Kí Ni Ìpọ́njú Ńlá?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ìgbà ìpọ́njú ńlá ni nǹkan máa nira jù lọ fún gbogbo aráyé. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tàbí “àkókò òpin.” (2 Tímótì 3:1; Dáníẹ́lì 12:4) Ó máa jẹ́ “ìpọ́njú irúfẹ́ èyí ti kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá tí Ọlọ́run dá títí di àkókò yẹn, kì yóò sì tún ṣẹlẹ̀ mọ́.”—Máàkù 13:19; Dáníẹ́lì 12:1; Mátíù 24:21, 22.
Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá
Ìparun ìsìn èké. Orí eré ni ìsìn èké máa pa run. (Ìṣípayá 17:1, 5; 18:9, 10, 21) Àwọn olóṣèlú tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń ṣojú fún ni Ọlọ́run máa lò láti ṣe èyí.—Ìṣípayá 17:3, 15-18. a
Wọ́n máa gbéjà ko ìsìn tòótọ́. Àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè, tí Ìsíkíẹ́lì pè ní “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù” nínú ìran tó rí, máa fẹ́ pa àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ run. Àmọ́, Ọlọ́run ò ní jẹ́ káwọn tó ń sìn ín pa run.—Ìsíkíẹ́lì 38:1, 2, 9-12, 18-23.
Ìdájọ́ aráyé. Jésù máa dá gbogbo aráyé lẹ́jọ́, ó sì máa “ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.” (Mátíù 25:31-33) Bóyá ẹnì kan ti àwọn “arákùnrin” Jésù lẹ́yìn tàbí kò tì wọ́n lẹ́yìn ló máa pinnu ẹjọ́ tí Jésù máa dá fún ẹnì kọ̀ọ̀kan. Àwọn “arákùnrin” Jésù yìí ni àwọn tó máa bá a jọba lọ́run.—Mátíù 25:34-46.
Kíkó àwọn tó máa ṣàkóso nínú Ìjọba náà jọ. Àwọn olóòótọ́ èèyàn tó wà láyé tí Ọlọ́run ti yàn láti bá Kristi jọba máa kú, wọ́n á sì jíǹde sí ọ̀run.—Mátíù 24:31; 1 Kọ́ríńtì 15:50-53; 1 Tẹsalóníkà 4:15-17.
Amágẹ́dọ́nì. Èyí ni “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè”, Bíbélì tún pè é ní “ọjọ́ Jèhófà.” (Ìṣípayá 16:14, 16; Aísáyà 13:9; 2 Pétérù 3:12) Àwọn tí Kristi bá dájọ́ ikú fún máa pa run nígbà ogun yìí. (Sefanáyà 1:18; 2 Tẹsalóníkà 1:6-10) Ètò òṣèlú àgbáyé, tí Bíbélì fi wé ẹranko ẹhànnà olórí méje náà máa pa run.—Ìṣípayá 19:19-21.
Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá
Wọ́n máa sé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù mọ́. Áńgẹ́lì alágbára kan máa ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù “sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” tó ṣàpẹẹrẹ bí wọn ò ṣe ní lè ta pútú, àfi bí ẹni tó ti kú. (Ìṣípayá 20:1-3) Ṣe ni Sátánì máa dà bí ẹni tó wà lẹ́wọ̀n; apá máa ká a pátápátá, kò ní rí ẹnikẹ́ni mú.—Ìṣípayá 20:7.
Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún máa bẹ̀rẹ̀. Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún, á sì bù kún aráyé lọ́pọ̀lọpọ̀. (Ìṣípayá 5:9, 10; 20:4, 6) “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ò níye máa “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá,” ìyẹn ni pé wọ́n máa là á já, á sì ṣojú wọn nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso fún Ẹgbẹ̀rún [1,000] Ọdún.—Ìṣípayá 7:9, 14; Sáàmù 37:9-11.
a Ìwé Ìṣípayá fi ìsìn èké wé Bábílónì Ńlá, ìyẹn “aṣẹ́wó ńlá.” (Ìṣípayá 17:1, 5) Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó máa pa Bábílónì Ńlá run ṣàpẹẹrẹ ètò kan tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti so àwọn orílẹ̀-èdè ayé pọ̀, kó sì máa ṣojú wọn. Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ni àjọ tí wọ́n kọ́kọ́ gbé kalẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ yìí, àmọ́ ní báyìí, ó ti di Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.