Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì

A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.

A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.

Brazil

Ìbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì

Ṣó yẹ kéèyàn sọ ṣáájú kó tó ṣẹ̀bẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ. A fẹ́ kí gbogbo ẹni tó fẹ́ ṣẹ̀bẹ̀wò sí bẹ́tẹ́lì kọ́kọ́ sọ fún wa ṣáájú kí wọ́n tó máa bọ̀, yálà àwọn tó ń bọ̀ pọ̀ tàbí wọn ò tó nǹkan ìdí sì ni pé a ò fẹ́ kí èrò pọ̀ jù, a si fẹ́ kí gbogbo ẹni tó wá gbádùn ìbẹ̀wò wọn.

Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ṣé ẹ ṣì lè ṣẹ̀bẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ó ṣeé ṣe ká má gbà yín láàyè láti rìn yíká ọgbà wa. Ìdí sì ni pé ó níye èèyàn tá a lè mù rìn yíká ọgbà wa lójúmọ́.

Ìgbà wo ló yẹ kẹ́ ẹ dé? Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dé ní ó kéré tán ọgbọ̀n (30) ìṣẹ́jú ṣáájú àsìkò tí wọ́n máa mú yín rìn yíká.

Báwo lẹ ṣe máa sọ fún wa ṣáájú? Tẹ bọ́tíìnì tá a pè ní “Ṣàdéhùn Ọjọ́ Ìbẹ̀wò.”

Ṣé ẹ lè yí ọjọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá pa dà tàbí kẹ́ ẹ sọ pé ẹ ò ní lè wá mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ bọ́tíìnì tá a pè ní “Wo Ọjọ́ Àdéhùn Tàbí Kó O Yí I Pa Dà.”

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí àyè mọ́ lọ́jọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá ńkọ́? Ẹ máa wo ìkànnì wa látìgbàdégbà. Àyè máa yọ táwọn kan bá yí ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ wá pa dà tàbí tí wọn ò fẹ́ wá mọ́.

Ìbẹ̀wò

Rodovia SP-141 - km 43

CESÁRIO LANGE-SP

18285-901

BRAZIL

+55 15-3322-9000

Àwọn Àtẹ Tó O Lè Wò Fúnra Ẹ

Àtẹ tá a pè ní The Bible​—The Book and Its Author. Àtẹ yìí gbé ògo tó yẹ fún ẹni tó jẹ́ Òǹṣèwé Bíbélì, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Bákàn náà ló jẹ́ ká rí ohun tí Bíbélì dá lé, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn tó wà ṣèbẹ̀wò á rí bí Ọlọ́run ṣe pa Bíbélì mọ́ láìka gbogbo ìsapá àwọn èèyàn láti pa á run sí. Bákan náà ni wọ́n á tún rí bí Jèhófà ṣe rí sí i pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì kò yí pa dà láìka gbogbo bí àwọn alátakò ṣe gbìyànjú láti yí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ pa dà.

Àtẹ Tó Ń Ṣàlàyé Ìtàn. Àtẹ yìí jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe bù kún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá à ti ń ṣe ní Brazil fún ohun tó lé ní ọgọ́fà (120) ọdún báyìí. Àwọn àlejò á tún rí àwọn ohun tí wọ́n ṣàwárí lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa bí iṣẹ́ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ àti bó ṣe gbòòrò bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtakò àti inúnibíni pọ̀ gan-an.

Wa Ìwé Pẹlẹbẹ Tó Ń Ṣàlàyé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa jáde