ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́
Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
Àwọn tọkọtaya kan tí àárín wọn ò gún máa ń ronú pé, á sàn káwọn kọ ara àwọn sílẹ̀ torí ìyẹn á ṣe àwọn ọmọ wọn láǹfààní. Èrò wọn ni pé ìyẹn dáa ju kí àwọn ọmọ máa gbé pẹ̀lú àwọn òbi tí ò gbọ́ ara wọn yé. Kí ni ẹ̀rí fi hàn?
Kí ni àbàjáde ìkọ̀sílẹ̀ lórí àwọn ọmọ?
Ìwádìí ti fi hàn pé àkóbá ńlá ni ìkọ̀sílẹ̀ máa ń ṣe fáwọn ọmọ. Àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn kọ ara wọn sílẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í:
bínú, kí ọkàn wọn má balẹ̀, kí wọ́n sì máa sorí kọ́
hu ìwàkiwà
fìdí rẹmi tàbí kí wọ́n má parí ilé ìwé wọn
ṣàìsàn
Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ló máa ń dá ara wọn lẹ́bi pé àwọn làwọn fa ìkọ̀sílẹ̀ náà, tàbí pé àwọn ò ṣe ohun tó yẹ káwọn ṣe.
Àwọn ìṣòro tí àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn kọ ara wọn sílẹ̀ máa ń ní lè bá wọn dàgbà. Bí wọ́n ṣe ń dàgbà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan, kò sì ṣòro fún wọn láti fọkàn tán àwọn míì. Tí wọ́n bá sì ṣègbéyàwó lọ́jọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe kí wọ́n kọ ẹnì kejì wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá dojú kọ àwọn ìṣòro.
Kókó ibẹ̀ rèé: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan tó ń gbèrò láti kọ ara wọn sílẹ̀ máa ń ronú pé ohun tó máa dáa jù fáwọn ọmọ wọn nìyẹn, àmọ ìwádìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó mọ̀ nípa ìtọ́jú àwọn ọmọ, ìyẹn Penelope Leach a sọ pé: “Ìkọ̀sílẹ̀ máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ọmọ.”
Ìlànà Bíbélì: “Bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”—Fílípì 2:4.
Ṣé inú ọmọ mi máa dùn sí i, tá a bá kọ ara wa sílẹ̀?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ pé bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ fi sọ́kàn pé ohun tí àwọn òbí nílò àti ohun táwọn ọmọ nílò sábà máa ń yàtọ̀ síra wọn. Ńṣe ni ẹni tó ń gbèrò ìkọ̀sílẹ̀ ń fẹ́ ìgbésí ayé tuntun. Ní ti àwọn ọmọ, ohun táwọn sábà máa ń fẹ́ ni pé kí àwọn máa bá ìgbésí ayé wọn lọ pẹ̀lú Dádì àti Mọ́mì wọn tí wọ́n jọ wà papọ̀.
Lẹ́yìn táwọn tó kọ ìwé The Unexpected Legacy of Divorce ṣe àyẹ̀wò ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìkọ̀sílẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ohun kan wà tó ṣe kedere: àwọn ọmọ ò sọ pé inu àwọn dùn jù ti ìgbà táwọn òbí àwọn ò tíi kọ ara wọn sílẹ̀ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n sọ ní ṣàkó pé, ‘Ọ̀jọ tí àwọn òbí mí kọ ara wọ́n sílẹ̀ ni ìgbésí ayé mi ti yí pa dà.’ ” Ìwé náà fi kún un pé, lójú wọn “kò sẹ́ni tó ṣe é fọkàn tán, torí àwọn òbí tí wọ́n fọkàn tán ti já wọn kulẹ̀.”
Kókó ibẹ̀ rèé: Àwọn ọmọ kì í sábà láyọ̀ táwọn òbí wọn bá kọ ara wọn sílẹ̀.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ̀mí tí ìdààmú bá máa ń tánni lókun.”—Òwe 17:22.
Kí ni mo gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa bí àwọn òbi tó ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe lè jùmọ̀ tọ́mọ?
Àwọn kan tó ti kọ ara wọn sílẹ̀ máa ń gbìyańjú láti máa tọ́ ọmọ wọn bíi pé àwọn ṣì wà pa pọ̀. Wọ́n ronú pé àwọn lè jùmọ̀ máa pín àwọn ojúṣe títọ́ ọmọ wọn lọ́gbọọgba. Bó ti wù kó rí, èyí kì í rọrùn rárá. Ìwádìí ti fi hàn pé àwọn tó ti kọ ara wọn sílẹ̀:
kì í lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn
sábà máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn ìlànà tó ta kora
sábà máa ń ṣe gbogbo ohun táwọn ọmọ bá fẹ́ kí wọ́n lè fìyẹn tu ara wọn nínú tàbí kó jẹ́ torí pé ó ti rẹ̀ wọ́n.
Nígbà míì, àwọn ọmọ tí òbí wọn kọ ara wọn sílẹ̀ kì í gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu. Ó ṣe tán, àwọn òbí náà kò kúkú fi àpẹẹrẹ ìwà tó dáa lélẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọn ò jólóòótọ́ sí ara wọn, wọn ò fọkàn tán ara wọn, wọn o sì pa àdéhùn tí wọ́n ṣe fún ara wọn mọ́. Ọmọ kan lè wá máa ronú pé: ‘Kí nìdí ti máa fi gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu?’
Kókó ibẹ̀ rèé: Ó máa ń ṣoro fún àwọn òbi tó ti kọ ara wọn sílẹ̀ láti jùmọ̀ tọ́mọ. Àmọ, ọ̀rọ̀ náà wá túbọ̀ ṣòro gan-an fún àwọn ọmọ.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọ́n má bàa soríkodò.”—Kólósè 3:21, àlàyé ìsàlẹ̀.
Ṣé ọ̀nà míì tó sàn jù wà tá a fi lè yanjú àwọn ìṣòro yìí?
Lọ́pọ̀ ìgbà, ká sọ pé ìsapá tí tọkọtaya máa ń ṣe lórí ìkọ̀sílẹ̀ ni wọ́n ṣe lórí ìgbéyàwó wọn, àárín wọn ò bá má dàrú. Ìwé The Case for Marriage sọ pé: “Ti pé ìgbéyàwó kan kò dùn lónìí, kò túmọ̀ sí pé kò lè dáa lọ́la bí àwọn kan ṣe rò. Ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya tí ò láyọ̀ báyìí síbẹ̀ tí wọ́n ń gbé pa pọ̀ ṣì máa ń láyọ̀ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn ọmọ máa ń ṣe dáadáa, wọ́n sì máa ń láyọ̀ tí àwọn òbí wọn bá wà pa pọ̀.
Èyí kò túmọ̀ sí pé ìkọ̀sílẹ̀ ò lè wáyé láwọn ìgbà míì. Kódà, Bíbélì sọ pé tọkọtaya lè kọ ara wọn sílẹ̀ tí ọ̀kan nínú wọn bá ṣe ìṣekúṣe. (Mátíù 19:9) Àmọ́ ṣá o, Bíbélì tún sọ pé “aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.” (Òwe 14:15) Àwọn tí ìgbéyàwó wọn ní ìṣòro tí wọ́n sì ń ronú láti kọ ara wọn sílẹ̀ gbọ́dọ̀ yiiri ọ̀rọ̀ náà wò dáadáa, kí wọ́n sì ronú lórí àkóbá tí èyi máa ṣe fáwọn ọmọ wọn.
Síbẹ̀ èyí ò túmọ̀ sí pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa forí rọ́ ìṣòro wọn láìṣe ohunkóhun nípa ẹ̀. Bíbélì sọ ohun tí tọkọtaya lè ṣe kí ìgbéyàwó wọn lè dùn bí oyin, kí wọ́n sì bá ara wọn kalẹ́. Ìyẹn ò sì yani lẹ́nu torí pé Jèhófà Ọlọ́run tó ni Bíbélì, náà ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀.—Mátíù 19:4-6.
Ìlànà Bíbélì: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.”—Àìsáyà 48:17.
a Látinú ìwé náà Your Growing Child—From Babyhood Through Adolescence.