Kí Ló Yẹ Kí O Ṣe Kó O Lè Lóye Bíbélì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì sọ ohun tó yẹ ká ṣe ká lè lóye ohun tí a bá kà. Láìka irú èèyàn tó o jẹ́ tàbí ibi tí o ti wá sí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì “kò ṣòro rárá fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ibi jíjìnnàréré.”—Diutarónómì 30:11.
Àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe kí o lè lóye Bíbélì
Ní èrò tó dáa. Gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ torí Ọlọ́run kórìíra àwọn agbéraga. (1 Tẹsalóníkà 2:13; Jákọ́bù 4:6) Àmọ́, dípò kó o kàn máa gba ohun tó o kà tàbí tí wọ́n sọ fún ọ gbọ́, ńṣe ni Ọlọ́run fẹ́ kó o máa lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ.—Róòmù 12:1, 2.
Gbàdúrà fún ọgbọ́n. Bíbélì sọ ní Òwe 3:5 pé: “Má . . . gbára lé òye tìrẹ.” Kàkà bẹ́ẹ̀, “máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run” pé kó fún ọ ní ọgbọ́n kó o lè máa lóye Bíbélì.—Jákọ́bù 1:5.
Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrè ni wàá jẹ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé dípò kó o máa kà á ní ìdákúrekú.—Jóṣúà 1:8.
Máa yan àkòrí tí wàá kẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀nà kan tó dáa tí o lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ ni pé kó yan àkòrí tàbí kókó ẹ̀kọ́ kan tó fẹ́ kọ́ nípa rẹ̀, kó wá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ níbi àwọn “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́” inú Bíbélì, lẹ́yìn náà, kó o “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú,” ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀. (Hébérù 6:1, 2) Wàá máa fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wé ara wọn, tí wàá sì wá rí bí apá kan nínú Bíbélì ṣe ṣàlàyé apá míì tó “nira láti lóye.”—2 Pétérù 3:16.
Ní kí àwọn ẹlòmíì ràn ọ́ lọ́wọ́. Bíbélì rọ̀ wá pé ká jẹ́ kí àwọn tó lóye Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀. (Ìṣe 8:30, 31) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Bíi ti àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tọ́ka sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa jẹ́ kí àwọn tí wọ́n ń kọ́ lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an.—Ìṣe 17:2, 3.
Àwọn nǹkan tí o kò nílò tó o bá fẹ́ lóye Bíbélì
Ọgbọ́n orí tàbí ẹ̀kọ́ ìwé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ka àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù méjìlá sí “àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù,” síbẹ̀ wọ́n lóye Ìwé Mímọ́, wọ́n sì tún kọ́ àwọn ẹlòmíì.—Ìṣe 4:13.
Owó. Ọ̀fẹ́ ni wàá máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mátíù 10:8.