Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Róòmù 12:12—“Ẹ Ma Yọ̀ ni Ireti; Ẹ Ma Mu Suru Ninu Ipọnju; Ẹ Ma Duro Gangan Ninu Adura”

Róòmù 12:12—“Ẹ Ma Yọ̀ ni Ireti; Ẹ Ma Mu Suru Ninu Ipọnju; Ẹ Ma Duro Gangan Ninu Adura”

 “Ẹ jẹ́ kí ìrètí tí ẹ ní máa fún yín láyọ̀. Ẹ máa fara da ìpọ́njú. Ẹ máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà.”—Róòmù 12:12, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Ẹ ma yọ̀ ni ireti; ẹ ma mu suru ninu ipọnju; ẹ ma duro gangan ninu adura.”—Róòmù 12:12, Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Róòmù 12:12

 Nínú ẹsẹ yìí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe àwọn ohun mẹ́ta tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n bá ń kojú inúnibíni àtàwọn ìṣòro míì.

 “Ẹ jẹ́ kí ìrètí tí ẹ ní máa fún yín láyọ̀.” Àwọn Kristẹni ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú, díẹ̀ nínú wọn máa lọ sí ọ̀run nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú wọn máa wà nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29; Jòhánù 3:16; Ìfihàn 14:1-4; 21:3, 4) Ìrètí yìí ló jẹ́ ka mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run a ló máa yanjú gbogbo ìṣòro tó ń fa ìyà fún àwa èèyàn. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run máa ń láyọ̀ kódà tí wọ́n bá ń fara da ìṣòro tó le gan-an, torí pe ìrètí tí wọ́n ní dá wọn lójú àti pé, inú Ọlọ́run ń dùn sí wọn bí wọ́n ṣe ń fara dà á.—Mátíù 5:11, 12; Róòmù 5:3-5.

 “Ẹ máa fara da ìpọ́njú.” Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà “ìfaradà” sábà máa ń túmọ̀ sí “kéèyàn dúró dípò kó sá, kó forí ti nǹkan, kó sì dúró gbọn-in.” Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi “kì í ṣe apá kan ayé,” b torí náà wọ́n mọ̀ pé wọ́n máa ṣe inúnibíni sí àwọn, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi nílò ìfaradà. (Jòhánù 15:18-20; 2 Tímótì 3:12) Tí Kristẹni kan bá ń fara da àdánwò tó sì ń fi gbogbo ọkàn ẹ̀ sin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ ẹ̀ á túbọ̀ lágbára torí ó mọ̀ pé Ọlọ́run máa san òun lẹ́san. (Mátíù 24:13) Lẹ́sẹ̀ kan náà, ìgbàgbọ́ ẹ̀ tó lágbára yìí ló máa jẹ́ kó lè fara da àwọn ìṣòro ẹ̀ pẹ̀lú sùúrù àti ayọ̀.—Kólósè 1:11.

 “Ẹ máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà.” Ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì káwa Kristẹni máa gbàdúrà déédéé. (Lúùkù 11:9; 18:1) Àwọn Kristẹni máa ń gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń jẹ́ kó tọ́ àwọn sọ́nà látìgbàdégbà nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. (Kólósè 4:2; 1 Tẹsalóníkà 5:17) Ó dá wọn lójú pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà wọn torí wọ́n ń ṣe ohun tínú Ọlọ́run dùn sí, wọ́n sì ń ṣègbọràn sáwọn àṣẹ rẹ̀. (1 Jòhánù 3:22; 5:14) Wọ́n tún mọ̀ pé táwọn bá tẹra mọ́ àdúrà gbígbà, Ọlọ́run máa fún wọn lókun tó máa mú kí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin láìka àdánwò tí wọ́n lè kojú sí.—Fílípì 4:13.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Róòmù 12:12

 Lọ́dún 56 Sànmánì Kristẹni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni tó ń gbé nílùú Róòmù. Ní orí 12 lẹ́tà náà, Pọ́ọ̀lù fún wọn láwọn ìmọ̀ràn lórí bí wọn ṣe lè máa hùwà tó yẹ Kristẹni, bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn àtàwọn míì títí kan bí wọn ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà tí wọ́n bá ń takò wọ́n. (Róòmù 12:9-21) Ìmọ̀ràn yìí bọ́ sákòókò gan-an, torí kò pẹ́ táwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù fi kojú àtakò tó gbóná janjan.

 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, iná ńlá ṣọṣẹ́ nílùú Róòmù lọ́dún 64 Sànmánì Kristẹni. Ìròyìn tàn kálẹ̀ pé Olú Ọba Nero ló fa iná náà. Tacitus tó jẹ́ òpìtàn ilẹ̀ Róòmù sọ pé, Nero di ẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ru àwọn Kristẹni kó lè dáàbò bo ara ẹ̀. Bó ṣe di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni nìyẹn. Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wọn lórí bí wọ́n ṣe lè fara da inúnibíni ló mú kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́, kí wọ́n má sì yẹsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń kojú àtakò yẹn. (1 Tẹsalóníkà 5:15; 1 Pétérù 3:9) Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ làwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lónìí lè rí kọ́ lára wọn.

 Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Róòmù.

a Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan ní ọ̀run tí Ọlọ́run máa lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ ní ayé. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

b Ọ̀rọ̀ náà “ayé” lè túmọ̀ sí àwùjọ àwọn èèyàn tí kò mọ Ọlọ́run.