Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Alibéníà àti Kosovo
Nígbà tí Gwen tó ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ lórílẹ̀-èdè Alibéníà ń sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Mi ò rò pé màá lè ṣe tó yìí fún Jèhófà.” a
Gwen wà lára ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kó lọ sí Alibéníà kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti kó “àwọn ohun iyebíye nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” jọ sínú ètò Ọlọ́run. (Hágáì 2:7) Kí ló mú káwọn ajíhìnrere yìí lọ síbẹ̀? Kí ni wọ́n ṣe kó lè rọrùn fún wọn láti lọ? Àwọn nǹkan wo ló jẹ́ kí wọ́n lè fara dà á láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n kojú sí?
Ipò Wọn Yàtọ̀, Ṣùgbọ́n Ohun Kan Náà Ni Wọ́n Fẹ́
Ohun kan náà ni gbogbo àwọn akéde tó lọ ṣèrànwọ́ fáwọn ará ní Alibéníà fẹ́ láti ṣe: Wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì fẹ́ kọ́ àwọn míì nípa rẹ̀.
Kí wọ́n tó gbéra, wọ́n kọ́kọ́ ṣe àwọn nǹkan kan táá mú kó rọrùn fún wọn láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì. Gwen sọ pé: “Mo kọ́kọ́ dara pọ̀ mọ́ àwùjọ tó ń sọ èdè Alibéníà ní ìlú mi. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí àpéjọ agbègbè kan lórílẹ̀-èdè Alibéníà. Nígbà tó yá, mo pa dà lọ síbẹ̀ fún àkókò díẹ̀ kí n lè túbọ̀ kọ́ èdè wọn.”
Nígbà tí Manuela tó jẹ́ ọmọ Ítálì wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlélógún (23), ó kó lọ sí agbègbè míì lórílẹ̀-èdè wọn kó lè lọ ran ìjọ kékeré kan lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Ọdún mẹ́rin ni mo fi sìn níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ni mo gbọ́ pé iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe ní Alibéníà. Torí náà, mo ṣètò láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níbẹ̀ fún oṣù mélòó kan.”
Ọmọ ọdún méje péré ni Federica nígbà tó gbọ́ ìròyìn nípa Alibéníà ní àpéjọ kan. Ó sọ pé: “Arákùnrin tó ròyìn nípa Alibéníà sọ pé àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa sì ń wá sípàdé. Àtìgbà yẹn ni mo tí ń sọ fáwọn òbí mi pé mo fẹ́ lọ sí Alibéníà. Ó yà wọ́n lẹ́nu pé ó wù mí láti lọ síbẹ̀, ṣùgbọ́n bàbá mi sọ pé, ‘Gbàdúrà nípa ẹ̀, bó bá sì jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà, ó máa gbọ́ àdúrà ẹ.’ Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n ní kí ìdílé wa lọ sìn ní Alibéníà!” Ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá báyìí, Federica sì ti ṣègbéyàwó. Òun àti Orges ọkọ ẹ̀ sì ń ṣe iṣẹ́ alákòókò kíkún ní Alibéníà.
Lẹ́yìn tí Gianpiero fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, òun àti ìyàwó rẹ̀ Gloria kó lọ sí Alibéníà. Ó sọ pé: “Orílẹ̀-èdè Ítálì la ti tọ́ àwọn ọmọ wa dàgbà. Mẹ́ta lára wọn kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Lọ́jọ́ kan, a ka àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ kan tó ní àkọlé náà, ‘Ǹjẹ́ O Lè Ré Kọjá Lọ sí Makedóníà?’ Ohun tó wà níbẹ̀ wọ̀ wá lọ́kàn gan-an. A wá jókòó, a sì ronú lórí bá a ṣe lè lo owó ìfẹ̀yìntì mi ká lè lọ sìn ní Alibéníà.”
Wọ́n Fara Balẹ̀ Ṣètò
Àwọn tó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ kọ́kọ́ máa ń fara balẹ̀ ṣètò ara wọn, wọ́n á sì ṣe àwọn ìyípadà táá mú kí wọ́n lè lọ. (Lúùkù 14:28) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti máa ń ronú nípa bí wọ́n á ṣe máa gbọ́ bùkátà ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Gwen tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣì wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó kọ́kọ́ lọ gbé lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kó lè tu owó jọ. Sophia àti Christopher táwọn náà wá láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “A ta mọ́tò wa àtàwọn ohun èèlò míì bí àga àti tábìlì. A ní in lọ́kàn pé ọdún kan la máa lè lò ní Alibéníà.” Ṣùgbọ́n wọ́n lò ju ọdún kan lọ níbẹ̀.
Àwọn akéde kan á lo oṣù díẹ̀ ní Alibéníà, wọ́n á pa dà sí orílẹ̀-èdè wọn lọ ṣiṣẹ́, wọ́n á tu owó jọ, wọ́n á wá pa dà wá sí Alibéníà. Ohun tí Eliseo àti Miriam ṣe nìyẹn. Eliseo ṣàlàyé pé: “Ibì kan táwọn èèyàn máa ń gbafẹ́ lọ lórílẹ̀-èdè Ítálì ni Miriam ti wá, ó sì rọrùn láti ríṣẹ́ téèyàn lè ṣe fúngbà díẹ̀ níbẹ̀. A máa ń lọ síbẹ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn láti lọ ṣiṣẹ́ fún oṣù mẹ́ta, owó tá a bá tù jọ làá wá fi gbéra fún oṣù mẹ́sàn-án tó kù ní Alibéníà. Ọdún márùn-ún la fi ṣe bẹ́ẹ̀.”
Bí Wọ́n Ṣe Borí Ìṣòro
Lẹ́yìn táwọn tó lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ bá ti débi tí wọ́n ń lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ mú ara wọn bá ipò ibẹ̀ mu. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn àti àpẹẹrẹ àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ní. Sophia tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà òtútù ní Alibéníà, inú ilé máa ń tutù gan-an ju bó ṣe máa ń rí níbi tá a ti wá. Mo kíyè sí báwọn arábìnrin tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ṣe ń múra, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í múra bíi tiwọn.” Orílẹ̀-èdè Poland ni Grzegorz àti ìyàwó rẹ̀ Sona ti wá, wọ́n sì ń sìn ní ìlú rírẹwà kan tó ń jẹ́ Prizren ní Kosovo. b Grzegorz sọ pé: “Onírẹ̀lẹ̀ làwọn akéde tó wà níbẹ̀, wọ́n nínúure, wọ́n sì ní sùúrù. Wọ́n ń kọ́ wa ní èdè wọn, wọ́n sì tún ń ràn wá lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n jẹ́ ká mọ àwọn ṣọ́ọ̀bù ti nǹkan ò ti wọ́n púpọ̀, wọ́n sì ṣàlàyé bá a ṣe lè ra nǹkan lọ́jà.”
Ìdí Tí Ayọ̀ Wọn fi Pọ̀
Àǹfààní táwọn tó lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì tún máa ń ní ni pé wọ́n máa ń di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀, wọ́n sì máa ń mọ ìtàn wọn. Sona ṣàlàyé pé: “Mo ti rí pé kò sí ìyípadà téèyàn ò lè ṣe tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àwọn ará tó wà níbi tá a ti ń sìn mú kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára torí pé mo rí bí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ìgbésí ayé wọn ṣe yí pa dà pátápátá nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Wọ́n jẹ́ ká rí i pé a wúlò nínú ìjọ, àwa náà sì rí ọ̀nà tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́. Inú mi dùn pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ọ̀wọ́n yìí la jọ ń sìn Jèhófà.” (Máàkù 10:29, 30) Gloria sọ pé: “Mo mọ ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tí wọ́n fara da inúnibíni líle koko látọ̀dọ̀ àwọn tó kórìíra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò wọn. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà wú mi lórí gan-an ni.”
Àwọn tó lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ tún ní àǹfààní láti mọ àwọn ohun pàtàkì tó ṣeé ṣe kí wọ́n má mọ̀ nílùú ìbílẹ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń rí i pé kéèyàn kúrò níbi tó ti mọ́ ọn lára kó lè túbọ̀ sin Jèhófà máa ń fúnni láyọ̀. Stefano sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Ní orílẹ̀-èdè tí mo ti wá, ìwàásù orí fóònù ni mo sábà máa ń ṣe, mo sì máa ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ ní ṣókí. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Alibéníà gbádùn kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ fún àkókò gígùn, pàápàá tí wọ́n bá ń mu kọfí. Torí pé mo máa ń tijú, ó kọ́kọ́ ni mí lára, mi kì í sì í mọ ohun tí màá sọ. Ṣùgbọ́n, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn náà jẹ mí lógún, mo ti wá ń gbádùn àtimáa bá wọn sọ̀rọ̀ báyìí. Ìyẹn sì ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ máa dùn mọ́ mi.”
Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni Leah àti ọkọ rẹ̀ William ti kó lọ sí Alibéníà. Ó sọ pé: “Bá a ṣe ń sìn níbí ti mú ká máa ronú lọ́nà tó yàtọ̀, ká sì máa gbé ìgbésí ayé tó yàtọ̀. A ti rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nípa bá a ṣe lè máa ṣàlejò, bá a ṣe lè bọ̀wọ̀ fúnni ká sì dọ̀rẹ́ àwọn èèyàn. A ti mọ àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà wàásù, tá a lè gbà mú káwọn èèyàn ronú lórí Bíbélì, ká sì ṣàlàyé ara wa.” William sọ pé: “Àwọn etíkun rírẹwà tó wà ní Alibéníà máa ń fa ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ mọ́ra. Ní tèmi, mo fẹ́ràn kí n máa gun kẹ̀kẹ́ gba àwọn orí òkè gbágungbàgun tó wà ní Alibéníà. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn tó wà ní Alibéníà ló jẹ́ kí ibí yìí gbádùn mọ́ mi jù! Ọ̀pọ̀ abúlé tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ló jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan la máa ń wàásù débẹ̀ lásìkò tá a bá ń ṣe àkànṣe ìwàásù. Nígbà míì, tá a bá lọ sí àwọn abúlé náà, odindi ọjọ́ kan la fi máa ń bá àwọn ìdílé mélòó kan sọ̀rọ̀.”
Ohun tó máa ń fún àwọn tó lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ láyọ̀ jù ni bí wọ́n ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (1 Tẹsalóníkà 2:19, 20) Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń Laura tó kó lọ sí Alibéníà lóun nìkan sọ pé: “Mo sìn fún àkókò díẹ̀ ní Fier. Láàárín ọdún méjì àtààbọ̀ péré, ọgọ́fà [120] èèyàn ló kúnjú ìwọ̀n láti máa wàásù! Kódà, èmi ni mo kọ mẹ́rìndínlógún (16) lára wọn lẹ́kọ̀ọ́!” Arábìnrin míì tó ń jẹ́ Sandra rántí ìrírí tó ní, ó sọ pé: “Mo wàásù fún obìnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ọjà. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi, ó sì kó pa dà sí abúlé tó ti wá. Nígbà tí mo gbúròó rẹ̀ kẹ́yìn, ó ti ń kọ́ èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!”
Jèhófà Bù Kún Wọn Torí Wọ́n Nífaradà
Àwọn kan lára àwọn tó lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ ní Alibéníà ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ṣì wà níbẹ̀, wọ́n sì ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn wọn gan-an. Ó máa ń yà wọ́n lẹ́nu nígbà míì tí wọ́n bá rí i pé àwọn èèyàn táwọn wàásù fún lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn ti wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Oníwàásù 11:6) Christopher tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mo pàdé ọkùnrin kan tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí mo kọ́kọ́ dé Alibéníà. Ó wú mi lórí nígbà tó ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ ohun tí èmí àti ẹ̀ jọ sọ̀rọ̀ lé lórí nínú Bíbélì nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ní báyìí, òun àti ìyàwó ẹ̀ ti ṣèrìbọmi.” Federica tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé pé: “Ní ìjọ kan, arábìnrin kan wá bá mi, ó sì béèrè bóyá mo rántí òun. Ó sọ pé mo wàásù fún òun lọ́dún mẹ́sàn-án sẹ́yìn. Lẹ́yìn témi kó lọ sílùú míì ni òun bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti ṣèrìbọmi. Ìgbà kan wà tí mo máa ń ronú pé àwọn ọdún tá a kọ́kọ́ fi wàásù ní Alibéníà kò sèso kankan. Mo ti wá rí i pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀!”
Inú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n kó lọ sí Alibéníà àti Kosovo dùn gan-an pé Jèhófà bù kún ìsapá wọn, ó sì ti jẹ́ káwọn gbádùn ìgbésí ayé wọn. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Eliseo ti lò ní Alibéníà, ó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn, ó sábà máa ń ṣe wá bíi pé ohun táyé ń gbé lárugẹ ló lè fini lọ́kàn balẹ̀. Ṣùgbọ́n irọ́ tó jìnnà sóòótọ́ nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìlànà Jèhófà ló máa ń jẹ́ káyé ẹni nítumọ̀, ó sì máa ń fini lọ́kàn balẹ̀. Bí mo ṣe ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ kì í jẹ́ kí n gbàgbé pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Mo rí i pé mo wúlò, àwọn ará sì mọyì mi. Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí àfojúsùn wa jọra ló yí mi ká.” Sandra náà gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ó ní: “Nígbà tí mo lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, mo mọ̀ pé àǹfààní ni Jèhófà fún mi láti ṣe ohun tó ti wà lọ́kàn mi tipẹ́, ìyẹn ni pé kí n jẹ́ míṣọ́nnárì. Mi ò kábàámọ̀ rí pé mo wá sí Alibéníà. Kódà mi ò láyọ̀ tó yìí rí láyé mi.”
a Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ìtàn iṣẹ́ ìwàásù wa ní Alibéníà, wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2010 lédè Gẹ̀ẹ́sì.
b Àríwá ìlà oòrùn Alibéníà ni Kosovo wà. Èdè Alibéníà ni ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ ń sọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá láti Alibéníà, àwọn ilẹ̀ Yúróòpù àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà yọ̀ǹda ara wọn láti wàásù ìhìn rere fáwọn tó ń sọ èdè Alibéníà ní Kosovo. Ní ọdún 2020, ọgọ́rùn-ún méjì ó lé àádọ́ta àti mẹ́fà [256] làwọn akéde tó wà níbẹ̀, iye ìjọ tó sì wà níbẹ̀ jẹ́ mẹ́jọ. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ní àwùjọ mẹ́ta àti àwọn méjì tó fẹ́ di àwùjọ.