Báwo Ni Ọdún Halloween Ṣe Bẹ̀rẹ̀?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì ò mẹ́nu kan ọdún Halloween rárá, ìyẹn ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún ní October 31. Àmọ́, ohun tó mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ọdún Halloween láyé àtijọ́ àti nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe nígbà ọdún náà kò bá Bíbélì mu rárá.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa
Bí ọdún Halloween ṣe bẹ̀rẹ̀ àti àwọn àṣà rẹ̀
Samhain: Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣàlàyé ibi tí ọdún Halloween ti bẹ̀rẹ̀, ó sọ pé: “Àwọn ẹ̀yà Celt tó jẹ́ abọ̀rìṣà ló bẹ̀rẹ̀ àjọ̀dún yìí ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn. Àwọn ẹ̀yà Celt gbà gbọ́ pé lásìkò ayẹyẹ yìí, àwọn òkú máa ń rìn kiri láàárín àwọn alààyè àti pé ìgbà yẹn náà ni àwọn èèyàn lè ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn òkú.”—Wo “ Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ń Pè É Ní Halloween?”
Bí wọ́n ṣe ń múra nígbà ọdún Halloween, súìtì àti àṣà dídẹ́rù ba àwọn èèyàn: Ìwé kan sọ pé àwọn ẹ̀yà Celt máa ń múra bí òkú kí àwọn òkú tó ń rín káàkiri “lè rò pé ọ̀kan náà làwọn,” ìyẹn á mú kí wọ́n fi wọ́n sílẹ̀. Àwọn míì máa ń fi súìtì rúbọ sí àwọn ẹ̀mí àìrí yìí láti fi tù wọ́n lójú. a
Láwọn ọdún 500 sí 1500 Sànmánì Kristẹni ní Yúróòpù, àwọn àlùfáà Kátólíìkì mú àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà wọ inú ẹ̀sìn wọn. Wọ́n á sọ pé kí àwọn ọmọ ìjọ wọn lo ìbòjú, kí wọ́n sì máa tọrọ àwọn ẹ̀bùn kéékèèké kiri láti ilé kan sí òmíì.
Àwọn ẹ̀mí àìrí, àwọn àǹjọ̀nnú tó ń mu ẹ̀jẹ̀, àwọn ṣèèyàn ṣẹranko àtàwọn àjẹ́: Ọjọ́ pẹ́ táwọn nǹkan yìí ti ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù. Ìwé Halloween Trivia pè wọ́n ní “àwọn abàmì ẹ̀dá tí wọ́n máa ń ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn òkú.”
Èso elégédé tí wọ́n gbẹ́ àti àtùpà tí wọ́n máa ń tàn lásìkò ọdún Halloween: Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àtijọ́, àwọn èèyàn “máa ń lọ láti ilé kan sí òmíì, wọ́n á máa béèrè oúnjẹ lọ́wọ́ àwọn èèyàn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣàdúrà fún àwọn òkú,” wọ́n á sì gbé “èso kan dání tí wọ́n gbẹ́ ojú àti eyín sí lára, tí wọ́n sì tan iná àbẹ́là sínú rẹ̀ bí àtùpà. Àbẹ́là tí wọ́n tàn yìí dúró fún ẹ̀mí àwọn tó ń joró nínú pọ́gátórì.” (Látinú ìwé Halloween—From Pagan Ritual to Party Night) Àwọn òpìtàn kan sọ pé àwọn àtùpà yìí ni wọ́n fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jìnnà. Láwọn ọdún 1800 ní North America, wọ́n fi àtùpà tí wọ́n fi igbá ṣe rọ́pò èso tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ torí pé igbá pọ̀ dáadáa, ó sì rọrùn láti dá ihò sí i lára jú èyí tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ lọ.
Ṣé bí ọdún Halloween ṣe bẹ̀rẹ̀ tiẹ̀ ṣe pàtàkì?
Bẹ́ẹ̀ ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ gbà pé kò sóhun tó burú nínú ọdún Halloween, àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe nígbà ayẹyẹ náà kò bá Bíbélì mu. Ìdí ni pé ọdún Halloween dá lórí ẹ̀kọ́ èké nípa àwọn òkú, ẹ̀mí àìrí tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù.
Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tó tẹ̀ lé e yìí, kíyè sí ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe nígbà ọdún Halloween:
“Má ṣe jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrín yín tí ó jẹ́ . . . a bá iwin gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókùúsọ̀rọ̀.” —Diutarónómì 18:10-12, Bíbélì Mímọ́.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ sí ẹnikẹ́ni tó ń sapá láti bá òkú sọ̀rọ̀, tàbí tó kàn tiẹ̀ ń díbọ́n bíi pé òun fẹ́ bá àwọn tó ti kú sọ̀rọ̀.
“Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníwàásù 9:5.
Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn òkú ò lè bá wa sọ̀rọ̀, nítorí pé wọn ò mọ nǹkan kan.
“Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀yin kò lè mu nínú ago ti Olúwa àti ago ti èṣù lẹ́ẹ̀kan náà.”—1 Kọ́ríńtì 10:20, 21, Bíbélì Mímọ́.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ẹni tó bá fẹ́ rí ojúure Ọlọ́run kò gbọ́dọ̀ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù.
“Ẹ . . . dúró gbọn-in láti dojú kọ àwọn àrékérekè Èṣù; nítorí a ní ìjà kan . . . pẹ̀lú agbo ọmọ ogun àwọn ẹ̀mí burúkú.”—Éfésù 6:11, 12.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ó yẹ káwọn Kristẹni sá fún ohunkóhun tó tó bá ti kan àwọn ẹ̀mí èṣù dípò kí wọ́n máa ṣe ayẹyẹ tó ń gbé wọn lárugẹ.
a Ka ìwé náà Halloween: An American Holiday, an American History, ojú ìwé 4.