Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Ojú Kì í Tì Mí Mọ́”

“Ojú Kì í Tì Mí Mọ́”
  • Ọdún Tí Wọ́n Bí Mi: 1963

  • Orílẹ̀-èdè Mi: Mẹ́síkò

  • Irú Ẹni Tí Mo Jẹ́ Tẹ́lẹ̀: Ọmọ asùnta; mo máa ń wo ara mi bí ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

 Ìlú Ciudad Obregón ní àríwá orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni wọ́n bí mi sí, èmi ni ìkarùn-ún nínú ọmọ mẹ́sàn-án táwọn òbí mi bí. Ìgbèríko ìlú wa là ń gbé, bàbá mi sì dá oko kékeré kan síbẹ̀. A gbádùn ibẹ̀ gan-an, a sì mọwọ́ ara wa gan-an nínú ìdílé wa. Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún márùn-ún, ìjì líle kan jà lágbègbè wa, ó sì ba oko wa jẹ́ pátápátá. Bó ṣe di pé a kó lọ sílùú míì nìyẹn.

 Bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í rí towó ṣe, àmọ́ kò pẹ́ ni wọ́n di ọ̀mùtí. Bó ṣe di pé àwọn àti màámi ò gbọ́ra wọn yé mọ́ nìyẹn, èyí sì ṣàkóbá fáwa ọmọ náà. Èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í mu àwọn sìgá tá à ń jí kó lọ́dọ̀ bàbá wa. Mi ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́fà lọ nígbà tí mo kọ́kọ́ mutí yó láyé mi. Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn òbí wa pínyà, bí mo ṣe kúkú bẹ̀rẹ̀ ìwàkiwà lójú páálí nìyẹn.

 Nígbà tí màámi kó kúrò lọ́dọ̀ bàbá wa, wọ́n kó lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin míì, wọ́n sì kó àwa ọmọ dání. Ọkùnrin yẹn kì í fún wọn lówó, owó tó sì ń wọlé fún màámi ò tó gbọ́ bùkátà wa. Lèmi àtàwọn ọmọ ìyá mi yòókù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tá a bá lè ṣe, síbẹ̀ náà awọ ò kájú ìlù. Mo rántí pé mo máa ń báwọn èèyàn dán bàtà, mo sì máa ń ta búrẹ́dì, ìwé ìròyìn, ṣingọ́ọ̀mù àtàwọn nǹkan míì. Mo tún máa ń káàkiri ìgboro, màá lọ tú inú pàǹtí táwọn olówó bá dà nù bóyá mo lè rí oúnjẹ ṣà jẹ níbẹ̀.

 Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, ọkùnrin kan ní kí n wá máa bá òun ṣiṣẹ́ níbi ààtàn kan tí wọ́n ń da ìdọ̀tí sí, mo sì gbà láti bá a ṣiṣẹ́. Torí náà, mo fi iléèwé sílẹ̀, mo sì kó kúrò nílé. Owó táṣẹ́rẹ́ kan ni ọkùnrin náà ń san fún mi lójúmọ́, ó sì máa ń fún mi lóúnjẹ tí wọ́n bá rí nínú ìdọ̀tí táwọn èèyàn dà nù. Àwọn pàǹtí kan tí mo kó jọ lórí ààtàn ni mo fi kọ́ ahéré kan, ibẹ̀ sì ni mò ń gbé. Ọ̀rọ̀ rírùn làwọn tó yí mi ká máa ń sọ kùrà, oníṣekúṣe sì ni wọ́n. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni oògùn olóró ti di bárakú fún, wọn ò sì lè ṣe kí wọ́n má mutí. Kí n sòótọ́, ayé sú mi, alaalẹ́ ni mo máa ń sunkún, ẹ̀rù sì máa ń bà mí gan-an. Ojú máa ń tì mí torí pé mo tòṣì àti pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ kàwé. Nǹkan bí ọdún mẹ́ta ni mo fi gbé níbi ààtàn yẹn, nígbà tó sì yá, mo kó lọ sí ìlú míì ní Mẹ́síkò. Níbẹ̀, onírúurú iṣẹ́ oko ni mo ṣe, bíi kí n bá wọn já òdòdó àti òwú, kí n kó ìrèké jọ tàbí kí n máa wa ọ̀dùnkún.

Irú ààtàn yìí ni mo gbé fún ọdún mẹ́ta

 Lẹ́yìn ọdún mẹ́rin, mo pa dà sílùú Ciudad Obregón. Ẹ̀gbọ́n dádì mi obìnrin, tó ń ṣiṣẹ́ awo, ní kí n wá máa gbé lọ́dọ̀ àwọn. Oríṣiríṣi àlákálàá ni mo máa ń lá níbẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá mi débi pé mo ronú pé kí n para mi. Lálẹ́ ọjọ́ kan, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Olúwa, tó bá jẹ́ lóòótọ́ lo wà, mo fẹ́ mọ̀ ẹ́, mo sì fẹ́ sìn ọ́ títí ayé. Tí ẹ̀sìn kan bá wà tó jẹ́ ẹ̀sìn tòótọ́, jọ̀ọ́, mo fẹ́ mọ̀ ọ́n.”

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

 Gbogbo ìgbà ló máa ń wù mí láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Kódà nígbà tí mo wà lọ́mọdé, àìmọye ṣọ́ọ̀ṣì ni mo lọ, àmọ́ gbogbo wọn ló já mi kulẹ̀. Kò sí ìkankan nínú wọn tó fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ Bíbélì, wọn ò sì kọ́ mi ní nǹkan kan nípa Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ owó làwọn kan máa ń ránnu mọ́ ṣáá, oníṣekúṣe paraku sì làwọn míì.

 Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún (19), ọkọ ẹ̀gbọ́n mi kan sọ fún mi pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ òun, wọ́n sì ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa lílo ère fún ìjọsìn. Ó ka Ẹ́kísódù 20:​4, 5 fún mi. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ère fún ara wa. Ẹsẹ karùn-ún sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n tàn ọ́ láti sìn wọ́n, torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo.” Ọkọ ẹ̀gbọ́n mi wá bi mí pé, “Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run ń fi ère ṣiṣẹ́ ìyanu tàbí tó fẹ́ ká máa fi wọ́n jọ́sìn, kí ló dé tó fi dẹ́bi fún lílo ère?” Èmi náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í ro ọ̀rọ̀ yẹn. Nígbà tó yá, a jíròrò ọ̀pọ̀ nǹkan látinú Bíbélì. Mo gbádùn àwọn ìjíròrò yẹn gan-an débi pé mi ò kì í mọ̀ pé ọjọ́ ti lọ.

 Nígbà tó yá, ó mú mi lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí mo rí àtohun tí mo gbọ́ níbẹ̀ wú mi lórí gan-an. Kódà, àwọn ọ̀dọ́ ṣiṣẹ́ nípàdé yẹn, wọ́n ń sọ̀rọ̀ látorí pèpéle, ọ̀rọ̀ sì dá ṣáká lẹ́nu wọn! Mo wá ń sọ lọ́kàn mi pé, ‘Ìdálẹ́kọ̀ọ́ táwọn aráabí ń gbà mà dáa o!’ Pẹ̀lú bí irun orí mi ṣe gùn, tí mo sì rí wúruwùru, ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀. Kódà, lẹ́yìn tí ìpàdé náà parí, ìdílé kan ní kí n wá jẹun alẹ́ lọ́dọ̀ àwọn!

 Ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ mi ti jẹ́ kí n rí i pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ wa sì jẹ ẹ́ lógún. Láìka bóyá olówó ni wá tàbí tálákà, irú ẹni tá a jẹ́ láwùjọ, dúdú ni wá àbí funfun, bóyá a kàwé àbí a ò kàwé, Jèhófà kà wá sí. Èyí jẹ́ kí n gbà lóòótọ́ pé Ọlọ́run kì í ṣojúsàájú. (Ìṣe 10:​34, 35) Inú mi dùn gan-an pé mo ti wá mọ Ọlọ́run, mo sì sún mọ́ ọn. Ìbànújẹ́ mi dayọ̀, ayé mi sì túbọ̀ ń nítumọ̀.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

 Ìgbé ayé ọ̀tun ni mò ń gbé báyìí. Mo jáwọ́ nínú sìgá mímu, mi ò mu ọtí nímukúmu mọ́, mi ò sì sọ̀rọ̀ rírùn mọ́. Ará máa ń kan mí gan-an tẹ́lẹ̀ torí bí nǹkan ṣe rí fún mi láti kékeré, àmọ́ ní báyìí ọkàn mi ti fúyẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, mi ò kì í lá àlákálàá mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń wo ara mi bí ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan tẹ́lẹ̀, torí àwọn nǹkan tójú mi ti rí ní kékeré àti bí mi ò ṣe fi bẹ́ẹ̀ kàwé. Àmọ́ ní báyìí, mi ò ní irú èrò bẹ́ẹ̀ mọ́.

 Mo ti ní ìyàwó gidi tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó sì jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà mi. Ní báyìí, mo jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò nínú ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì máa ń bẹ àwọn ìjọ wò kí n lè fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi lókun. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tó tún ayé mi ṣe àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jíire tí Ọlọ́run ń fún wa, ojú kì í tì mí mọ́.

Ó máa ń wu èmi àtìyàwó mi láti ran àwọn míì lọ́wọ́, torí àwọn kan ló ran èmi náà lọ́wọ́