Kí Ni Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ìrìbọmi túmọ̀ sí kí wọ́n ri èèyàn bọmi pátápátá. a Ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣèrìbọmi ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa. (Ìṣe 2:41) Lára wọn ni Jésù tí Jòhánù rì bọmi nínú odò Jọ́dánì. (Mátíù 3:13, 16) Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Fílípì náà ri ọkùnrin ará Etiópíà kan bọmi ní “ibi tí omi wà” ní tòsí ọ̀nà tí wọ́n ti ń rìnrìn àjò.—Ìṣe 8:36-40.
Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé kí ẹnì kan tó lè di ọmọlẹ́yìn òun, ẹni náà gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi. (Mátíù 28:19, 20) Àpọ́sítélì Pétérù sì fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.—1 Pétérù 3:21.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Kí ni ìrìbọmi túmọ̀ sí?
Ìrìbọmi ni ohun tẹ́nì kan ṣe ní gbangba tó jẹ́ àmì tó ṣeé fojú rí pé ẹni náà ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣèlèrí pé òun á máa fayé òun ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Lára ohun tẹ́ni náà á máa ṣe ni pé, á máa gbé ìgbé ayé ẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ó ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti Jésù. Torí náà, ṣe làwọn tó ṣèrìbọmi ń tọ ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.
Bí wọ́n ṣe ri èèyàn bọmi pátápátá jẹ́ àmì tó fi hàn pé ẹni náà ti yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà. Lọ́nà wo? Bíbélì fi ẹni tó ṣe ìrìbọmi wé ẹni tí wọ́n sin. (Róòmù 6:4; Kólósè 2:12) Bí wọ́n ṣe ń ri ẹni náà bọmi fi hàn pé ó ti di òkú sí irú ìgbé ayé tó ń gbé tẹ́lẹ̀. Bó sì ṣe ń jáde nínú omi, fi hàn pé á máa bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé ọ̀tun bíi Kristẹni tó ti ya ara ẹ̀ sí mímọ́.
Kí ni Bíbélì sọ nípa ìsàmì tàbí ìrìbọmi fún àwọn ìkókó?
Bíbélì kò sọ ohunkóhun nípa “ìsàmì” fún àwọn ìkókó. b Bẹ́ẹ̀ sì ni kò sọ̀rọ̀ nípa ìrìbọmi fún àwọn ìkókó.
Ìrìbọmi fún àwọn ìkókó kò bá ohun tí Bíbélì sọ mu. Bíbélì sọ àwọn nǹkan kan ní pàtó tí ẹni tó bá fẹ́ ṣe ìrìbọmi gbọ́dọ̀ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó bá fẹ́ ṣe ìrìbọmi gbọ́dọ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ̀ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Bíbélì kó sì máa fi wọ́n sílò. Ó gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kó sì ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúra. (Ìṣe 2:38, 41; 8:12) Ó dájú pé àwọn ìkókó kò le ṣe àwọn ohun tá a sọ yìí.
Kí ló túmọ̀ sí láti ṣèrìbọmi ní orúkọ Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́?
Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé, ẹ máa sọ àwọn èèyàn “di ọmọ ẹ̀yìn . . . , ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Ọ̀rọ̀ náà “ní orúkọ” túmọ̀ sí pé ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi náà lóye ipò àti ọlá àṣẹ Ọlọ́run àti ti Jésù, ó sì tún mọ bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣiṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pétérù sọ fún ọkùnrin kan tó ti yarọ látìgbà tí wọ́n ti bí i pé: “Ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárẹ́tì, máa rìn!” (Ìṣe 3:6) Ńṣe ni ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé ó mọ agbára àti ọlá àṣẹ Jésù, ó sì gbà pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni òun fi wo ọkùnrin náà sàn.
Ọ̀rọ̀ náà “Baba” ń tọ́ka sí Jèhófà c Ọlọ́run. Jèhófà ni aláṣẹ tó ga jù lọ, torí pé òun ló ń Fúnni ní Ìyè, òun ni Ẹlẹ́dàá àti Olódùmarè.—Jẹ́nẹ́sísì 17:1; Ìfihàn 4:11.
Jésù Kristi ni “Ọmọ,” òun ló sì kú fún wa. (Róòmù 6:23) Ká tó lè rí ìgbàlà a gbọ́dọ̀ gbà pé Jésù ni Ọlọ́run máa lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ fún aráyé.—Jòhánù 14:6; 20:31; Ìṣe 4:8-12.
“Ẹ̀mí mímọ́” jẹ́ agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn ni pé òun ni Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́. d Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti dá gbogbo nǹkan, láti fúnni ni ìwàláàyè, òun ló sì lò láti bá àwọn wòlíì rẹ̀ àtàwọn míì sọ̀rò. Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ ni Ọlọ́run ń lò láti ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2; Jóòbù 33:4; Róòmù 15:18, 19) Ọlọ́run tún lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mí sí àwọn tó kọ Bíbélì kí wọ́n lè kọ èrò rẹ̀ sílẹ̀.—2 Pétérù 1:21.
Ǹjẹ́ ó burú láti tún ìrìbọmi ṣe?
Nígbà míì àwọn èèyàn máa ń fi ẹ̀sìn wọn sílẹ̀. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ti ṣe ìrìbọmi ní ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń lọ tẹ́lẹ̀ ńkọ́, ṣé ó burú tí wọ́n bá tún ìrìbọmi ṣe? Àwọn kan lè sọ pé ó burú nítorí ohun tó wà ní Éfésù 4:5 tó sọ pé: “Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan.” Àmọ́ ẹsẹ yìí ò sọ pé èèyàn ò lè tún ìrìbọmi ṣe. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá bọ̀ kó tó sọ ohun tó wà nínú Éfésù 4:5 fi hàn pé ọ̀rọ̀ bí àwọn Kristẹni ṣe máa wà níṣọ̀kan tó bá kan ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ló ń sọ. (Éfésù 4:1-3, 16) Ohun tó sì lè jẹ́ kí wọ́n wà níṣọ̀kan ni pé kí wọ́n máa jọ́sìn Ọlọ́run kan náà, kí wọ́n gba ohun kan náà gbọ́ tàbí kí wọ́n lóye kan náà nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Bákan náà, wọ́n gbọ́dọ̀ jọ máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ ìrìbọmi.
Ìgbà kan wà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn kan tó ti ṣẹ̀rìbọmi tẹ́lẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n tún ìrìbọmi ṣe. Ìdí sì ni pé wọn ò lóye ẹ̀kọ́ tó kún rẹ́rẹ́ nípa Kristi kí wọ́n tó ṣèrìbọmi.—Ìṣe 19:1-5.
Ohun tó lè mú kí ẹni kan tún ìrìbọmi ṣe. Kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gba ìrìbọmi ẹnì kan, irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó péye nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. (1 Tímótì 2:3, 4) Tó bá jẹ́ pé ẹ̀sìn téèyàn ń ṣe kó tó ṣèrìbọmi kì í fi ìlànà Bíbélì kọ́ni, Olọ́run kò ní tẹ́wọ́ gba irú ìrìbọmi bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 4:23, 24) Ẹni náà lè gbà pé ohun tó tọ́ lòun ṣe, àmọ́ kò ṣèrìbọmi “pẹ̀lú ìmọ̀ tó péye.” (Róòmù 10:2) Ẹni náà gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó máa fi ohun tó ń kọ́ sílò, kó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, kó sì ṣe ìrìbọmi, ìgbà yẹn ló tó lè rí ojú rere Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ pé torí àwọn nǹkan tá a sọ yìí ni ẹni náà ṣe fẹ́ tún ìrìbọmi ṣe kò burú rárá. Kódà ohun tó tọ́ ló ṣe yẹn.
Bíbélì tún mẹ́nu kan àwọn ìrìbọmi míì
Bíbélì tún mẹ́nu kan àwọn ìrìbọmi míì tó yàtọ̀ sí èyí tí àwọn ọmọ lẹ́yìn Jésù ṣe. Ẹ́ jẹ́ ká wo díẹ̀.
Ìrìbọmi tí Jòhánù Arinibọmi ṣe. e Ìrìbọmi tí Jòhánú ṣe fún àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù jẹ́ àmì ìrònúpìwàdà sí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí Òfin Mósè, ìyẹn Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. A lè sọ pé ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn náà ń múra wọn sílẹ̀ dé Mèsáyà ìyẹn Jésù tí Násárẹ́tì.—Lúùkù 1:13-17; 3:2, 3; Ìṣe 19:4.
Ìrìbọmi Jésù. Ìrìbọmi tí Jòhánù Arinibomi ṣe fún Jésù ṣàrà ọ̀tọ̀, ìdí sì ni pé ẹni pípé ni Jésù kò sì dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan. (1 Pétérù 2:21, 22) Nítorí náà kò sí ìdí fún Jésù láti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tàbí kó “bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀rí ọkàn rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Pétérù 3:21) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìrìbọmi tó ṣe jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ti ṣe tán láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, bíi Mèsáyà tàbí Kristi tá a ṣèlérí. Ìyẹn ló sì jẹ́ kó lè kú fún wa.—Hébérù 10:7-10.
Ìbatisí pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́. Jòhánù Arinibọmi àti Jésù kristi sọ̀rọ̀ nípa ìbatisí pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́. (Mátíù 3:11; Lúùkù 3:16; Ìṣe 1:1-5) Ìbatisí yìí yàtọ̀ sí ìbatisí ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́. (Mátíù 28:19) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ìwọ̀nba àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní a batisí pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́. Àwọn yìí ni Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlufáà lé ilẹ̀ ayé lórí. f (1 Pétérù 1:3, 4; Ìfihàn 5:9, 10) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tó ní ìrètí láti gbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ni wọ́n sì máa ṣàkóso lé lórí.—Mátíù 5:5; Lúùkù 23:43.
Ìbatisí sínú Kristi Jésù àti sínú ikú rẹ̀. Àwọn tí a fi ẹ̀mí mímọ́ batisí ni a tún “batisí sínú Kristi Jésù.” (Róòmù 6:3) Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó jẹ́ ẹni àmì òróró tí wọ́n sì jọ máa ṣàkóso ní ọ̀run ni a batisí lọ́nà yìí. Torí pé wọ́n batisí wọn sínú Jésù, wọ́n di ẹni àmì òróró. Jésù ni Orí, àwọn sì ni ara.—1 Kọ́ríńtì 12:12, 13, 27; Kólósè 1:18.
Àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró la tún “batisí sínú ikú [Jésù].” (Róòmù 6:3, 4) Bíi ti Jésù, wọ́n máa ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn, wọ́n sì máa ń yááfì ìrètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ̀yìn tí wọ́n bá kú tí Ọlọ́run sì jí wọn dìde sí ọ̀run bí ẹ̀dá ẹ̀mí ni ìbatisí ìṣàpẹẹrẹ yìí máa parí.—Róòmù 6:5; 1 Kọ́ríńtì 15:42-44.
Ìbatisí pẹ̀lú iná. Jòhánù Arinibọmi sọ fún àwọn èèyàn pé: “Ẹni yẹn [Jésù] máa fi ẹ̀mí mímọ́ àti iná batisí yín. Ṣọ́bìrì tó fi ń fẹ́ ọkà wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì máa gbá ibi ìpakà rẹ̀ mọ́ tónítóní, ó máa kó àlìkámà rẹ̀ jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, àmọ́ ó máa fi iná tí kò ṣeé pa sun ìyàngbò.” (Mátíù 3:11, 12) Ẹ kíyè si pé ìyàtọ̀ wà nínú ká fi ẹ̀mí mímọ́ batisí ẹnì kan àti ká fi iná batisí ẹnì kan. Kí ni àpèjúwe Jòhánù yìí túmọ̀ sí?
Àlìkámà dúró fún àwọn tó ń tẹ́tí sí Jésù tí wọ́n sì ń ṣègbọràn. Àwọn yìí nírètí pé Ọlọ́run máa fi ẹ̀mí mímọ́ batisí wọn. Ìyàngbò dúró fún àwọn tí kò ní ṣègbọràn sí Jésù, ìbatisí nínú iná ló ń dúró de irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, èyí tó túmọ̀ sí ìparun yán-ányán-án.—Mátíù 3:7-12; Lúùkù 3:16, 17.
a Bí ìwé Vine’s Complete Expository Dictionary of Old and New Testament Words ṣe sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìbatisí” túmọ̀ sí “kí wọ́n ri èèyàn bọ inú omi, kí omi boni mọ́lẹ̀ pátápátá, kí ẹni náà sì tún jáde láti inú omi.”
b “Ìsàmì” ń tọ́ka sí ayẹyẹ táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kan máa ń ṣe níbi tí wọ́n ti máa ń fún ọmọ ìkókọ́ ní orúkọ, wọ́n á sì “batisí” rẹ̀ ní ti pé wọ́n á wọ́n omi sí i lórí tàbí kí wọ́n dà á sí i lára.
c Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”
d Ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?”
e Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jòhánù Arinibọmi?”
f Ka àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?”
g Bíbélì tún máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ìbatisí” láti ṣàlàyé àwọn ayẹyẹ kan tí wọ́n wọ́n máa ń fi ṣe ìwẹ̀mọ́, bí dída omi sórí ife, ṣágo àtàwọn nǹkan míì. (Máàkù 7:4; Hébérù 9:10) Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ìrìbọmi tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ṣe.