ORIN 100
Máa Fi Ìfẹ́ Gbà Wọ́n Lálejò
(Ìṣe 17:7)
-
1. Jèhófà máa ń fìfẹ́ tọ́jú gbogbo wa.
Ó máa ń fìfẹ́ pèsè fún gbogbo èèyàn.
Ó ń mú kí oòrùn ràn,
Ó ńmú kí òjò rọ̀;
Ó ń fún wa ní oúnjẹ tó dára.
Ó yẹ káwa náà fara wé Ọlọ́run.
Ká máa ṣàánú àwọn tó jẹ́ aláìní.
Ká máa ràn wọ́n lọ́wọ́,
Kí ara lè tù wọ́n.
Ká rí i pé a ṣeé látọkàn wá.
-
2. Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Lìdíà
Tó gba àwọn ẹni mímọ́ lálejò.
Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ wa
Àtìfẹ́ tá a ń fi hàn
Yóò fògo fún Bàbá wa ọ̀run.
Tí àwọn àlejò bá wá sọ́dọ̀ wá,
Ẹ jẹ́ ká fìfẹ́ gbà wọ́n sínú ‘lé wa.
Bàbá wa onífẹ̀ẹ́
Rí gbogbo ‘hun tá à ń ṣe.
Ó dájú pé yóò pín wa lérè.