TẸLIFÍṢỌ̀N JW
Bó O Ṣe Lè Wá Àtẹ́tísí àti Fídíò Lórí Roku
O lè wá nǹkan lórí Tẹlifíṣọ̀n JW ní apá tá a pè ní Wá a.
Níbi ìbẹ̀rẹ̀, lọ sí apá tá a pè ní Wá a kó o sì tẹ OK kó lè gbé àpótí tá a fi ń wá nǹkan wá.
Nínú àpótí náà, fi keyboard ojú tẹlifíṣọ̀n tẹ ọ̀rọ̀ tó o lè fi dá ohun tó ò ń wá mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè tẹ díẹ̀ lára àkòrí ẹ̀ síbẹ̀ tàbí kó o tẹ orúkọ ẹni tó dá lé tàbí ohun tí wọ́n ṣe nínú fídíò tàbí àtẹ́tísí náà. Bó o bá ṣe ń tẹ ọ̀rọ̀ láá ti máa gbé àwọn èyí tó jọ ọ́ wá. Fi bọ́tìnì Up, Down, Left àti Right tó wà lórí rìmóòtù rẹ lọ síbi àwòrán tàbí àkòrí fídíò tàbí àtẹ́tísí tó ò ń wá, kó o wá tẹ OK.
Tó o bá fẹ́ wá ọ̀rọ̀ kan pàtó nínú àkòrí fídíò tàbí àtẹ́tísí náà, tẹ ọ̀rọ̀ náà, kó o fi àmì “ bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, kó o sì fi àmì ” parí rẹ̀.
Oríṣiríṣi àtẹ́tísí àti fídíò ló máa gbé wá fún ẹ. Tó o bá fẹ́ kí ohun tó ń gbé wá túbọ̀ ṣe ṣàkó, tẹ bọ́tìnì Fídíò kó lè gbé fídíò nìkan wa, tàbí kó o tẹ bọ́tìnì Àtẹ́tísí kó lè gbé àtẹ́tísí nìkan wá.
Fídíò tàbí àtẹ́tísí mẹ́rìnlélógún (24) àkọ́kọ́ tó bá ọ̀rọ̀ tó o tẹ̀ mu jù ló máa kọ́kọ́ gbé wá. Wàá rí àpapọ̀ iye fídíò tàbí àtẹ́tísí tó rí (bí àpẹẹrẹ, “Ò ń wo 24 nínú 28”).
Tó ò bá rí ohun tó ò ń wá, tẹ ọ̀rọ̀ tó túbọ̀ ṣe ṣàkó. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ ètò oṣooṣù kan pàtó lò ń wá, àmọ́ tó o tẹ “eto osoosu”, á dáa kó o fi oṣù àti ọdún tó jẹ́ sí i, orúkọ arákùnrin tó ṣe atọ́kùn tàbí ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yẹn.