Ṣé Bíbélì Fi Kọ́ni Pé Ayé Rí Pẹrẹsẹ?
Ohun tí Bíbélì sọ
Rárá o, Bíbélì ò sọ pé ayé rí pẹrẹsẹ. a Bíbélì kì í ṣe ìwé tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ohun tó wà nínú Bíbélì ò ta ko ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe. Ohun tí Bíbélì bá sọ máa ń “ṣeé gbára lé ní gbogbo ìgbà, ní báyìí àti títí láé.”—Sáàmù 111:8.
Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé” tó wà nínú Bíbélì túmọ̀ sí?
Àwọn ọ̀rọ̀ náà “ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé” àti “àwọn ìkángun ayé” tó wà nínú Bíbélì lóhun tí wọ́n túmọ̀ sí, kò ṣeé túmọ̀ ní tààràtà bẹ́ẹ̀, táá fi wá dà bíi pé ayé ní igun mẹ́rin àbí pé ó ní ìkángun. (Àìsáyà 11:12; Jóòbù 37:3) Kàkà bẹ́ẹ̀, àkànlò èdè làwọn ọ̀rọ̀ yẹn jẹ́, wọ́n ń tọ́ka sí gbogbo ayé lódindi. Ohun kan náà ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì ń mẹ́nu ba ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, àríwá àti gúúsù.—Lúùkù 13:29.
Ó jọ pé àkànlò èdè tó dá lórí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìyẹ́” ni ọ̀rọ̀ Hébérù náà “ìkángun” tàbí “igun.” Bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia ṣe sọ, “torí pé ìyẹ́ ni ẹyẹ máa ń fi bo ọmọ rẹ̀, [ọ̀rọ̀ Hébérù yìí] ni wọ́n fi ń ṣàpèjúwe ìkángun ohunkóhun tó bá nà jáde.” Ìwé yẹn tún fi kún un pé nínú Jóòbù 37:3 àti Àìsáyà 11:12, “ohun tí ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí ni àwọn etíkun, ààlà tàbí àwọn ibi tí ilẹ̀ kángun sí ní ayé.” b
Kí la lè sọ nípa ìdẹwò tí Èṣù ṣe fún Jésù?
Nígbà tí Èṣù fẹ́ dán Jésù wò, “Èṣù . . . mú un lọ sí òkè kan tó ga lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án.” (Mátíù 4:8) Ohun táwọn kan sọ ni pé ṣe ni ìtàn tó wà nínú Bíbélì yìí jẹ́ ká rí i pé èèyàn lè rí gbogbo ayé láti ibì kan ṣoṣo torí pé ayé rí pẹrẹsẹ. Àmọ́ ó jọ pé àpèjúwe lásán ni “òkè kan tó ga lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀” tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, kì í ṣe ibì kan pàtó. Wo ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà bẹ́ẹ̀.
Kò sí òkè náà láyé yìí téèyàn lè gùn táá fi rí gbogbo ìjọba ayé.
Kì í ṣe gbogbo ìjọba nìkan ni Èṣù fi han Jésù, ó tún fi “ògo wọn” hàn án. Èèyàn ò lè rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láti ọ̀nà jíjìn, torí náà, ó jọ pé ojú ìran ni Èṣù ti fi àwọn nǹkan yìí han Jésù. Ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń fi fọ́tò àwọn apá ibòmíì lágbàáyé han ẹnì kan lójú amóhùnmáwòrán ńlá.
Nígbà tí Lúùkù 4:5 ń sọ̀rọ̀ nípa ìtàn yìí kan náà, ó sọ pé Èṣù “fi gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí a ń gbé [han Jésù] lójú ẹsẹ̀,” kò sì ṣeé ṣe kéèyàn fi ojú lásán rí ìyẹn. Èyí fi hàn pé ọ̀nà míì ni Èṣù gbà fi ohun tó fẹ́ fi dẹ Jésù wò yìí hàn án, kì í ṣe pẹ̀lú ojú lásán.
a Bíbélì pe Ọlọ́run ní Ẹni “tó ń gbé orí òbìrìkìtì ayé.” (Àìsáyà 40:22) Àwọn ìwé ìwádìí kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí “òbìrìkìtì” tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí ohun tó rí rogodo bíi bọ́ọ̀lù, àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ló fara mọ́ èrò yìí. Síbẹ̀ náà, kò sí ẹ̀rí nínú Bíbélì tó fi hàn pé ayé rí pẹrẹsẹ.
b Ẹ̀dà Tí A Tún Ṣe, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 4.