BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
“Bí Mo Ṣe Ń Hùwà Ọ̀daràn, Tí Mo Sì Lépa Owó Ṣàkóbá fún Mi”
Ọdún Tí Wọ́n Bí Mi: 1974
Orílẹ̀-Èdè Mi: Alibéníà
Irú Ẹni Tí Mo Jẹ́ Tẹ́lẹ̀: Olè, ẹlẹ́wọ̀n, mo sì máa ń ta oògùn olóró
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ
Ìlú Tiranë tó jẹ́ olú ìlú Alibéníà ni wọ́n bí mi sí, òtòṣì paraku sì ni ìdílé wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi kì í figbá kan bọ̀kan nínú, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè bójú tó wa, síbẹ̀ nǹkan ò rọrùn fún wa. Nígbà tí mo wà ní kékeré ó máa ń dùn mí gan-an tí n bá ń ronú nípa ipò tí ìdílé wa wà. Kódà nígbà yẹn, mi ò ní bàtà kankan, agbára káká la sì fi máa ń rí oúnjẹ jẹ.
Àtikékeré ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í jalè. Mo ronú pé màá lè fìyẹn ran ìdílé wa lọ́wọ́. Àmọ́ kò pẹ́ tọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá fi tẹ̀ mí. Torí náà lọ́dún 1988, bàbá mi rán mi lọ síléèwé àwọn ọmọ aláìgbọràn, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14) péré sì ni mí nígbà yẹn. Mo lo ọdún méjì níbẹ̀ mo sì kọ́ṣẹ́ wẹ́dà. Nígbà tí mo kọ́ṣẹ́ tán, mo wáṣẹ́ títí àmọ́ mi ò ríṣẹ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò níṣẹ́ lọ́wọ́ ní Alibéníà nígbà yẹn torí pé ìlú ò fara rọ. Nígbà tí gbogbo ẹ̀ sú mi, mo pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́, bí mo ṣe tún bẹ̀rẹ̀ sí í jalè nìyẹn. Àmọ́ nígbà tó yá, ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ba èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi, wọ́n sì rán wa lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta.
Lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ṣe ni mo tún pa dà sídìí ìwà ọ̀daràn. Ọrọ̀ ajé Alibéníà ti dẹnu kọlẹ̀, wàhálà sì ń ṣẹlẹ̀ nílùú. Ní gbogbo àsìkò yẹn ṣe lowó ń ya wọlé fún mi. Lọ́jọ́ kan tá a lọ jalè, wọ́n mú méjì lára àwọn ọ̀rẹ́ mi, bí mo ṣe sá kúrò nílùú nìyẹn kọ́wọ́ má bàa tẹ̀ mí kí wọ́n sì jù mí sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ. Lásìkò yẹn, mo ti ní ìyàwó, Julinda lorúkọ ẹ̀, a sì ní ọmọkùnrin kan.
Nígbà tó yá, a kó lọ sórílẹ̀-èdè England. Ohun tó wù mí ni pé kí n wáṣẹ́ míì kí èmi àti ìyàwó mi lè máa bójú tó ọmọ wa, àmọ́ ó ṣòro fún mi láti jáwọ́ nínú ìwà mi àtijọ́. Bí mo ṣe dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń ta oògùn olóró nìyẹn, owó kékeré sì kọ́ ló wà nínú iṣẹ́ yìí.
Báwo niṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí ṣe rí lára Julinda ìyàwó mi? Ẹ jẹ́ kó fẹnu ara ẹ̀ sọ fún yín: “Àtikékeré ni nǹkan ò ti rọrùn fún wa ní Alibéníà, torí náà bí mo ṣe máa lówó lọ́wọ́ ló gbà mí lọ́kàn. Mo ṣe tán láti ṣe ohunkóhun kí n lè lówó lọ́wọ́. Mo ronú pé tá a bá lówó lọ́wọ́, ayé wa máa dùn. Torí náà, mi ò rí ohun tó burú nínú bí ọkọ mi ṣe ń parọ́, tó ń jalè, tó sì ń ta oògùn olóró, tèmi ni pé kó ṣáà ti mówó wálé.”
Àmọ́ lọ́dún 2002, àwọn agbófinró ká oògùn olóró tó pọ̀ gan-an mọ́ mi lọ́wọ́, wọ́n sì jù mí sẹ́wọ̀n. Bí ìgbésí ayé wa ṣe dojú rú nìyẹn.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ
Láìmọ̀, Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í tún ayé mi ṣe díẹ̀díẹ̀. Lọ́dún 2000, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Julinda lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èmi ò gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí mo rò pé mi ò lè gbádùn ẹ̀. Àmọ́ Julinda fẹ́ràn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní tiẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn òbí mi kì í fi ọ̀rọ̀ ìjọsìn ṣeré, ìyẹn sì jẹ́ kí n gbádùn kíka Bíbélì. Ó máa ń wù mí láti mọ ohun tó wà nínú Bíbélì, torí náà inú mi dùn nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Mo mọyì àwọn ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì, ìyẹn sì mú kí n ṣe àwọn àtúnṣe kan ní ìgbésí ayé mi. Àmọ́ ní gbogbo àsìkò yẹn, mo ṣì gbà pé téèyàn bá lówó lọ́wọ́ nìkan ló máa láyọ̀. Ìgbà tọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ ọkọ mi ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í tún èrò mi ṣe. Mo wá rí i pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́ owó. Ojoojúmọ́ ayé wa la fi ń lépa owó, síbẹ̀ a ò láyọ̀. Mo wá rí i pé tí n bá fẹ́ láyọ̀ tòótọ́, mo gbọ́dọ̀ máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ délẹ̀délẹ̀.”
Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n lọ́dún 2004, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú àtipadà sídìí iṣẹ́ títa oògùn olóró. Àmọ́ ìyàwó mi ò fẹ́ kí n ṣiṣẹ́ yẹn mọ́, ohun tó sọ ló sì mú kí n ronú jinlẹ̀. Ó ní: “Mi ò fẹ́ owó yín mọ́. Mo fẹ́ máa rí yín lójoojúmọ́ ká lè jọ máa tọ́jú àwọn ọmọ wa.” Ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ mí lára, torí pé òótọ́ ọ̀rọ̀ pọ́ńbélé ló sọ. Mo ti fi ìdílé mi sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Yàtọ̀ síyẹn, mo tún ronú nípa gbogbo ìyà tí mo ti jẹ bí mo ṣe ń wá owó lójú méjèèjì. Torí náà, mo pinnu láti yí ìwà mi pa dà, mo sì fi àwọn ọ̀rẹ́ burúkú tí mò ń bá rìn sílẹ̀.
Ohun tí mo rí lọ́jọ́ tí mo tẹ̀ lé ìyàwó mi àtàwọn ọmọ mi méjèèjì lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló yí mi lọ́kàn pa dà pátápátá. Ara àwọn tí mo rí níbẹ̀ yọ̀ mọ́ọ̀yàn, ó sì hàn lójú wọn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi. Bí èmi náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.
Mo máa ń ronú pé téèyàn ò bá lówó rẹpẹtẹ, kò lè láyọ̀
Bíbélì jẹ́ kí n rí i pé “ìfẹ́ owó ni ọ̀kan lára ohun tó ń fa onírúurú jàǹbá, àwọn kan tí wọ́n sì ní irú ìfẹ́ yìí . . . ti fi ìrora tó pọ̀ gún gbogbo ara wọn.” (1 Tímótì 6:9, 10) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti jẹ́ kí n rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lẹsẹ Bíbélì yẹn sọ! Mo kábàámọ̀ àwọn nǹkan tí mo ti ṣe sẹ́yìn, ó sì dùn mí pé mo kó ẹ̀dùn ọkàn bá ìdílé mi. (Gálátíà 6:7) Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, mo bẹ̀rẹ̀ sí í yíwà mi pa dà. Dípò tí màá fi máa ronú nípa ara mi nìkan, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn míì, ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ ráyè fún ìdílé mi.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ
Mo ti rí i pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.” (Hébérù 13:5) Ọkàn mi ti wá balẹ̀, mo sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Ní báyìí, ayọ̀ tí mo ní kọjá àfẹnusọ, èmi àti ìyàwó mi ti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa, ìdílé mi sì ń láyọ̀.
Tẹ́lẹ̀, mo ronú pé téèyàn ò bá lówó rẹpẹtẹ, kò lè láyọ̀. Àmọ́ ní báyìí, mo ti rí àkóbá tí ìwà ọ̀daràn àti bí mo ṣe wá owó lójú méjèèjì ṣe fún mi. Lóòótọ́ a ò lówó rẹpẹtẹ, síbẹ̀ inú wa ń dùn torí pé a ti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn sì lohun tó ṣe pàtàkì jù láyé yìí. Ní báyìí, èmi àti ìdílé mi jọ ń sin Jèhófà, kò sì sóhun tó lè fún wa láyọ̀ tóyẹn.