Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọtí? Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Kí Èèyàn Máa Mu Ọtí?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọtí? Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Kí Èèyàn Máa Mu Ọtí?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kí èèyàn mu ọtí níwọ̀nba. Bíbélì pe wáìnì ní ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó ń mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ gbádùn mọ́ni. (Sáàmù 104:14, 15; Oníwàásù 3:13; 9:7) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé wáìnì ṣe pàtàkì fún ìlera wa.​—1 Tímótì 5:23.

 Jésù mu wáìnì nígbà tó wà láyé. (Mátíù 26:29; Lúùkù 7:34) Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe tá a mọ̀ dáadáa ni pé ó sọ omi di ọtí wáìnì níbi àsè ìgbéyàwó kan.​—Jòhánù 2:1-​10.

Ewu tó wà nínú ọtí àmujù

 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ ohun tó dára nípa wáìnì, síbẹ̀ ó ní ká má ṣe mu ọtí ní àmujù tàbí ní àmupara. Torí náà, ó yẹ kí Kristẹni tó bá fẹ́ láti mu ọtí mu ún níwọ̀ntúnwọ̀nsì. (1 Tímótì 3:8; Títù 2:2, 3) Bíbélì sọ àwọn ìdí tó fi yẹ ká yẹra fún ọtí àmujù.

  •   Ọtí àmujù kì í jẹ́ kí èèyàn ronú bó ṣe yẹ. (Òwe 23:29-​35) Ẹni tó mùtí yó kò lè pa àṣẹ Bíbélì yìí mọ́, àṣẹ náà ni pé “ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.”​—Róòmù 12:1.

  •   Ọtí àmujù kì í jẹ́ kéèyàn bẹ̀rù tàbí kó tijú, ó sì máa ń “gba ète rere kúrò.”​—Hóséà 4:11; Éfésù 5:18.

  •   Ọtí àmujù lè sọni di òtòṣì tàbí kó ṣàkóbá fún ìlera.​—Òwe 23:21, 31, 32.

  •   Ọlọ́run kórìíra ọtí àmujù àti àmupara.​—Òwe 23:20; Gálátíà 5:19-​21.

Báwo ni mo ṣe lè mọ ìwọ̀n ọtí tó yẹ kí n mu?

 Ọtí tí ẹnì kan mu ti pọ̀ jù tó bá jẹ́ pé ọtí náà ṣe àkóbá fún ẹni tó mu ún tàbi àwọn ẹlòmíì. Ohun tí Bíbélì sọ fi hàn pé tí ẹnì kan bá mutí yó kì í dákú, àmọ́ á máa hùwà bí ẹni tí kò ní láàákàyè, á máa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, á máa bínú tàbí kó máa sọ ìsọkúsọ. (Jóòbù 12:25; Sáàmù 107:27; Òwe 23:29, 30, 33) Àwọn tí kò mutí yó pàápàá ṣì lè di ẹni “tí a dẹrù pa pẹ̀lú . . . ìmutíyó kẹ́ri” kí wọ́n sì jìyà àbájáde rẹ̀.​—Lúùkù 21:34, 35.

Ìgbà tó yẹ kéèyàn yẹra fún ọtí pátápátá

 Bíbélì mẹ́nu ba àwọn ìgbà tí kò yẹ kí ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni máa mu ọtí:

  •   Tó bá ti máa ṣe àkóbá fún àwọn ẹlòmíì.​—Róòmù 14:21.

  •   Tí ìjọba bá fòfin de ọtí mímu.​—Róòmù 13:1.

  •   Téèyàn kò bá lè kápá bó ṣe ń mu ọtí. Àwọn tí wọ́n sì ti sọ ọtí mímu di bárakú tàbí tí wọ́n máa ń mu ọtí ní àmupara pàápàá gbọ́dọ̀ tètè gbé ìgbésẹ̀.​—Mátíù 5:29, 30.