Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin àti Arábìnrin Oniszczuk wà pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i ní Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Kirov

SEPTEMBER 6, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Dá Arákùnrin Andrzej Oniszczuk Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n Lẹ́yìn Tó Ti Lo Oṣù Mọ́kànlá ní Àhámọ́

Wọ́n Dá Arákùnrin Andrzej Oniszczuk Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n Lẹ́yìn Tó Ti Lo Oṣù Mọ́kànlá ní Àhámọ́

Ní September 3, 2019, wọ́n dá Arákùnrin Andrzej Oniszczuk sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Láti October 9, 2018 ni wọ́n ti fi í sẹ́wọ̀n torí pé ó ń jọ́sìn Ọlọ́run. Láàárín àkókò yẹn, wọ́n fi í sínú àhámọ́, wọn ò jẹ́ kó rí Anna ìyàwó rẹ̀, wọn ò tún jẹ́ kó bá a sọ̀rọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti jẹ́ kó pa dà sílé báyìí, àmọ́ àwọn aláṣẹ ò gbà á láyè láti lọ síbi tó wù ú. Wọn ò sì tíì parí ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án.

Inú wa dùn pé Arákùnrin Andrzej Oniszczuk àti ìyàwó rẹ̀ dúró gbọin-in lákòókò tí nǹkan le koko yìí. A dúpẹ́ pé Jèhófà ń dáhùn àwọn àdúrà tá a gbà nítorí àwọn tó wa nínú “ìdè ẹ̀wọ̀n.”​—Kólósè 4:2, 3.