Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Ohun Tí Ò Yé Mi Pọ̀ Ju Èyí Tó Yé Mi Lọ”

“Ohun Tí Ò Yé Mi Pọ̀ Ju Èyí Tó Yé Mi Lọ”
  • Ọdún Tí Wọ́n Bí Mi: 1976

  • Orílẹ̀-Èdè Mi: Honduras

  • Irú Ẹni Tí Mo Jẹ́ Tẹ́lẹ̀: Pásítọ̀

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

 Ìlú La Ceiba lórílẹ̀-èdè Honduras ni wọ́n bí mi sí, èmi ni àbíkẹ́yìn nínú ọmọ márùn-ún táwọn òbí mi bí, èmi nìkan sì lọkùnrin. Yàtọ̀ síyẹn, èmi nìkan ni adití nínú ìdílé wa. Àdúgbò tó léwu là ń gbé, a sì tálákà gan-an. Ojú pọ́n wa gan-an nígbà tí bàbá mi jábọ́ látorí òrùlé, tí wọ́n sì kú, bẹ́ẹ̀ sì rèé, nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́rin ni mí nígbà yẹn.

 Ìyá mi forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n lè tọ́jú èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í rówó raṣọ fún mi. Tójò bá ń rọ̀, òtútù máa ń mú mi gan-an, torí mi ò láwọn aṣọ tí mo lè fi gbòtútù.

 Bí mo ṣe ń dàgbà, mo kọ́ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Honduras (LESHO), èdè yìí ló jẹ́ kí n lè máa bá àwọn míì tó jẹ́ adití sọ̀rọ̀. Torí pé ìyá mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi ò gbọ́ èdè adití, ṣe ni wọ́n máa ń fọwọ́ ṣàpèjúwe ohun tí wọ́n bá fẹ́ bá mi sọ. Ìyá mi fẹ́ràn mi gan-an, kò sì fẹ́ kí ohunkóhun ṣe mí. Ìwọ̀nba èdè adití tí wọ́n mọ̀ ni wọ́n fi máa ń kìlọ̀ fún mi pé kí n yẹra fáwọn àṣà burúkú, bíi mímu sìgá àti lílo oògùn olóró. Inú mi dùn gan-an ni pé ohun tí ìyá mi ṣe yìí ni ò jẹ́ kí n lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà burúkú yẹn bí mo ṣe ń dàgbà.

 Nígbà tí mo wà ní kékeré, ìyá mi máa ń mú mi lọ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, àmọ́ ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ kì í yé mi rárá, torí kò sẹ́ni tó máa ń bá mi túmọ̀ ẹ̀ sédè adití. Gbogbo ẹ̀ wá tojú sú mi, torí náà nígbà tí mo pọ́mọ ọdún mẹ́wàá mi ò lọ ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Síbẹ̀, ó wù mí kí n túbọ̀ mọ Ọlọ́run.

 Lọ́dún 1999, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlélógún (23), mo pàdé obìnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ṣọ́ọ̀ṣì ajíhìnrere ló ń lọ. Ó kọ́ mi láwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì, ó sì tún kọ́ mi ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà (ASL). Mo gbádùn àwọn ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì débi tí mo fi pinnu pé màá di pásítọ̀. Torí náà, mo kó lọ sílùú Puerto Rico, mo sì lọ sí ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ṣètò fáwọn adití tó fẹ́ mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Kristẹni. Nígbà tí mo pa dà sílùú La Ceiba lọ́dún 2002, mo dá ṣọ́ọ̀ṣì kan sílẹ̀ fáwọn adití, díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi sì dara pọ̀ mọ́ mi. Nígbà tó yá, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi yẹn tó ń jẹ́ Patricia di ìyàwó mi.

 Torí pé èmi ni pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì náà, mo máa ń fi èdè adití LESHO ṣe ìwàásù, màá fi àwọn àwòrán ìtàn Bíbélì han àwọn ọmọ ìjọ, màá sì ṣàṣefihàn àwọn ìtàn náà kó lè yé àwọn tó jẹ́ adití dáadáa. Mo tún máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn adití láwọn ìlú tó wà nítòsí wa, kí n lè fún wọn níṣìírí, kí n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Mo tiẹ̀ tún ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì lọ sórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Zambia. Àmọ́ ká sòótọ́, mi ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ọ̀pọ̀ nǹkan nínú Bíbélì. Àwọn nǹkan tí mo ti gbọ́ àti bí àwọn àwòrán tí mo rí ṣe yé mi sí ni mo fi ń kọ́ àwọn èèyàn. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ohun tí ò yé mi pọ̀ ju èyí tó yé mi lọ.

 Lọ́jọ́ kan, àwọn kan nínú ìjọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í tan irọ́ kálẹ̀ nípa mi. Wọ́n ní mo máa ń mutí para, mo sì máa ń kóbìnrin. Ọ̀rọ̀ yẹn bà mí nínú jẹ́ gan-an, ó sì tún bí mi nínú. Kò pẹ́ sígbà yẹn lèmi àti Patricia kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì yẹn.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

 Ó ti pẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń wá sọ́dọ̀ èmi àtìyàwó mi, àmọ́ a kì í fún wọn láyè. Ní báyìí tá ò lọ ṣọ́ọ̀ṣì wa mọ́, ìyàwó mi gbà káwọn tọkọtaya kan máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn Thomas àti Liccy. Ó yà mí lẹ́nu pé wọ́n gbọ́ èdè adití, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe adití. Bí mo ṣe gbà pé kí wọ́n máa kémi náà lẹ́kọ̀ọ́ nìyẹn o.

 Fídíò tó wà lédè àwọn adití (ASL) la máa ń fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́, a sì gbádùn ṣíṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù. Àmọ́ nígbà táwọn ọ̀rẹ́ wa kan sọ fún wa pé èèyàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé, a dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Thomas jẹ́ kí n rí ẹ̀rí pé kì í ṣèèyàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé, mi ò gbà á gbọ́.

 Lẹ́yìn oṣù mélòó kan, ìyàwó mi ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára, ó wá gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún pa dà wá. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni aládùúgbò wa kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ ìyàwó mi, ó sì lóun máa sọ fún Liccy pé kó wá sọ́dọ̀ ẹ̀. Bó ṣe di pé Liccy wá nìyẹn o. Kódà, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló máa ń wá sọ́dọ̀ Patricia kó lè fún un níṣìírí, kó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí n má parọ́, ọ̀rẹ́ gidi ni Liccy. Síbẹ̀ náà, mò ń ṣiyèméjì nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

 Lọ́dún 2012, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe àkànṣe ìwàásù kan, wọ́n pín fídíò Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? lédè àwọn adití. Liccy gba ẹ̀dà kan, ó sì mú un wá sílé. Nígbà tí mo wo fídíò náà, ó yà mí lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí mo fi ń kọ́ àwọn èèyàn ò sí nínú Bíbélì, irú bí ọ̀run àpáàdì àti àìleèkú ọkàn.

 Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, mo lọ rí Thomas ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ká lè jọ sọ̀rọ̀. Mo sọ fún un pé mo fẹ́ máa kọ́ àwọn adití ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì, àmọ́ kì í ṣe pé mo fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí mo ní lọ́kàn ni pé mo fẹ́ dá ṣọ́ọ̀ṣì tuntun sílẹ̀ tó máa wà fáwọn adití nìkan. Thomas gbóríyìn fún mi torí ìtara tí mo ní yìí, àmọ́ ó fi ohun tó wà ní Éfésù 4:5 hàn mí, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan.

 Thomas tún fún mi ní fídíò Jehovah’s Witnesses​—⁠Faith in Action, Part 1: Out of Darkness lédè adití. Fídíò yìí jẹ́ kí n rí bí àwọn ọkùnrin kan ṣe kóra jọ, tí wọ́n sì fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Bíbélì kí wọ́n lè lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́. Bí mo ṣe ń wo fídíò náà, mo rí i pé ọ̀rọ̀ wa jọra. Ó ṣe tán, òtítọ́ lèmi náà ń wá kiri. Fídíò yìí jẹ́ kí n rí i dájú pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni, torí pé inú Bíbélì ni wọ́n ti mú gbogbo ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Bí mo tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, nígbà tó di ọdún 2014, èmi àti Patricia ṣèrìbọmi, a sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀWỌN ÌBÙKÚN TÍ MO RÍ

 Mo fẹ́ràn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mo sì mọyì wọn gan-an torí pé ìwà àti ìṣe wọn mọ́, Ọlọ́run ni wọ́n sì fìyẹn jọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sọ̀rọ̀ rírùn, inú kan ni wọ́n fi ń bára wọn lò, ìwà tó dáa ni wọ́n sì ń hù sáwọn míì. Èèyàn àlàáfíà ni wọ́n, wọ́n sì máa ń fún ara wọn níṣìírí. Ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì kan náà ni gbogbo wọn fi ń kọ́ni, láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà tàbí èdè tí wọ́n ń sọ sí.

 Mo gbádùn àwọn ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì gan-an. Bí àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni Ọlọ́run Olódùmarè, òun ni Ọba Aláṣẹ láyé àti lọ́run. Gbogbo èèyàn ló nífẹ̀ẹ́, àti adití o, àtẹni tí kì í ṣe adití. Kí ni kí n sọ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí mi? Ó kọjá bẹ́ẹ̀. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ayé yìí máa di Párádísè, àá máa gbénú ẹ̀ títí láé, àá sì ní ìlera tó pé. Kí n sòótọ́, ṣe ló ń ṣe mí bíi pé ká ti wà níbẹ̀!

 Èmi àti Patricia ìyàwó mi fẹ́ràn àtimáa kọ́ àwọn adití lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà, à ń kọ́ àwọn kan tó jẹ́ ará ṣọ́ọ̀ṣì wa tẹ́lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Ní báyìí, ohun tí mo fi ń kọ́ àwọn èèyàn yé mi dáadáa, kò dà bí ìgbà tí mo ṣì jẹ́ pásítọ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mi, torí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.