Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Máa Ṣe Nǹkan Láṣeyanjú

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Máa Ṣe Nǹkan Láṣeyanjú

 Iṣẹ́ kan wà tí wọ́n gbé fọ́mọ ẹ pé kó ṣe, nígbà tó bá a dé àárín kan, ó sọ pé: “Ẹ wò ó, ó ti lè jù, mi ò rò pé màá lè ṣe rárá!” Lédè míì, ó ti sú u, ó sì fẹ́ pa á tì. Ìwọ náà mọ̀ pé iṣẹ́ náà nira díẹ̀, kò sì wù ẹ́ kó làágùn jìnnà. Síbẹ̀, ó fẹ́ kó mọ béèyàn ṣe ń forí ti ohun tó nira. Kí lo máa wá ṣe báyìí? Ṣé wàá gbaṣẹ́ náà lọ́wọ́ ẹ̀ ni, kó o lè bá a ṣe é? Àbí, wàá ní kó pa iṣẹ́ náà tì? Àbí kẹ̀, ṣé wàá lo àǹfààní yẹn láti kọ́ ọmọ rẹ béèyàn ṣe ń forí ti nǹkan?

Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn

 Ó yẹ kéèyàn mọ bí wọ́n ṣe ń forí ti nǹkan. Ó ṣe pàtàkì káwọn òbí kọ́ ọmọ wọn nípa béèyàn ṣe ń ní àforítì nígbèésí ayé, pàápàá lẹ́nu iṣẹ́. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kírú ọmọ bẹ́ẹ̀ jáfáfá, kó sì máa ṣe dáadáa nílé ẹ̀kọ́. Yàtọ̀ síyẹn, á mọ béèyàn ṣe ń mú nǹkan mọ́ra, ara ẹ̀ á sì dá ṣáṣá. Bákan náà, tọ́mọ rẹ bá ní àforítì, á láwọn ọ̀rẹ́ gidi, àwọn èèyàn á sì gbádùn bíba a ṣiṣẹ́. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, táwọn òbí ò bá jẹ́ kí ọmọ wọn kọ́ béèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́ kára tàbí béèyàn ṣe ń kápá ìṣòro, bópẹ́ bóyá, ó lè máa ṣe ọmọ náà bíi pé òun ò mọ nǹkan ṣe, ó lè rẹ̀wẹ̀sì, kódà ó lè má níyì lójú ara ẹ̀ tó bá dàgbà.

 A lè kọ́ béèyàn ṣe ń ní àforítì. Àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá lè kọ́ béèyàn ṣe ń fàyà rán ìṣòro láìbọ́hùn. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn ọmọ tí ò ju ọdún kan àtoṣù mẹ́ta lọ, wọ́n rí i pé lẹ́yìn táwọn ọmọ náà kíyè sí báwọn àgbàlagbà ṣe tiraka láti ṣe ohun kan yọrí, ìyẹn máa ń jẹ́ káwọn náà gbìyànjú, kí wọ́n sì tiraka nídìí ohun tí wọ́n bá ń ṣe.

 “Mo rántí ìgbà tí mò ń kọ́ àwọn ọmọbìnrin mi bí wọ́n ṣe lè de okùn bàtà wọn. Ẹ̀yin náà mọ̀ pé àkọ́túnkọ́ léèyàn ń kọ́ ọmọdé ní nǹkan. Tí wọ́n bá fẹ́ de okùn náà fúnra wọn, bí wọ́n ṣe ń fà á síbí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á máa fà á sọ́hùn. Ó máa ń gbà wọ́n níṣẹ̀ẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nígbà míì. Tí wọn ò bá wá rí i dè, mo máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù àti ìgbìyànjú, pẹ̀lú omijé lójú nígbà míì, wọ́n mọ okùn bàtà wọn dè fúnra wọn. Ká ní bàtá tí kò lókùn ni mo rà fún wọn ni, nǹkan ì bá dẹrùn fún èmi alára. Àmọ́, ṣé wọ́n á mọ béèyàn ṣe ń de okùn bàtà? Torí náà, ó ṣe pàtàkì káwa òbí náà ní àforítì, ìyẹn lá jẹ́ ká lè kọ́ àwọn ọmọ wa nípa béèyàn ṣe ń ní àforítì.”​—Colleen.

 Láìmọ̀, a lè ṣe ohun tí kò ní jẹ́ káwọn ọmọ wa ní àforítì. Àwọn òbí kan lè mú káwọn ọmọ wọn dẹni tí ò ní àforítì mọ́. Lọ́nà wo? Àwọn òbí kan kì í fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn dààmú rárá, tí wọ́n bá ti kojú ìṣòro kékeré báyìí, kíá láwọn òbí náà ti máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́, ìṣòro kan wà tíyẹn máa ń fà. Ẹ gbọ́ ohun tí òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Jessica Lahey sọ, ó ní: “Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà tí ọmọ wa bá níṣẹ́ kan tó le díẹ̀ la máa ń bá a ṣe é, ohun tá à ń dọ́gbọ́n sọ ni pé ọgbọ́n ẹ̀, làákàyè ẹ̀, àti agbára ẹ̀ kù díẹ̀ káàtó. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ń dọ́gbọ́n sọ fún un pé kò ṣe é fọkàn tán.” a Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sírú ọmọ bẹ́ẹ̀? Nǹkan á tètè máa sú u, á máa ronú pé ó dìgbà tí àgbàlagbà kan bá ran òun lọ́wọ́ kóun tó lè ṣe ohunkóhun yọrí.

Dípò tí wàá fi bá ọmọ ẹ̀ ṣe gbogbo ohun tó bá ti le díẹ̀, o lè kọ́ ọ kó lè ní àforítì

Ohun tó o lè ṣe

 Kọ́ wọn láti máa ṣiṣẹ́ kára. Ẹ̀yin òbí lè kọ́ àwọn ọmọ yín nípa béèyàn ṣe ń ní àforítì tẹ́ ẹ bá ń fún wọn níṣẹ́ tí agbára wọn gbé. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè ní kí ọmọ ọdún mẹ́ta sí márùn-ún ṣa àwọn aṣọ tó dọ̀tí jọ tàbí kó palẹ̀ àwọn ohun ìṣeré ẹ̀ mọ́. Ẹ lè ní káwọn ọmọ ọlọ́dún mẹ́fà sí méjìlá kó àwọn nǹkan tẹ́ ẹ rà bọ̀ lọ́jà síbi tó yẹ, kí wọ́n to abọ́, kí wọ́n sì palẹ̀ wọn mọ́ tẹ́ ẹ bá jẹun tán. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ lè ní kí wọ́n gbálẹ̀, kí wọ́n da ìdọ̀tí nù tàbí kí wọ́n nu ilẹ̀. Ẹ lè ní káwọn ọmọ tó ti lé lọ́mọ ọdún méjìlá ṣe àwọn iṣẹ́ míì tó tún le díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè ní kí wọ́n tún ilé tàbí àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe. Kì í fìgbà gbogbo yá àwọn ọmọdé lára láti ṣiṣẹ́ ilé. Àmọ́ tẹ́yin òbí bá jẹ́ kí wọ́n mọ ojúṣe wọn nínú ilé, tẹ́ ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, á ṣe wọ́n láǹfààní gan-an. Àǹfààní kan ni pé wọn ò ní ya ọ̀lẹ, wọn ò sì ní máa bẹ̀rù àtiṣiṣẹ́ tó lágbára tí wọ́n bá dàgbà.

 Ìlànà Bíbélì: “Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè.”​—Òwe 14:23.

 “Má kàn fún àwọn ọmọ ẹ níṣẹ́ tí ò nítumọ̀ torí kí wọ́n má bàa yọ ẹ́ lẹ́nu. Kó sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ sírú nǹkan bẹ́ẹ̀, títí kan àwọn ọmọdé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ gbéṣẹ́ kéékèèké tó nítumọ̀ tí wọ́n lè bá yín ṣe fún wọn. Tí ọmọ ẹ bá ṣì kéré, o lè ní kó nu àwọn nǹkan tí ọwọ́ ẹ̀ tó, bíi tábìlì àtàwọn àga inú ilé. Tó o bá ń fọ mọ́tò, o lè ní kó fọ àwọn apá ìsàlẹ̀ mọ́tò náà, dípò tí wàá fi máa bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ láti fọ̀ ọ́. Má sì gbàgbé láti gbóríyìn fún un.”​—Chris.

 Máa tọ́ ọmọ ẹ sọ́nà tó bá ń ṣiṣẹ́ tó lè díẹ̀. Àwọn ìgbà míì wà tó lè má rọrùn fún ọmọ kan láti ṣiṣẹ́ kan yanjú torí pé kò fi bẹ́ẹ̀ yé e. Torí náà, tó bá jẹ́ iṣẹ́ tọ́mọ ẹ̀ ò ṣe rí lo ní kó ṣe, o lè fi àwọn àbá tá a máa sọ yìí sílò. Àkọ́kọ́, ṣe iṣẹ́ náà lójú ọmọ ẹ. Lẹ́yìn náà, ẹ jọ ṣe é. Lẹ́yìn ìyẹn, ní kó o ṣe lójú ẹ, kó o sì máa tọ́ ọ sọ́nà nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Paríparí ẹ̀, ní kóun fúnra ẹ̀ dá ṣe iṣẹ́ náà.

 Ìlànà Bíbélì: “Torí mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.”​—Jòhánù 13:15.

 “Ohun tí mo rí ni pé, àpẹẹrẹ àwa òbí ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ káwọn ọmọ wa mọ béèyàn ṣe ń forí ti nǹkan. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwà wa àti ojú tá a fi ń wo nǹkan.”​—Doug.

 Jẹ́ kọ́mọ ẹ mọ̀ pé kò sí adára-má-kù-síbì-kan. O lè sọ àwọn ìgbà kan tíwọ náà ò ṣe dáadáa tó, àmọ́ tó ò jẹ́ kó sú ẹ. Jẹ́ kó mọ̀ pé téèyàn bá ń ṣiṣẹ́ kan fúngbà àkọ́kọ́, ó lè má rọrùn, èèyàn sì lè ṣàṣìṣe torí pé àṣìṣe ò lọ́gàá. Fi ọmọ ẹ lọ́kàn balẹ̀ pé ti pé ó ṣàṣìṣe nídìí iṣẹ́ ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé o ò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ mọ́. Ṣe lọ̀rọ̀ fíforí ti nǹkan dà bí iṣan ara èèyàn, béèyàn bá ṣe túbọ̀ ń lò ó lá máa lágbára sí i. Lọ́nà kan náà, tó o bá ń jẹ́ kọ́mọ ẹ ṣiṣẹ́ tó bá ọjọ́ orí ẹ̀ mu bíṣẹ́ ọ̀hún tiẹ̀ le, á jẹ́ kó kọ́ bó ṣe lè túbọ̀ ní àforítì. Torí náà, tó bá dà bíi pé iṣẹ́ kan ṣòro fún un, mú sùúrù, jẹ́ kó gbìyànjú gbogbo ohun tó lè ṣe, dípò tí wàá fi bá a ṣe. Ìwé How Children Succeed sọ ohun kan lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Tó o bá fẹ́ kí ọmọ ẹ yàn kó yanjú, kó sì hàn pé òṣìṣẹ́ kára ni, ohun tó dáa jù tó o lè ṣe ni pé kó o jẹ́ kó ṣe ohun tó rò pé òun ò ní lè ṣe.”

 Ìlànà Bíbélì: “Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.”​—Ẹkun Jeremiah 3:27, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

 “Tó o bá gbéṣẹ́ fáwọn ọmọ ẹ, tíṣẹ́ náà sì máa gba pé kí wọ́n tiraka gidigidi nídìí ẹ̀, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ọkàn wọn á balẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni wọ́n á sì rí kọ́. Nígbà tí wọ́n bá fi máa ṣe iṣẹ́ náà yọrí, wọn ò ní rántí pé àwọn làágùn nídìí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á túbọ̀ já fáfá, wọ́n á sì rí i pé iyì wà nínú kéèyàn ní àforítì.”​—Jordan.

 Máa yìn ín fún ìsapá ẹ̀, kì í ṣe torí ọgbọ́n ẹ̀ nìkan. Dípò tí wàá fi sọ fọ́mọ ẹ pé, “Ọmọ, iṣẹ́ lo ṣe nínú ìdánwò yẹn! Ọpọlọ ẹ pé, ó kọjá bẹ́ẹ̀,” o lè sọ pé, “Ọmọ, iṣẹ́ lo ṣé nínú ìdánwò yẹn! Mo mọyì bó o ṣe múra ìdánwò náà sílẹ̀, tó o sì kàwé ẹ̀ dáadáa.” Kí nìdí tó fi dáa kó o gbóríyìn fún un torí ìsapá ẹ̀ dípò torí ọgbọ́n ẹ̀? Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Carol Dweck sọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ torí ọgbọ́n ọmọ kan la ṣe ń yìn ín. Ó ní: “Àyà irú ọmọ bẹ́ẹ̀ á máa já tó bá di pé kó ṣe iṣẹ́ tó díjú tàbí èyí tó gba kéèyàn sapá gidigidi.” Ọmọwé náà wá fi kún un pé: “Ẹ̀bùn tó dáa jù táwọn òbí lè fún àwọn ọmọ wọn ni pé kí wọ́n ṣe ohun táá jẹ́ káwọn ọmọ nífẹ̀ẹ́ àtimáa fara ṣiṣẹ́, kí wọ́n mọ béèyàn ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe, kí wọ́n lẹ́mìí béèyàn ṣe lè sunwọ̀n lẹ́nu iṣẹ́ tó ò ń ṣe, kó sì máa wù ú láti gba ìmọ̀ kún ìmọ̀. Táwọn òbí bá ṣe ohun tá a sọ yìí, àwọn ọmọ wọn á máa gbájú mọ́ ohun tó ṣe pàtàkì dípò kí wọ́n máa retí ìyìn látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn.” b

 Ìlànà Bíbélì: “Ìyìn tí ẹnì kan gbà . . . ń dán an wò.”​—Òwe 27:21.

a Látinú ìwé The Gift of Failure.

b Látinú ìwé Mindset.