NOVEMBER 6, 2018
AJẸNTÍNÀ
A Wàásù Lákànṣe Níbi Térò Pọ̀ sí Nígbà Eré Ìdárayá Òlíńpíìkì Tó Wáyé ní Ajẹntínà Lọ́dún 2018
Ní October 6 sí 18, 2018, àwọn ará wa wàásù lákànṣe láwọn ibi térò pọ̀ sí nígbà Eré Ìdárayá Òlíńpíìkì Ọdún 2018 tó wáyé ní ìlú Buenos Aires, lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà.
Àwọn tó kópa nínú eré ìdárayá tó wà fáwọn ọ̀dọ́ náà lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000), wọ́n wá láti igba ó lé mẹ́fà (206) orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn gbà pé eré ìdárayá yìí ló tóbi jù lọ láyé, torí oríṣiríṣi eré ìdárayá tó wà fáwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sí méjìdínlógún (18) ni wọ́n ṣe níbẹ̀. Kí ọ̀pọ̀ àwọn eléré ìdárayá àtàwọn àlejò tó wá láti oríṣiríṣi ilẹ̀ yìí lè gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (6,400) Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kópa nínú ìwàásù náà. Àwọn ará wa lo ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́rùn-ún (390) àtẹ ìwé ní nǹkan bí ibi ọgọ́rùn-ún (100) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Torí pé àwọn ọ̀dọ́ ni eré ìdárayá náà wà fún, àwọn ará lo ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ apá méjèèjì àti ìwé pẹlẹbẹ Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè. Àwọn ìwé náà wà níbẹ̀ lóríṣiríṣi èdè, irú bíi Lárúbáwá, Chinese, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, German, Korean, Potogí, Russian, Sípáníìṣì àti Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Ajẹntínà. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje ó lé àádọ́rùn-ún (790) ìtẹ̀jáde làwọn èèyàn ń gbà lójoojúmọ́ lásìkò eré ìdárayá náà.
Inú àwọn ará tó kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà dùn gan-an láti sọ ìrètí tó wà nínú Bíbélì fún tọmọdé tàgbà.—Sáàmù 110:3.