Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Apá Àràmàǹdà Tí Octopus

Apá Àràmàǹdà Tí Octopus

 Àwọn ẹnjiníà tó ń ṣe rọ́bọ́ọ̀tì ti ń ṣe àwọn irinṣẹ́ tó máa jẹ́ káwọn dókítà ráyè ṣiṣẹ́ abẹ láwọn ibi kọ́lọ́fín inú ara láìsí pé wọ́n ń fi abẹ la aláìsàn nílàkulà. Ohun tó sún wọn máa ṣe ọ̀kan lára àwọn irinṣẹ́ yìí ni àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe lórí apá rírọ̀ tí ẹran inú omi kan tó ń jẹ́ octopus ní.

 Rò ó wò ná: Apá mẹ́jọ ni octopus ní. Torí pé àwọn apá yìí rọ̀, ó lè nà wọ́n síwá sẹ́yìn bó ṣe wù ú, ó sì lè fi gbá nǹkan mú tàbí kó fi fún nǹkan, kódà kí nǹkan ọ̀hún wà níbi kọ́lọ́fín. Yàtọ̀ sí pé octopus lè na apá rẹ̀ síbi tó wù ú, ó tún lè le òkè apá, àárín, tàbí ìsàlẹ apá rẹ̀ tó bá gbà bẹ́ẹ̀.

 Àwọn tó ń ṣèwádìí gbà pé táwọn ẹnjiníà bá lè ṣe rọ́bọ́ọ̀tì tó ní irú ọwọ́ tó rọ̀ yìí, ó máa wúlò gan-an láti ṣiṣẹ́ abẹ láìsí pé wọ́n ń la ara aláìsàn nílàkulà. Irú irinṣẹ́ yìí máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ abẹ tó rọrùn fún àwọn aláìsàn tó jẹ́ pé iṣẹ́ abẹ tó díjú gan-an ni wọn ì bá ṣe fún wọn.

 Wo bí octopus ṣe ń fi àwọn apá rẹ̀ tó rọ̀ dárà

 Wọ́n ti ṣe rọ́bọ́ọ̀tì tó ní irú apá yìí, wọ́n sì ti ń lò ó láti ṣiṣẹ́ abẹ. Kọ̀ǹpútà ni wọ́n fi máa ń darí ẹ̀. Ohun kan wà lára apá náà tí ò ju gègé ìkọ̀wé lọ, tí wọ́n lè fi gbé àwọn ẹ̀yà ara tó wà nínú ara lọ́hùn-ún sókè tàbí kí wọ́n fi dì wọ́n mú láìpa àwọn ẹ̀yà ara náà lára, ohun míì sì wà lára apá náà tó jẹ́ pé òun ló máa ṣiṣẹ́ abẹ yẹn gangan. Dr. Tommaso Ranzani, tó wà lára àwọn tó ṣe rọ́bọ́ọ̀tì náà sọ pé, “A gbà pé ìbẹ̀rẹ̀ ni ẹ̀rọ yìí jẹ́, a ṣì máa ṣe àwọn rọ́bọ́ọ̀tì míì tó dáa jùyí lọ, tó sì tún díjú ju eléyìí lọ.”

Rọ́bọ́ọ̀tì tó bá ní apá tó rọ̀ máa wúlò gan-an láti ṣiṣẹ́ abẹ

 Kí lèrò ẹ? Ṣé apá octopus kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló dá a?