Wọ́n Mọyì Àwọn Lẹ́tà Tó Kọ
Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Brooke, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló sì ń gbé. Lásìkò tí àrùn Kòrónà ń jà ràn-ìn, ó máa ń kọ lẹ́tà láti wàásù fáwọn èèyàn. Kódà, ọ̀pọ̀ lẹ́tà ló máa ń kọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àmọ́, lẹ́yìn ọdún kan ààbọ̀ ó sú u, torí pé ẹnì kan ṣoṣo péré ló fèsì lẹ́tà rẹ̀, ẹni náà sì sọ fún un pé kó má tún kọ lẹ́tà sí òun mọ́. Brooke wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé pàbó ni gbogbo ìsapá òun já sí.
Nígbà tó yá, Kim tóun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún Brooke pé oníbàárà kan ní báǹkì tóun ti ń ṣiṣẹ́ sọ fún òun pé òun gba lẹ́tà látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Kim wá rí i pé ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà tí Brooke kọ ni. Nígbà tí oníbàárà náà pa dà lọ sí báńkì lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó béèrè lọ́wọ́ Kim pé ṣé òun lè máa lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lásìkò yẹn orí zoom la ti ń ṣe àwọn ìpàdé wa.
Kò pẹ́ sígbà yẹn, David tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún Brooke pé ọkùnrin kan níbi iṣẹ́ òun sọ pé òun rí lẹ́tà kan gbà látọ̀dọ̀ Brooke. Ọkùnrin náà mọyì lẹ́tà yẹn gan-an torí pé ọwọ́ ni Brooke fi kọ ọ́ kì í ṣe ẹ̀rọ ló fi tẹ̀ ẹ́. Ó ní: “Ó yẹ kí ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì máa jẹ wọ́n lógún bíi ti obìnrin yìí.” David wá lo àǹfààní yìí láti wàásù fún ọkùnrin náà, ó sì ṣèlérí pé òun á fún un ní ọ̀kan lára àwọn ìwé wa. Inú ọkùnrin yẹn dùn láti gba ìwé náà.
Nígbà míì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í mọ ìgbà tí irúgbìn tá a fún lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù máa dàgbà. (Oníwàásù 11:5, 6) Síbẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Brooke ti jẹ́ kó túbọ̀ mọyì ipa tóun náà kó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.—1 Kọ́ríńtì 3:6.