Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Bí A Ṣe Lè Ran Awọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Borí Ìjákulẹ̀

Bí A Ṣe Lè Ran Awọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Borí Ìjákulẹ̀

 Bópẹ́ bóyá, àwọn ọmọ rẹ máa dojú kọ àwọn ohun tó máa já wọ́n kulẹ̀ tàbí kí wọ́n kùnà nínú ohun tí wọ́n ń ṣe. Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́fẹ padà?

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

 Gbogbo èèyàn ló máa ń ní ìjákulẹ̀. Bíbélì sọ pé, “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jémíìsì 3:2) Àwọn ọmọ náà máa ń ṣàṣìṣe. Àmọ́, ìjákulẹ̀ lè ṣeni láǹfààní, ó máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ fara da ipò ṣòro. A kì í bí ìfaradà mọ́ èèyàn, ńṣe la máa ń kọ́ ọ.

Ìyá kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Laura sọ pé: “Èmi àti ọkọ mí ti ṣàkíyèsí pé ó dáa káwọn ọmọ kọ́ bí wọn ṣe lè borí ìjákulẹ̀ ju kí wọ́n díbọ́n pé kò sóhun tó ń jẹ́ ìjákulẹ̀. Wọ́n á lè kọ́ bá a ṣé ń ní àforítì nígbà tí nǹkan ò bá lọ dáadáa”.

 Ọ̀pọ̀ ọmọ ni kó mọ béèyàn ṣe lè borí ìjákulẹ̀. Àwọn ọmọ kan kò tíì kọ́ bí wọn ṣe lè borí ìjákulẹ̀ torí pé àwọn òbí wọn kì í jẹ́ kí wọ́n mọ ẹ̀bi wọn lẹ́bi. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ kàn ò bá ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, àwọn òbí kan máa ń sọ pé àwọn olùkọ́ ló fà á. Tí ọmọ kan bá ní èdèkòyédè pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀, àwọn òbí kan máa sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló jẹ̀bi.

  Ní ti tòótọ́, báwo ní àwọn ọmọ ṣe lè kọ́ bí wọ́n ṣe lè gba ẹ̀bi wọn lẹ́bi nígbà táwọn òbí ò bá fẹ́ kí wọ́n jìyà ohun tí wọ́n ṣe?

Ohun tó o lè ṣe

  •   Kọ́ àwọn ọmọ rẹ pé gbogbo ìwà wọn ló máa ní ìyọrísí.

     Bíbélì sọ pé: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.”—Gálátíà 6:7.

     Gbogbo nǹkan téèyàn bá ṣe ló máa ń ní ìyọrísí. Tí èèyàn bá ba nǹkan jẹ́, ó máa ná an ní nǹkan láti tún un ṣe. Gbogbo àṣìṣe ló ní wàhálà tó ń bá a rìn. Ó yẹ kí àwọn ọmọ mọ̀ pé ohun téèyàn bá gbìn ló máa ká, kí wọn sì mọ̀ pé àwọn máa gba ẹ̀bi ohun táwọn ṣe. Torí náà, yẹra fún dídá ẹlòmíì lẹ́bi tàbí wíwá àwáwí nítorí àwọn ọmọ rẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí wọ́n jìyà àṣìṣe wọn lọ́nà tó bá ọjọ́ orí wọn mu. Ó yẹ kí ọmọ kan mọ̀ kedere pé ìwà tí ò dáa máa fa ìyà bá ẹni tó hù ú.

  •  Ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti wá ojútùú.

     Ìlànà Bíbélì: “Nítorí olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje, á sì tún dìde.”—Òwe 24:16.

     Ìjákulẹ̀ máa ń dunni gan-an, àmọ́ kò túmọ̀ sí pé èèyàn ò lè ṣe dáadáa mọ́. Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ bí wọ́n ṣe máa rí ojútùú dípò tí wọ́n a fí jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà kó ìdààmú bá wọn. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ rẹ ò bá ṣe dáadáa nínú ìdánwò nílé ẹ̀kọ́, ràn án lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe lè kàwé dáadáa kó sì pinnu láti ṣe dáadáa nígbà míì. (Òwe 20:4) Tí ọmọbìnrin rẹ bá ní èdèkòyédè pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀, ràn án lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe lè fi ẹ̀bẹ̀ yanjú ọ̀rọ̀ náà láì sọ pé ẹnì kan ló jẹ̀bi.—Róòmù 12:18; 2 Tímótì 2:24.

  •   Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti mọ̀wọ̀n ara wọn.

     Ìlànà Bíbélì: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.”—Róòmù 12:3.

     Tó o bá sọ fún ọmọ rẹ pé òun ló mọ nǹkan ṣe ju lọ, ìyẹn kì í ṣòótọ́, kò sí ní ràn án lọ́wọ́. Ó ṣe tán, àwọn ọmọ tó ṣe dáadáa gan-an nínú ẹ̀kọ́ wọn, lè má gba máàkì tó dáa jù lọ ní gbogbo ìgbà. Àwọn ọmọ tó tayọ nínú àwọn eré ìdárayá kan, kì í fìgbà gbogbo gba ipò kìíní. Àwọn ọmọ tó mọ̀wọ̀n ara wọn tètè máa ń borí ìjákulẹ̀ àti ìfàsẹ́yìn.

     Bíbélì sọ pé ìpọ́njú lè mú ká di alágbára, ó sì máa jẹ́ ká ní ìfaradà. (Jémíìsì 1:2-4) Torí náà, bí ìjákulẹ̀ àti ìfàsẹ́yìn bá tiẹ̀ ń fa ìbànújẹ́, o lè ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti fojú tó dáa wò wọ́n.

     Kíkọ́ ọmọ rẹ láti ní ìfaradà dà bí ìgbà téèyàn ń kọ́ ọmọ bó ṣe máa ṣe nǹkan, ó máa gba àkókò àti ìsapá. Àmọ́, èrè ẹ̀ pọ̀ lọ́jọ́ iwájú nígbà tí wọ́n bá dàgbà. “Àwọn ọ̀dọ́ tó mọ bá a ṣe ń fara da nǹkan, kì í sábà hùwà òmùgọ̀ nígbà tí nǹkan bá tojú sú wọn. Ó ṣeé ṣe kí wọn ṣe dáadáa nínú ipòkípò tó bá yọjú àti ipò àìròtẹ́lẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí ìwé Letting Go With Love and Confidence ṣe sọ. Ó dájú pé wọ́n máa jàǹfààní ìfaradà tí wọ́n ti kọ yẹn nígbà tí wọ́n bá dàgbà pàápàá.

 Àbá: Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Rántí pé, ọwọ́ tó o bá fi mú ìjákulẹ̀ ló máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ bí wọ́n ṣe máa fọwọ́ mú tiwọn náà.