Kí Nìdí Tí Mo Fi Gbọ́dọ̀ Gbàdúrà Lórúkọ Jésù?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ní orúkọ Jésù la gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà nítorí pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí Ọlọ́rùn fọwọ́ sì nìyẹn pé ká máa gbà bá òun sọ̀rọ̀. Jésù sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Jésù tún sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ bá béèrè fún ohunkóhun lọ́wọ́ Baba, yóò fi í fún yín ní orúkọ mi.”—Jòhánù 16:23.
Àwọn ìdí míì tó fi yẹ ká máa gbàdúrà lórúkọ Jésù
À ń bọ̀wọ̀ fún Jésù àti bàbá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run.—Fílípì 2:9-11.
À ń fi hàn pé a mọrírì kíkú tí Jésù kú fún wa ká bàa lè rí ìgbàlà látọ̀dọ Ọlọ́run.—Mátíù 20:28; Ìṣe 4:12.
A mọyì ipa tó ṣàrà-ọ̀tọ̀ tí Jésù ń kó gẹ́gẹ́ bí Alárinnà láàárín Ọlọ́run àti èèyàn.—Hébérù 7:25.
A bọ̀wọ̀ fún òjúṣe Jésù gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà tó lè jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.—Hébérù 4:14-16.