Kí Ni Àjíǹde?
Ohun tí Bíbélì sọ
Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà a·naʹsta·sis ni wọ́n tú sí “àjíǹde,” ohun tó sì túmọ̀ sí ni “gbé dìde” tàbí kí nǹkan “dìde dúró lẹ́ẹ̀kan sí i.” Tẹ́nì kan bá jíǹde, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún kì í ṣe òkú mọ́, àmọ́ ẹ̀mí ti pa dà sára ẹ̀ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ kó tó kú, àwọn èèyàn á sì dá a mọ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:12, 13.
Ọ̀rọ̀ náà “àjíǹde” kò sí nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù táwọn èèyàn sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa àjíǹde wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run mí sí wòlíì Hósíà láti ṣèlérí fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Màá rà wọ́n pa dà lọ́wọ́ agbára Isà Òkú; màá gbà wọ́n pa dà lọ́wọ́ ikú.”—Hósíà 13:14; Jóòbù 14:13-15; Àìsáyà 26:19; Dáníẹ́lì 12:2, 13.
Ibo làwọn òkú máa jí dìde sí? Àwọn kan máa jí dìde sí ọ̀run kí wọ́n lè jọba pẹ̀lú Kristi. (2 Kọ́ríńtì 5:1; Ìfihàn 5:9, 10) Bíbélì pe àjíǹde sí ọ̀run ní “àjíǹde àkọ́kọ́,” ohun tí èyí sì túmọ̀ sí ni pé àwọn míì máa jí dìde lẹ́yìn ìyẹn. (Ìfihàn 20:6; Fílípì 3:11) Ìgbà àjíǹde kejì yìí ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ti kú máa jí dìde, ayé ni wọ́n á sì máa gbé.—Sáàmù 37:29.
Báwo ni àwọn òkú ṣe máa jí dìde? Ọlọ́run ti fún Jésù lágbára láti jí àwọn òkú dìde. (Jòhánù 11:25) Torí náà, Jésù máa jí “gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí” dìde, kí wọ́n lè wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. Àwọn èèyàn á dá wọn mọ̀, àwọn tó jíǹde náà á sì rántí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí wọn kí wọ́n tó kú. (Jòhánù 5:28, 29) Àwọn tí Ọlọ́run bá jí dìde sí ọ̀run máa ní ara ti ẹ̀mí, àwọn tó bá sì jí dìde sáyé máa ní ara tó ṣeé fojú rí, ara wọn á jí pépé, wọn ò sì ní ní àbùkù kankan lára.—Àìsáyà 33:24; 35:5, 6; 1 Kọ́ríńtì 15:42-44, 50.
Àwọn wo ló máa jí dìde? Bíbélì sọ pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Díẹ̀ lára àwọn tí Bíbélì pè ní olódodo ni Nóà, Sérà àti Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9; Hébérù 11:11; Jémíìsì 2:21) Àwọn tí Bíbélì sì pè ní aláìṣòdodo ni àwọn tí ò ṣẹ̀fẹ́ Ọlọ́run torí pé wọn ò láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn òfin ẹ̀ débi tí wọ́n á fi pa á mọ́.
Àmọ́, àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ hùwà burúkú, tọ́rọ̀ wọn sì ti kọjá àtúnṣe kò ní jí dìde. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò nírètí láti wà láàyè mọ́, ṣe ni wọ́n máa pa run títí láé.—Mátíù 23:33; Hébérù 10:26, 27.
Ìgbà wo ni àwọn òkú máa jí dìde? Bíbélì sọ pé ìgbà tí Kristi bá wà níhìn-ín ni Ọlọ́run máa jí àwọn tó ń lọ sọ́run dìde, àsìkò yẹn sì ti bẹ̀rẹ̀ látọdún 1914. (1 Kọ́ríńtì 15:21-23) Ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù Kristi làwọn òkú máa jíǹde sáyé, ìgbà yẹn sì ni ayé yìí máa di Párádísè.—Lúùkù 23:43; Ìfihàn 20:6, 12, 13.
Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àwọn òkú máa jí dìde? Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àjíǹde mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ṣẹlẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ṣojú àwọn èèyàn. (1 Àwọn Ọba 17:17-24; 2 Àwọn Ọba 4:32-37; 13:20, 21; Lúùkù 7:11-17; 8:40-56; Jòhánù 11:38-44; Ìṣe 9:36-42; 20:7-12; 1 Kọ́ríńtì 15:3-6) Èyí tó jọni lójú jù lọ lára wọn ni àjíǹde Lásárù, torí pé ẹ̀yìn ọjọ́ mẹ́rin tó kú ni Jésù tó jí i dìde, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì wà níbi tí Jésù ti jí i. (Jòhánù 11:39, 42) Kódà àwọn tó ń ta ko Jésù ò lè sọ pé kò jí Lásárù dìde, dípò tí wọ́n á fi sọ bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa pa Jésù àti Lásárù.—Jòhánù 11:47, 53; 12:9-11.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run lágbára láti jí àwọn òkú dìde, ó sì ń wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kì í ṣohun tó ṣòro rárá fún Ọlọ́run oníṣẹ́ àrà láti rántí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó fẹ́ jí dìde. (Jóòbù 37:23; Mátíù 10:30; Lúùkù 20:37, 38) Ọlọ́run lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde, ó sì ń wù ú jí wọn dìde! Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe rí lára Ọlọ́run láti jí àwọn òkú dìde, ó sọ pé: “Ó máa wù ọ́ gan-an láti rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”—Jóòbù 14:15.
Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní nípa àjíǹde
Èrò tí kò tọ́: Nígbà àjíǹde, ọkàn àti ara tó ti ya ara wọn tẹ́lẹ̀ máa pa dà wà pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
Òótọ́: Bíbélì kọ́ni pé odindi èèyàn ni ọkàn, kì í ṣohun kan tó wà nínú èèyàn tó sì máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn téèyàn bá kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7, àlàyé ìsàlẹ̀; Ìsíkíẹ́lì 18:4) Tí Ọlọ́run bá jí ẹnì kan dìde, kì í ṣe pé ọkàn àti ara ẹni náà ń pa dà wà pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i; ṣe ni Ọlọ́run tún ẹni náà dá kó lè wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i.
Èrò tí kò tọ́: Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ táwọn kan bá jíǹde ni Ọlọ́run tún máa pa wọ́n run.
Òótọ́: Bíbélì sọ pé “àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà” máa ní “àjíǹde ìdájọ́.” (Jòhánù 5:29) Àmọ́, ohun tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí wọ́n jíǹde ni Ọlọ́run máa fi dá wọn lẹ́jọ́, kì í ṣe ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kú. Jésù sọ pé: “Àwọn òkú máa gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọ́run, . . . àwọn tó fiyè sílẹ̀ sì máa yè.” (Jòhánù 5:25) Táwọn tó jíǹde náà bá ‘fiyè sí’ tàbí ṣègbọràn sí ohun tí wọ́n kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n jíǹde, Ọlọ́run máa kọ orúkọ wọn sínú “àkájọ ìwé ìyè.”—Ìfihàn 20:12, 13.
Èrò tí kò tọ́: Tẹ́nì kan bá jíǹde, ara tí onítọ̀hún ní gangan kó tó kú ló máa ní.
Òótọ́: Tẹ́nì kan bá ti kú, ara ẹni náà á ti jẹrà.—Oníwàásù 3:19, 20.