BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
“Ó Ṣe Mí Bíi Pé Gbogbo Ohun Tí Mo Fẹ́ Lọwọ́ Mi Ti Tẹ̀”
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1962
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: Kánádà
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Oníṣekúṣe
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ
Ìlú Montreal ni wọ́n bí mi sí, ìlú yìí ló tóbi jù ní ìpínlẹ̀ Quebec lórílẹ̀-èdè Kánádà. Àwọn òbí mi tọ́ èmi, ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi méjèèjì dàgbà ní àdúgbò Rosemont, àdúgbò tó dùn ún gbé ni. Àwọn òbí mi nífẹ̀ẹ́ wa, a jọ rọra ń gbé ayé wa jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, a sì wà lálàáfíà.
Láti kékeré ló ti wù mí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo rántí ìgbà tí mò ń ka ìtàn ìgbésí ayé Jésù nínú Májẹ̀mú Tuntun lọ́mọ ọdún méjìlá [12], mo gbádùn ẹ̀ gan-an. Bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, tó sì káàánú wọn wú mi lórí gan-an, ó sì wù mí kí n fìwà jọ ọ́. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé bí mo ṣe ń dàgbà ni èrò dáadáa tí mo ní yìí bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tí kò yẹ kẹ́gbẹ́.
Bàbá mi mọ bí wọ́n ṣe ń fi saxophone kọrin, wọ́n sì pa dà fún mi ní saxophone tí wọ́n fi ń kọrin yẹn. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ ni mo jogún lára wọn, wọ́n tún jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ orin gan-an débi pé orin kíkọ wá gbà mí lọ́kàn. Mo gbádùn orin kíkọ gan-an débi pé kò pẹ́ tí mo fi mọ guitar ta. Nígbà tó yá, èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi mélòó kan bẹ̀rẹ̀ sí í jọ kọrin, a sì lọ kọrin láwọn àríyá kan. Bó ṣe di pé àwọn gbajúgbajà kan tó ń ṣe orin jáde kíyè sí mi nìyẹn, tí wọ́n sì wá bá mi pé àwọn máa bá mi gbé orin mi lárugẹ. Mo gbà láti bá iléeṣẹ́ ńlá kan tó ń ṣe orin jáde ṣiṣẹ́. Orin mi wá di ìlúmọ̀ọ́ká, kódà léraléra ni wọ́n máa ń kọ ọ́ lórí rédíò ní Quebec.
Ó ṣe mí bíi pé gbogbo ohun tí mo fẹ́ lọwọ́ mi ti tẹ̀. Ọ̀dọ́ ni mí, mo tún gbajúmọ̀, ohun tí mo fẹ́ràn ni mo fi ń ṣiṣẹ́ ṣe, mo sì ń rówó gan-an nídìí ẹ̀. Lójúmọmọ, ibi tí wọ́n ti ń ṣeré ìmárale ni mo máa ń wà, àwọn èèyàn máa ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, mo máa ń buwọ́ lu ìwé táwọn èèyàn bá mú wá bá mi, iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n sì máa ń gbé mi sáyé. Tó bá wá dalẹ́, màá lọ kọrin, màá sì ṣàríyá. Nígbà tí mo ṣì kéré, ṣe ni mo máa ń mutí kí n lè máa mórí àwọn tó gba tèmi yá, àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró nígbà tó yá. Ṣe ni mo kàn ń ṣe bó ṣe wù mí, mo sì ya oníṣekúṣe.
Ó máa ń wu àwọn kan kí wọ́n dà bí mi torí mo jọ ẹni tó ń láyọ̀ lójú wọn. Àmọ́ nínú lọ́hùn-ún, mi ò láyọ̀ rárá. Ó sábà máa ń ṣe mí bẹ́ẹ̀ tí mo bá dá wà. Ìbànújẹ́ dorí mi kodò, ọkàn mi ò sì balẹ̀. Ẹ̀dùn ọkàn gbáà ló jẹ́ pé ìgbà tí ọwọ́ mi mókè tán ni méjì nínú àwọn tó ń bá mi ṣe orin jáde kó àrùn AIDS, tí wọ́n sì gbabẹ̀ kú. Ẹ̀rù bà mí gan-an! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo nífẹ̀ẹ́ orin, ìgbésí ayé táwọn olórin ń gbé máa ń kó mi nírìíra.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ
Mo rí towó ṣe lóòótọ́, mo sì gbajúmọ̀, àmọ́ mo mọ̀ pé kì í ṣe bó ṣe yẹ kí nǹkan rí láyé ló rí yìí. Kí ló dé tí ìwà ìrẹ́jẹ pọ̀ tó báyìí? Ó ń yà mí lẹ́nu bí Ọlọ́run ò ṣe wá nǹkan ṣe sí i. Kódà, mo sábà máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí n rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mi. Mo lọ gbafẹ́ nígbà kan, mo wá ní kí n sinmi díẹ̀, ibi tí mo ti ń sinmi ni mo tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú nǹkan tí mò ń kà ni ò yé mi, ibi tí mo parí èrò sí ni pé òpin ayé ti sún mọ́lé.
Nígbà tí mò ń ka Bíbélì, mo ka ibì kan tí Bíbélì ti sọ pé ìgbà kan wà tí Jésù gbààwẹ̀ ogójì [40] ọjọ́ nínú aṣálẹ̀. (Mátíù 4:1, 2) Mo wá rò ó lọ́kàn ara mi pé témi náà bá ṣe bẹ́ẹ̀, bóyá Ọlọ́run á fi ara rẹ̀ hàn mí. Ni mo bá mú ọjọ́ tí mo máa bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ ọ̀hún. Nígbà tó ku ọ̀sẹ̀ méjì kí n bẹ̀rẹ̀, Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan ilẹ̀kùn mi, mo sì ní kí wọ́n wọlé, àfi bíi pé mo ti ń retí wọn tẹ́lẹ̀. Mo wo ojú ọ̀kan nínú wọn tó ń jẹ́ Jacques, mo sì bi í pé, “Báwo la ṣe máa mọ̀ bóyá a ti ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé yìí?” Ló bá ṣí Bíbélì ẹ̀, ó sì ka 2 Tímótì 3:1-5. Mo tún da ọ̀pọ̀ ìbéèrè míì bo àwọn méjèèjì, ìdáhùn tí wọ́n fún mi bọ́gbọ́n mu, ó tẹ́ mi lọ́rùn, inú Ìwé Mímọ́ ni wọ́n sì ti mú gbogbo ohun tí wọ́n sọ. Ìyẹn wú mi lórí gan-an. Lẹ́yìn ẹ̀ẹ̀mélòó kan tí wọ́n wá sílé mi, mo rí i pé mi ò nílò ààwẹ̀ kankan.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Nígbà tó yá, mo gé irún gígùn tó wà lórí mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo ìpàdé tí wọ́n ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn èèyàn máa ń fi ọ̀yàyà kí mi láwọn ìpàdé yẹn, ó sì jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé mo ti wá rí òtítọ́.
Òtítọ́ kan ni pé tí mo bá fẹ́ fi ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì sílò, àfi kí n yí àwọn nǹkan pàtàkì kan pa dà láyé mi. Àkọ́kọ́, mo gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú oògùn olóró tí mò ń lò, kí n sì jáwọ́ nínú ìṣekúṣe. Mo tún gbọ́dọ̀ yí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tí mo ní pa dà, kí n sì túbọ̀ máa gba tàwọn míì rò. Ohun míì tún ni pé èmi ni mò ń dá tọ́ àwọn ọmọ mi méjèèjì, torí náà, ó yẹ kí n kọ́ bí màá ṣe máa bójú tó wọn, kí n sì máa fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wọn. Bí mo ṣe pa iṣẹ́ orin tí mò ń ṣe tì nìyẹn, tí mo sì wá iṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú kan ṣe níléeṣẹ́ kan.
Kò rọrùn láti ṣe àwọn nǹkan tí mo sọ yìí. Bí mo ṣe ń gbìyànjú láti jáwọ́ lílo oògùn olóró, ara mi kì í lélẹ̀ tí mi ò bá ti lò ó, èyí sì mú kí n tún pa dà sídìí ẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mélòó kan. (Róòmù 7:19, 21-24) Èyí tó le gan-an fún mi láti ṣe ni kí n jáwọ́ nínú ìṣekúṣe. Bákan náà, iṣẹ́ tuntun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà máa ń tán mi lókun, owó táṣẹ́rẹ́ tí mo sì ń rí níbẹ̀ ò múnú mi dùn. Nígbà tí mo ṣì ń kọrin, wákàtí méjì péré ni màá fi pa owó tí mò ń fi oṣù mẹ́ta ṣiṣẹ́ fún báyìí.
Àdúrà ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fara da àwọn àtúnṣe tó le tí mo ṣe yẹn. Bí mo tún ṣe máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ ràn mí lọ́wọ́. Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan wà tó gbé mi ró gan-an. Ọ̀kan ni 2 Kọ́ríńtì 7:1, tó rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “wẹ ara [wọn] mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì tó tún fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé ó ṣeé ṣe fún mi láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tí mò ń hù ni Fílípì 4:13, tó sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” Jèhófà Ọlọ́run gbọ́ àdúrà mi, ó pa dà jẹ kí òtítọ́ Bíbélì yé mi, ó sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa fi ṣèwà hù. Èyí ló sún mi tí mo fi ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún un. (1 Pétérù 4:1, 2) Ọdún 1997 ni mo ṣèrìbọmi, tí mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ
Ó dá mi lójú pé ká ní ìgbésí ayé tí mò ń gbé tẹ́lẹ̀ náà ni mo ṣì ń gbé, mi ò bá ti kú báyìí. Àmọ́ ayé mi ti nítumọ̀ báyìí, mo sì ń láyọ̀! Ìbùkún ńlá ni Elvie, ìyàwó mi àtàtà jẹ́ fún mi. Òjíṣẹ́ alákòókò kíkún làwa méjèèjì, a jọ ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a sì ń gbádùn ẹ̀. Èyí ń múnú mi dùn gan-an, ó sì ń fi mí lọ́kàn balẹ̀. Mo dúpẹ́, mo tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fà mí sọ́dọ̀ ara rẹ̀.—Jòhánù 6:44.