“Mò Ń Ṣèwọ̀n Tí Mo Lè Ṣe”
Orílẹ̀-èdè Germany ni Irma ń gbé, ó sì ti fẹ́ pé ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún. Ẹ̀ẹ̀méjì ni ìjàǹbá ọkọ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí i rí, wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ abẹ fún un nígbà mélòó kan, torí náà kò lè wàásù láti ilé dé ilé mọ́ bó ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ní báyìí, lẹ́tà ló máa ń kọ láti fi wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ àtàwọn tó bá mọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí àti ti ìtùnú tó máa ń wà nínú lẹ́tà rẹ̀ máa ń wọni lọ́kàn débi pé àwọn èèyàn máa ń pè é láti mọ ìgbà tí wọ́n tún máa rí lẹ́tà míì gbà látọ̀dọ̀ ẹ̀. Wọ́n sì máa ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ìdúpẹ́ sí i, wọ́n á ní kó tún kọ òmíì ránṣẹ́ sáwọn. Irma sọ pé, “Gbogbo èyí ń fún mi láyọ̀, kò sì jẹ́ kí n dẹwọ́ nípa tẹ̀mí.”
Irma tún máa ń kọ lẹ́tà sí àwọn tó wà níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn arúgbó. Ó ní: “Obìnrin àgbàlagbà kan pè mí lórí fóònù, ó sì sọ pé lẹ́tà mi tu òun nínú gan-an nígbà tí ọkọ òun kú. Inú Bíbélì ẹ̀ ló tọ́jú lẹ́tà náà sí, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń kà á nírọ̀lẹ́. Obìnrin míì tí ọkọ rẹ̀ kú lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé, lẹ́tà mi ran òun lọ́wọ́ gan-an, kódà ó kọjá ìwàásù àlùfáà. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló fẹ́ bi mí, torí náà ó ní ṣé òun lè wá bá mi nílé.”
Ọ̀kan lára àwọn tí Irma mọ̀ dáadáa, àmọ́ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kó lọ síbòmíì tó jìnnà, àmọ́ ó ní kí Irma máa kọ lẹ́tà sóun. Irma sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Obìnrin náà tọ́jú gbogbo lẹ́tà tí mo kọ sí i.” Irma tún sọ pé, “Lẹ́yìn tó kú, ọmọ rẹ̀ obìnrin pè. Ó sọ fún mi pé òun ti ka gbogbo lẹ́tà tí mo kọ sí màmá òun, ó sì bẹ̀ mí pé kí n máa kọ lẹ́tà tó dá lórí Bíbélì sí òun náà.”
Irma ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ gan-an ni. Ó ní,“Mò ń bẹ Jèhófà pé kó fún mi lókun tí màá lè máa fi sìn ín nìṣó.” Ó fi kún un pé, “Bí mi ò tiẹ̀ lè wàásù láti ilé dé ilé mọ́, mò ń ṣèwọ̀n tí mo lè ṣe.”