Àkúnya Omi Mú Kí Wọ́n Gbọ́ Ìwàásù
Lọ́dún 2017, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìlá fi ọkọ̀ ojú omi rìnrìn àjò láti Etíkun Mosquito (Miskito) lórílẹ̀-èdè Nicaragua. Orúkọ ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ ni Sturi Yamni. Ọ̀kan lára àwọn tó rìnrìn àjò náà tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Stephen sọ pé: “A rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mélòó kan tó ń gbé ní àdádó ká lè fún wọn níṣìírí, ká sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù torí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn tóbi gan-an.”
Odò Pearl Lagoon làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìlá (12) tó rìnrìn àjò náà ti gbéra, ìrìn àjò ọgọ́rùn-ún méjì (200) kìlómítà ni wọ́n sì rìn kí wọ́n tó dé agbègbè Río Grande de Matagalpa. Ohun tí orúkọ ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ túmọ̀ sí lédè Miskito ni “Ìròyìn Ayọ̀.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn ò mọ̀ pé orúkọ tí wọ́n fún ọkọ̀ ojú omi wọn yìí máa ní ìtumọ̀ àrà ọ̀tọ̀ sí àwọn tó ń gbé lágbègbè yẹn. Yàtọ̀ sí àkókò tí wọ́n fi sùn mọ́jú níbi tí ilẹ̀ ṣú wọn sí, nǹkan bíi wákàtí méjìlá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí fi rìnrìn àjò débi tí wọ́n ń lọ, ìyẹn ìlú La Cruz de Río Grande. Tayọ̀tayọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́fà tí wọ́n bá níbẹ̀ fi kí àwọn ará wọn yìí káàbọ̀.
Àmọ́ àjálù kan ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ìjì líle kan bẹ̀rẹ̀ sí í jà, ó sì mú kí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá rọ̀ débi pé odò Río Grande de Matagalpa kún àkúnya. Kò ju wákàtí mélòó kan lọ tí odò náà fi kún àkúnya, kódà ṣe ló ń pọ̀ sí i jálẹ̀ ọjọ́ méjì tó tẹ̀ lé e. Omi ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ọ̀pọ̀ ilé nílùú La Cruz. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá sílùú yẹn ran àwọn ará ìlú náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè kó kúrò nílé wọn. Wọ́n mú ọ̀pọ̀ nínú wọn lọ sí ilé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ ilé alájà méjì, ọjọ́ méjì ni wọ́n sì fi sùn níbẹ̀.
Nígbà tó di alẹ́ ọjọ́ kẹta, baálẹ̀ ìlú La Cruz lọ sọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá sílùú náà, ó ní kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. Ó fẹ́ kí wọ́n bá òun fi ọkọ̀ ojú omi wọn gbé àwọn ọkùnrin mélòó kan sọdá odò lọ sí àwọn agbègbè míì tí àjálù náà ti wáyé, kí wọ́n lè lọ ṣèrànwọ́, torí pé ọkọ̀ ojú omi wọn nìkan ló lágbára láti rìnrìn àjò yẹn. Tayọ̀tayọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí yẹn gbà láti ran baálẹ̀ náà lọ́wọ́.
Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, mẹ́ta nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà gbéra pẹ̀lú àwọn ọkùnrin yẹn. Stephen tó jẹ́ ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Odò yẹn ò tíì pa rọ́rọ́ nígbà yẹn. Ìjì tó jà yẹn hú àwọn igi kan, àwọn igi náà sì léfòó sórí omi káàkiri, omi odò náà ń yára ṣàn gan-an, kódà ó lè gbéèyàn lọ.” Àmọ́ láìka gbogbo ìyẹn sí, ọkọ̀ ojú omi náà dé àwọn abúlé mẹ́ta tá a fẹ́ lọ.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ta náà lo àǹfààní yẹn láti tu àwọn ará abúlé náà nínú, torí wọ́n nílò rẹ̀ gan-an. Àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn tún pín ẹ̀dà Jí! ti ọdún 2017 tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀—Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Gbẹ̀mí Là.”
Àwọn ará abúlé tó ń gbé nítòsí odò yẹn mọrírì ìrànwọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ṣe gan-an, wọ́n sì gbádùn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n fi tù wọ́n nínú. Àwọn kan lára wọn sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń múra tán láti ṣèrànwọ́ lákòókò ìṣòro.” Àwọn míì sọ pé: “Wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn lóòótọ́, kì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n lásán.” Lẹ́yìn táwọn èèyàn náà rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn ṣe sapá láti ran àwọn ará wọn àtàwọn míì lọ́wọ́, ó wá ń wu ọ̀pọ̀ nínú wọn láti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì.
Marco tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà fẹ́ lọ wàásù fáwọn tó wà lábúlé
Ọkọ̀ ojú omi Sturi Yamni gúnlẹ̀ síwájú abúlé kan tí àkúnya omi ti ṣẹlẹ̀