Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 22, 2017
AUSTRIA

Ìlú Kan ní Austria Rántí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31], Tí Wọ́n Ṣẹ́ Níìṣẹ́ Lábẹ́ Ìjọba Násì

Ìlú Kan ní Austria Rántí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31], Tí Wọ́n Ṣẹ́ Níìṣẹ́ Lábẹ́ Ìjọba Násì

Olórí ìlú Techelsberg, Ọ̀gbẹ́ni Johann Koban (àárín) ń ṣí àmì ẹ̀yẹ nílùú Techelsberg, pẹ̀lú Peter Stocker (lápá ọ̀tún) àti gómìnà ìlú Carinthia, Dr. Peter Kaiser (lápá òsì).

NÍ ÌLÚ Selters, Jámánì—Ní àárọ̀ Friday May 19, 2017, àwọn aláṣẹ ìlú Techelsberg, ní Austria, ṣe ayẹyẹ láti rántí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba Násì pa àti awọn tí wọ́n fi sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Nígbà tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ yìí, wọ́n ṣí àmì kan tó ń jẹ́rìí sí bí wọ́n ṣe fìyà àìtọ́ jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Mọ́kànlélọ́gbọ̀n[31] ní ìlú Techelsberg àti àgbègbè rẹ̀.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orin “Ẹ Tẹ̀ Síwájú, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí!” tí àwọn ọgọ́ta [60] akọrin fi ẹnu lásán kọ. Orin yìí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lò níbi ìjọ́sìn wọn kárí ayé, ni Erich Frost kó jọ nígbà tó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen. Erich Frost wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí àwọn Násì fi sẹ́wọ̀n nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Lẹ́yìn tí wọ́n kọrin, àwọn àlejò olùbánisọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Johann Koban (olórí ìlú Techelsberg), Ọ̀gbẹ́ni Peter Stocker (ọmọ-ọmọ Gregor Wohlfahrt, Sr.—ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ṣẹ́ níìṣẹ́ ní Techelsberg), Ọ̀jọ̀gbọ́n Peter Gstettner, Ọ̀jọ̀gbọ́n Vinzenz Jobst, àti Dr. Peter Kaiser (gómìnà ìlú) bá àwùjọ tó tó ọgọ́rún-ún mẹ́ta àti áàdọ́ta [350] sọ̀rọ̀. Ilé iṣẹ́ ìròyin ORF 2 àti ORF Kärnten ti ìlu Austria pa pọ̀ pẹ̀lú oríṣiríṣi ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn lágbéègbè yẹn ló wá fídíò ìpàdé náà.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Peter Gstettner ń bá àwọn tó péjọ sọ̀rọ̀.

Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí tó tó igba ó lé méjìlá [212] nínú àwọn àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta [550] tó wà ní Austria ni wọ́n rán lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Wọ́n fi ẹ̀sùn èké kàn wọ́n pé wọ́n ń ṣe àkóbá fún ìjọba àjùmọ̀ni ti ilẹ̀ Jámánì, nítorí wọ́n kìí lọ́wọ́ sí òṣèlú, wọ́n kìí sì kọ́wọ́ ti ogun. Wón fi ipá mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa wọ aṣọ ẹ̀wọ̀n tó ní àmì igun mẹ́ta àti àwọ̀ àlùkò ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀é yìí kí wón ba lè tètè dá wọn mọ̀. Àpapọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Austria tó kú sí àgọ́ náà jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́jọ [154].

Kí wọ́n tó ṣe ìrántí yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí márùn-ún tó wá láti ìlu Techelsberg (Johann Stossier, Anton Uran, Gregor Wohlfahrt Sr., Gregor Wohlfahrt Jr., àti Willibald Wohlfahrt) tí ìjọba Násì fi sẹ́wọ̀n ni wọ́n ti kọ orúkọ wọn mọ́ “àwọn ẹni tó sọnù” nínú ìràntí ogun wọn, àmọ́ ìtàn yìí kìí ṣe òótọ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n Gstettner ṣàlàyé ìdí tí àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí yìí fi ṣe pàtàkì, Ó ní: “Àmí yìí ló jẹ́ ká mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an láyé ọjọ́un. Ibi gan-an ló sì yẹ kó wà ká lè máa rántí àwọn èèyàn tó ní ìgboyà tó kàmàmà yìí. Àwọn tó jẹ́ pé tọkàntọkàn ní wọ́n fi dúró lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ láìka ìyà ìkà tí wọ́n fi jẹ wọ́n sí, tó sì jẹ́ pé nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, wọ́n jáwé olúborí.”

Àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n fi ṣe ìrántí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31] tí Ìjọba Násì pa, àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n àtàwọn tí wọ́n ṣẹ́ níìṣẹ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ìlú Techelsberg ní wọ́n rì í sí. Díẹ̀ lára ewì tí Franz Wohlfahrt kọ wà lára àmì náà (wo àpótí tó wà nísàlẹ̀ yìí) àti orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà márùn-ún tí wọ́n kọ́kọ́ kọ orúkọ wọn mọ́ “àwọn ẹni tó sọnù.”

Johann Zimmermann, agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Austria, sọ pé: “A mọrírì irú àwọn ayẹyẹ yìí, tó jẹ́ káráyé mọ ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní báa tiẹ̀ ń kojú àtakò tó gbóná janjan. A lérò pé ayẹyẹ yìí á mú káwọn èèyàn tún inú rò lórí bó ṣé jẹ́ ìwà ìkà tó pé kí Ìjọba máa fojú ọ̀dàlúrú wo àwọn ẹ̀sìn tí àwọn tó ń ṣe wọ́n ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.”

Agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Austria: Johann Zimmermann, +43-1-804-53-45

Jámánì: Wolfram Slupina, +49-6483-41-3110