ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ
Ẹ Máa Wáyè fún Ara Yín
Ọ̀pọ̀ ọkọ àti aya ni kì í ráyè bára wọn sọ̀rọ̀, kódà bí wọ́n bá jọ wà níbì kan náà. Kí ló fà á tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?
Kí nìdí táwọn tọkọtaya kan kì í fi í ráyè bára wọn sọ̀rọ̀?
Ó ti máa ń rẹ̀ wá jù
“Nígbà tí àyè bá yọ fún èmi àti ọkọ mi láti bára wa sọ̀rọ̀, ó lè ti rẹ̀ ẹ́ tàbí kó ti rẹ̀ mí. Tó bá sì ti rẹ̀ mí, ara máa ń kan mí. Ó kúkú sàn ká máa wo tẹlifíṣọ̀n.”—Anna.
Fóònù àtàwọn ìkànnì àjọlò
“Ìkànnì àjọlò àti eré ìnàjú orí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń gbani lákòókò. Èèyàn lè lo ọ̀pọ̀ wákàtí nídìí wọn, kó má sì bá ọkọ tàbí aya rẹ̀ sọ̀rọ̀ rárá. Nígbà míì, ẹ tiẹ̀ lè jọ wà nínú ilé kí kálukú sì máa tẹ fóònù ẹ̀.”—Katherine.
Èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́
“Tí ọkọ mi bá ti ibi iṣẹ́ dé, ó láwọn nǹkan tó fẹ́ràn láti máa ṣe. Ó sì yẹ kó gbádùn ara ẹ̀ lóòótọ́ torí pé ó máa ń ṣiṣẹ́ gan-an. Ṣùgbọ́n ì bá wù mí káwa méjèèjì túbọ̀ máa lo àkókò pa pọ̀.”—Jane.
Iṣẹ́
“Ẹ̀rọ ìgbàlódé ò jẹ́ kéèyàn mọ ìyàtọ̀ láàárín ibi iṣẹ́ àti inú ilé mọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń fi àkókò tó yẹ kí n fi wà pẹ̀lú ìyàwó mi fèsì ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi lorí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”—Mark.
Ohun tó o lè ṣe
Fi sọ́kàn pé ó ṣe pàtàkì kó o wáyè fún ẹnì kejì ẹ.
Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ìwà rẹ fi hàn pé o ka ìgbéyàwó rẹ sí pàtàkì ju iṣẹ́ tàbí àwọn nǹkan tó o fẹ́ràn lọ? Ṣé ìgbà tí ọwọ́ ẹ bá dilẹ̀ lo tó máa ń rí ti ẹnì kejì ẹ rò?
Ìmọ̀ràn: Ẹ má ṣe dúró dìgbà táyè bá yọ fún yín. Ṣètò àkókò tí ẹ̀yin méjèèjì nìkan á fi máa wà pa pọ̀.
“Ó máa ń dùn mọ́ mi tí ọkọ mi bá ṣètò ohun tó máa pa èmi àti ẹ̀ nìkan pọ̀. Ó máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé ó kà mí sí gan-an àti pé ó wù ú láti wà pẹ̀lú mi. Ìyẹn ń mú kí emi náà túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”—Anna.
Mọ ìgbà tó yẹ kó o pa kọ̀ǹpútà tàbí fóònù rẹ tì.
Ìlànà Bíbélì: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún.”—Oníwàásù 3:1.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí ìsọfúnni tó ń wọlé sórí fóònù rẹ kì í jẹ́ kó o ráyè pọkàn pọ̀ tí ẹnì kejì ẹ bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀?
Ìmọ̀ràn: Ẹ gbìyànjú kẹ́ ẹ jọ máa jẹun pọ̀, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́, kẹ́ ẹ sì máa fi fóònù yín sínú yàrá míì. Bẹ́ ẹ ṣe ń jẹun, ẹ lè jọ máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí kálukú yín ṣe lọ́jọ́ yẹn.
Tó bá ṣeé ṣe, ẹ jọ lọ sọ́jà tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ, nítorí pé wọ́n ní èrè púpọ̀ fún iṣẹ́ àṣekára wọn.”—Oníwàásù 4:9, àlàyé ìsàlẹ̀.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni kálukú yín máa ń dá lọ ra àwọn nǹkan tẹ́ ẹ nílò nílé?
Ìmọ̀ràn: Ẹ jọ pawọ́ pọ̀ ṣiṣẹ́, kódà kó jẹ́ ohun tí ẹnì kan lè dá ṣe.
“Dípò kẹ́ ẹ máa wo ríra oúnjẹ sílé, fífọ abọ́, kíká aṣọ àti ṣíṣiṣẹ́ nínú ọgbà bí ara iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ téèyàn ń ṣe nínú ilé, ẹ rí wọn bí ohun tó máa mú kẹ́ ẹ jọ wà pa pọ̀.”—Nina.
Ẹ máa gba tara yín rò
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.”—Fílípì 4:5.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Báwo ni ohun tó ò ń retí látọ̀dọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ ṣe lè fi hàn pé ò ń fòye báni lò?
Ìmọ̀ràn: Ẹ jọ sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ lè mọ ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan yín fẹ́. Ẹ pinnu bẹ́ ẹ ṣe máa lo àkókò yín lọ́nà táá mú kí ẹ̀yin méjèèjì máa láyọ̀.
“Ara ọkọ mì le dáadáa, ṣùgbọ́n àìlera ò jẹ́ kára tèmi fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń ní kí ọkọ mi lọ dára yá níta, tí màá sì sọ fún un pé àá máa ríra tó bá dé. Èmi á dúró sílé torí pé mo nílò ìsinmi, òun á sì lọ síta torí eré ìmárale tó nílò. Ara máa ń tu àwa méjèèjì torí pé a fún ara wa ní ohun tá a fẹ́.”—Daniela.
Ohun tẹ́ ẹ lè jọ jíròrò
Kálukú yín lè kọ́kọ́ dá ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ jọ jíròrò ìdáhùn sáwọn ìbéèrè náà.
Ṣé o lè sọ pé ìwọ àti ẹnì kejì rẹ jọ ń lo àkókò tó pọ̀ tó ní báyìí?
Kí ni ọkọ tàbí aya rẹ ti ṣe kó lè lo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú rẹ tí wàá sì fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún?
Ọ̀nà wo lo máa fẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ gbà sunwọ̀n sí i?
Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀rọ ìgbàlódé kì í jẹ́ kó o ráyè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ ń sọ?
Báwo ni ohun tí ẹ̀yin méjèèjì ń retí látọ̀dọ̀ ara yín ṣe lè fi hàn pé ẹ̀ ń fòye bára yín lò?
Àtúnṣe wo ni kálukú yín lè ṣe lọ́sẹ̀ yìí kẹ́ ẹ lè jọ lo àkókò pa pọ̀?