn.
(ÈGBÈ)
Ohun tí mò ń ṣe,
Jọ ẹyọ owó,
Tí opó kan fi ṣe ọrẹ.
Eyọ méjì péré
Jèhófà mọyì mi
Torí ó mọyì owó
Tó fi tọrẹ.
(ÀSOPỌ̀)
Jèhófà tóbi ju ọkàn wa lọ
Ó mọ̀ wá ju bí a ṣe lérò lọ.
A mọ̀ pó nífẹ̀ẹ́ wa.
(ÈGBÈ)
Ohun tí à ń ṣe,
Jọ ẹyọ owó,
Tí opó kan fi ṣe ọrẹ
Eyọ méjì péré
Jèhófà mọyì wa
Torí ó mọyì owó tó
Fi ṣe ọrẹ.
Ó tóbi ju ọkàn wa lọ.