ORIN 14
Ẹ Yin Ọba Tuntun Tó Jẹ Lórí Ayé
-
1. Jésù Kristi àti àwọn
ẹni àmì òróró
Ń kó ọ̀pọ̀ èèyàn jọ láti
inú gbogbo ‘rílẹ̀-èdè.
Ìjọba náà ti wà lọ́run,
yóò mú ìfẹ́ Jáà ṣẹ láyé.
Ìrètí yìí mà ṣeyebíye!
Ó ń tù wá nínú, à ń láyọ̀.
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Ọlọ́run wa; Ẹ yin Jésù Kristi,
Olúwa, Ọba àwọn ọba.
Gbogbo wa kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ̀,
A ó sì máa yìn ín níṣọ̀kan.
-
2. À ń fìyìn f’Ónídàájọ́ wa
tí yóò mú ìgbàlà wá.
Ọmọ Aládé Àlàáfíà
ti ń ṣàkóso ní ọ̀run.
Yóò jí àwọn òkú dìde;
Yóò mú ‘bẹ̀rù kúrò láyé.
À ń retí àkókò yìí, kó dé.
Gbogbo ayé ló máa láyọ̀!
(ÈGBÈ)
Ẹ yin Ọlọ́run wa; Ẹ yin Jésù Kristi,
Olúwa, Ọba àwọn ọba.
Gbogbo wa kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ̀,
A ó sì máa yìn ín níṣọ̀kan.
(Tún wo Sm. 2:6; 45:1; Àìsá. 9:6; Jòh. 6:40.)