Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Yevgeniy Spirin àti Natalya ìyàwó ẹ̀

OCTOBER 14, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Fagi Lé Ìdájọ́ Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Ṣe fún Arákùnrin Spirin Pé Kó San Owó Ìtanràn

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Fagi Lé Ìdájọ́ Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Ṣe fún Arákùnrin Spirin Pé Kó San Owó Ìtanràn

Ní October 14, 2020, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Ivanovo fagi lé ìdájọ́ tílé ẹjọ́ kọ́kọ́ ṣe fún Arákùnrin Yevgeniy Spirin ní July 2020 pé kó san owó ìtanràn. Ohun táwọn alátakò fẹ́ ni pé kí wọ́n tún ẹjọ́ Arákùnrin Spirin gbọ́, àmọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yìí sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ tún un gbọ́. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe káwọn alátakò pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ tuntun yìí, kí wọ́n lè béèrè ohun tí wọ́n fẹ́ látìbẹ̀rẹ̀ pé kí Arákùnrin Spirin lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méje.