ORIN 112
Jèhófà, Ọlọ́run Àlàáfíà
-
1. Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́,
Jọ̀ọ́, fún wa ní àlàáfíà
Tó o ṣèlérí pó o máa fún wa
Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.
Ìgbàgbọ́ tí a ní
Nínú Jésù Ọmọ rẹ
Ló mú ká sún mọ́ ọ, ká sì
Wà lálàáfíà pẹ̀lú rẹ.
-
2. Ẹ̀mí rẹ ń ṣèrànwọ́
Láyé tó ṣókùnkùn yìí.
Ọ̀rọ̀ rẹ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀,
Ó ń tọ́ wa, ó ń pa wá mọ́.
Láìpẹ́, Ìjọba rẹ
Yóò fòpin sí ‘ṣòro wa.
Ṣùgbọ́n báyìí, ràn wá lọ́wọ́
Ká lè máa wà lálàáfíà.
-
3. Àwa ìránṣẹ́ rẹ
Ní ọ̀run àti láyé,
O fìfẹ́ kó gbogbo wa jọ;
À ń kọ́wọ́ ti ’Jọba rẹ.
Láìpẹ́, yóò dé sáyé,
Yóò sì fòpin sí ogun.
Àwọn olódodo máa yọ̀,
Wọn yóò máa gbé lálàáfíà.
(Tún wo Sm. 4:8; Fílí. 4:6, 7; 1 Tẹs. 5:23.)